Àwọn ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní February: Ẹ lè lo Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé tàbí Jọ́sìn Ọlọ́run Tòótọ́ Kan Ṣoṣo Náà. March: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá gidigidi láti àwọn bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. April àti May: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Nígbà tẹ́ ẹ bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó fìfẹ́ hàn tó fi mọ́ àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tàbí àwọn àpéjọ míì tí ètò Ọlọ́run ṣètò àmọ́ tí wọn kò tíì máa dara pọ̀ mọ́ ìjọ déédéé, ẹ fún wọn ní ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Kẹ́ ẹ sì ní in lọ́kàn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn.
◼ Ẹṣin ọ̀rọ̀ àkànṣe àsọyé fún gbogbo èèyàn ní àkókò Ìrántí Ikú Kristi tọdún 2011 ni “Ǹjẹ́ Àwọn Ìlànà Bíbélì Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Kojú Àwọn Ìṣòrò Òde Òní?”
◼ A ò ní ṣe ìpàdé kankan lọ́jọ́ Sunday April 17, tá a máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi àyàfi ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá. Kí àwọn ìjọ tó bá ń ṣe ìpàdé lọ́jọ́ yẹn ṣètò láti ṣe ìpàdé wọn ní ọjọ́ míì láàárín ọ̀sẹ̀. Tó bá jẹ́ pé àwọn ìjọ mélòó kan ló ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan, tí wọn ò sì lè ráyè ṣe ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba láàárín ọ̀sẹ̀, wọ́n lè fagi lé ìpàdé náà. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, a rọ gbogbo ìdílé láti ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ti ọ̀sẹ̀ yẹn nígbà Ìjọsìn Ìdílé wọn.