Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ March 7
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MARCH 7
Orin 102 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cf orí 18 ìpínrọ̀ 19 sí 23, àti àpótí tó wà lójú ìwé 191 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ẹ́sítérì 6-10 (10 min.)
No. 1: Ẹ́sítérì 7:1-10 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Àwọn Kristẹni Gbọ́dọ̀ Bọ̀wọ̀ fún Ìlànà Ipò Orí—td 19B (5 min.)
No. 3: Ìdí Tí Jésù Fi Jẹ́ Olórí Aṣojú àti Aláṣepé Ìgbàgbọ́ Wa—Héb. 12:2 (5 min.)
□ Ìpàdé Ìṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: Máa Lo Ìyíniléròpadà Nígbà Tó O Bá Ń Kọ́ni. Àsọyé tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 255 sí 257. Ní ṣókí, ṣe àṣefihàn kókó kan tàbí méjì tó wà níbẹ̀.
10 min: Máa Lo Àwọn Ìwé Àṣàrò Kúkúrú. Ìjíròrò. Sọ àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú tó wà. Sọ àwọn ìgbà téèyàn lè lò wọ́n àti ohun tó mú kó máa fa àwọn èèyàn lọ́kàn mọ́ra. Ní kí àwọn ará sọ bí wọ́n ti ṣe lo àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú. Ṣé àṣefihàn kan tàbí méjì.
10 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
Orin 35 àti Àdúrà