ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 2/11 ojú ìwé 7
  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
km 2/11 ojú ìwé 7

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí la máa fi ṣàtúnyẹ̀wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní February 28, 2011. Àtúnyẹ̀wò yìí dá lórí àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe láàárín ọ̀sẹ̀ January 3 sí February 28, 2011, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ á sì darí rẹ̀ fún ogún [20] ìṣẹ́jú.

1. Iṣẹ́ wo ni Hesekáyà dáwọ́ lé nígbà tó bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso rẹ̀, báwo la sì ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ lóde òní? (2 Kíró. 29:16-18) [w09 6/15 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 13]

2. Báwo ni ọ̀rọ̀ tó wà nínú 2 Kíróníkà 36:21 ṣe fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Jeremáyà 25:8-11 ní ìmúṣẹ? [w06 11/15 ojú ìwé 32 ìpínrọ̀ 1 sí 4]

3. Báwo ni Ẹ́sírà 3:1-6 ṣe fi hàn pé àsìkò tí Ìwé Mímọ́ sọ pé ìsọdahoro Jerúsálẹ́mù tó jẹ́ àádọ́rin ọdún máa dópin gan-an ló dópin? [w06 1/15 ojú ìwé 19 ìpínrọ̀ 2]

4. Kí nìdí tí ẹnu fi ya Ẹ́sírà nígbà tó gbọ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń fẹ́ àwọn ọmọ ilẹ̀ náà? (Ẹ́sírà 9:1-3) [w06 1/15 ojú ìwé 20 ìpínrọ̀ 1]

5. Àwọn wo ni àwọn “ọlọ́lá ọba,” àṣà tó wà lọ́wọ́ wọn wo ló sì yẹ ká ṣọ́ra fún? (Neh. 3:5) [w06 2/1 ojú ìwé 10 ìpínrọ̀ 1; w86 6/1 ojú ìwé 21]

6. Báwo ni Gómìnà Nehemáyà ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún àwọn Kristẹni alábòójútó? (Neh. 5:14-19) [w06 2/1 ojú ìwé 10, ìpínrọ̀ 4]

7. Bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà ayé Nehemáyà, báwo la ò ṣe ní dẹni tó ń ṣàìnáání “ilé Ọlọ́run wa”? (Neh. 10:32-39) [w98 10/15 ojú ìwé 21-22 ìpínrọ̀ 12]

8. Tá a bá ronú nípa ọ̀nà tí Nehemáyà gbà gbé ìgbé ayé rẹ̀, ìbéèrè wo ló máa mú ká bi ara wa? (Neh. 13:31) [w96 9/15 ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 3]

9. Ǹjẹ́ Ẹ́sítérì ní ìbálòpọ̀ tí kò tọ́ pẹ̀lú ọba Ahasuwérúsì? (Ẹ́sít. 2:14-17) [w91 1/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 6]

10. Kí nìdí tí Módékáì fi kọ̀ láti tẹrí ba fún Hámánì? (Ẹ́sít. 3:2, 4) [w06 3/1 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 4]

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́