Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Pápá Tó Ń Gbéni Ró, Tó Ń Múni Gbára Dì, Tó sì Ń Mú Ká Wà Létòlétò
1. Kí nìdí tá a fi ń ṣe ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá?
1 Nígbà kan, Jésù ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tí iye wọn jẹ́ àádọ́rin [70], kí wọ́n lọ wàásù. (Lúùkù 10:1-11) Ó sọ̀rọ̀ tó gbé wọn ró nípa bó ṣe rán wọn létí pé wọn ò ní dá nìkan ṣe iṣẹ́ yìí àti pé Jèhófà, “Ọ̀gá ìkórè” náà ló ń darí wọn. Ó tún fún wọn láwọn ìtọ́ni tó mú kí wọ́n gbára dì láti ṣe iṣẹ́ náà, ó sì ṣètò wọn ní ti pé ó pín wọn ní “méjìméjì.” Bákan náà lóde òní, ohun kan náà ni ìpàdé tá a máa ń ṣe ká tó lọ sóde ẹ̀rí wà fún, ó máa ń gbé wa ró, ó máa ń mú ká gbára dì, ó sì máa ń mú ká wà létòlétò.
2. Báwo ló ṣe yẹ kí àkókò tá a fi ń ṣe ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá gùn tó?
2 Ní báyìí, ìṣẹ́jú mẹ́wàá sí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún la máa ń fi ṣe ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá, lára ohun tá a máa ń ṣe ni pé ká pín àwọn ará, ká sọ ìpínlẹ̀ ìwàásù tá a ti máa ṣiṣẹ́, ká sì gbàdúrà. Àmọ́, a ti wá ṣe àyípadà sí bí a ó ṣe máa ṣe ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá báyìí. Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù April, ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá kò ní máa ju ìṣẹ́jú márùn-ún sí méje lọ. Àmọ́, ẹ lè má lò tó bẹ́ẹ̀ tó bá jẹ́ pé lẹ́yìn tí ìpàdé ìjọ parí lẹ máa ṣe ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá, torí pé àwọn ará ṣẹ̀ṣẹ̀ gbádùn ìjíròrò tá a gbé ka Ìwé Mímọ́ tán ni. Tí ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá kò bá gùn jù, èyí á jẹ́ ká lè lo àkókò tó pọ̀ sí i lóde ẹ̀rí. Láfikún sí èyí, tí àwọn aṣáájú-ọ̀nà tàbí àwọn akéde bá ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ kí ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá tó bẹ̀rẹ̀, ìwọ̀nba àkókò díẹ̀ ni ìdádúró yóò fi wáyé lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wọn.
3. Báwo la ṣe lè ṣètò ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá lọ́nà tí yóò fi ṣe àwọn ará láǹfààní gan-an?
3 Ó yẹ ká ṣètò ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá lọ́nà tó máa ṣe àwọn ará láǹfààní gan-an. Ní ọ̀pọ̀ ìjọ, wọ́n ti rí i pé ó dára kí àwọn àwùjọ máa pàdé pọ̀ lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ dípò kí gbogbo wọn máa pàdé níbì kan. Èyí á mú kó rọrùn fún àwọn ará láti dé ibi tá a ti fẹ́ ṣe ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá àti ìpínlẹ̀ ìwàásù. Èyí á tún jẹ́ ká lè tètè pín àwọn ará, yóò sì mú kó rọrùn fún àwọn alábòójútó àwùjọ láti fún àwọn tó wà lábẹ́ àbójútó wọn ní àfiyèsí. Ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà lè gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀ wò, kí wọ́n sì pinnu ohun tó yẹ ní ṣíṣe. Ó yẹ káwọn ará ti mọ ibi tí wọ́n ti máa ṣiṣẹ́ àti ẹni tí wọ́n máa bá ṣiṣẹ́ ká tó fi àdúrà ṣókí parí ìpàdé náà.
4. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa ronú pé ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá kò ṣe pàtàkì bíi tàwọn ìpàdé ìjọ tó kù?
4 Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Ṣe Pàtàkì Bíi Tàwọn Ìpàdé Ìjọ Tó Kù: Torí pé àwọn tó fẹ́ lọ sí òde ẹ̀rí ni ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá wà fún, ó lè máà jẹ́ gbogbo àwọn ará ìjọ ló máa wà níbẹ̀. Àmọ́, èyí kò wá túmọ̀ sí pé ká fọwọ́ yẹpẹrẹ mú un tàbí ká máa ronú pé kò ṣe pàtàkì bíi tàwọn ìpàdé ìjọ tó kù. Bíi ti gbogbo ìpàdé ìjọ, ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá jẹ́ ìpèsè látọ̀dọ̀ Jèhófà tó ń jẹ́ ká lè máa ru ara wa sókè lẹ́nì kìíní-kejì sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà. (Héb. 10:24, 25) Torí náà, kí ẹni tó máa darí ìpàdé yìí múra sílẹ̀ dáadáa kí ìjíròrò náà lè bọlá fún Jèhófà, kó sì ṣe àwọn tó wà níbẹ̀ láǹfààní. Tó bá ti lè ṣeé ṣe tó, kí àwọn akéde tó ń lọ sóde ẹ̀rí sapá láti pésẹ̀ sí ìpàdé náà.
