Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn
Àwọn akéde tí iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ó lé àádọ́rin lé nírínwó ó dín méjì [300,468] ló ròyìn lóṣù September ọdún 2010, ìyẹn la sì fi bẹ̀rẹ̀ ọdún iṣẹ́ ìsìn 2011. Bákan náà, lóṣù yẹn, a darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó jẹ́ ọ̀kẹ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbàájọ àti ẹgbẹ̀rin ó dín mẹ́tàlélógún [635,777], èyí jẹ́ ẹ̀rí pé a ṣì ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nínú iṣẹ́ ìkórè náà.