Kò yẹ ká máa fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá tàbí ká máa wò ó pé kò ṣe pàtàkì bíi tàwọn ìpàdé ìjọ tó kù
5. (a) Àwọn nǹkan wo ni alábòójútó iṣẹ́ ìsìn gbọ́dọ̀ ṣe kí ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá lè wà létòlétò? (b) Báwo ló ṣe yẹ kí àwọn arábìnrin máa darí ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá?
5 Bí Ẹni Tó Máa Darí Ìpàdé Náà Ṣe Lè Múra Sílẹ̀: Kó bàa lè ṣeé ṣe fún ẹnì kan láti múra iṣẹ́ tó máa ṣe ní ìpàdé sílẹ̀ dáadáa, ó yẹ kí wọ́n ti fún un ní iṣẹ́ náà ṣáájú ìgbà tó máa ṣe é. Bí ọ̀rọ̀ ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá náà ṣe rí nìyẹn. Òótọ́ ni pé nígbà tí àwọn àwùjọ bá pàdé lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, àwọn alábòójútó àwùjọ tàbí àwọn olùrànlọ́wọ́ wọn ló máa ń darí ìpàdé náà ní àwùjọ wọn. Àmọ́, tó bá jẹ́ gbogbo ìjọ ló máa pàdé láti ṣe ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá, alábòójútó iṣẹ́ ìsìn á ti yan ẹni tó máa darí ìpàdé náà. Àwọn alábòójútó iṣẹ́ ìsìn kan máa ń fún gbogbo àwọn tó ń darí ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ, wọ́n á sì tún lẹ ọ̀kan mọ́ pátákó ìsọfúnni. Kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn fọgbọ́n yan àwọn tí á máa darí ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá, kó fi sọ́kàn pé tí ìpàdé náà báa máa gbẹ́ṣẹ́ dáadáa, àwọn tó ń darí rẹ̀ gbọ́dọ̀ mọ̀ọ̀yàn kọ́, kí wọ́n sì mọ bá a ṣe ń ṣètò nǹkan. Tí kò bá sí alàgbà, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí arákùnrin míì tó ti ṣèrìbọmi tó tóótun tó lè darí ìpàdé náà láwọn ọjọ́ míì, kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn yan arábìnrin kan tó tóótun tó máa darí rẹ̀.—Wo àpilẹ̀kọ náà “Tó Bá Jẹ́ Pé Arábìnrin Ló Máa Darí Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Pápá.”
6. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí ẹni tó máa darí ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá múra sílẹ̀ dáadáa?
6 Tí wọ́n bá fún wa níṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run tàbí Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn, a máa ń fọwọ́ pàtàkì mú un, a sì máa ń múra rẹ̀ sílẹ̀ dáadáa. Ṣàṣà nínú wa ló máa dúró dìgbà tó bá wà lójú ọ̀nà ìpàdé kó tó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa ohun tó máa sọ. Ọwọ́ tó yẹ ká fi mú dídarí ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá náà nìyẹn. Ní báyìí tí àkókò tí a ó máa fi ṣe ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá máa dín kù, ó wá túbọ̀ ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa múra sílẹ̀ dáadáa kí ìpàdé náà lè nítumọ̀ kó sì parí lákòókò. Ara ìmúrasílẹ̀ náà ni pé ká ti mọ ibi tá a ti máa ṣiṣẹ́ ṣáájú.
7. Àwọn nǹkan wo ni ẹni tó máa darí ìpàdé náà lè jíròrò?
7 Ohun Tá A Máa Jíròrò: Torí pé bí ìpínlẹ̀ kan ṣe rí yàtọ̀ sí òmíràn, ẹrú olóòótọ́ kò ṣe ìlapa èrò tí a ó máa lò ní ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá kọ̀ọ̀kan tá a bá ń ṣe. Àwọn kókó tá a lè sọ̀rọ̀ lé lórí wà nínú àpótí tó ní àkọlé náà, “Àwọn Ohun Tí Ẹ Lè Jíròrò ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Pápá.” Ohun kan ni pé, a ó máa ṣe ìpàdé yìí lọ́nà ìjíròrò. Láwọn ìgbà míì, a ó máa ṣe àṣefihàn tí akéde kan ti múra rẹ̀ sílẹ̀ dáadáa tàbí ká wo fídíò kan lórí Ìkànnì jw.org/yo tó bá ohun tí à ń jíròrò mu. Tí ẹni tó máa darí ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá bá ń múra sílẹ̀, ó yẹ kó ronú nípa ohun tó máa gbé àwọn tó ń lọ sóde ẹ̀rí ró, tí yóò sì mú wọn gbára dì fún iṣẹ́ ìwàásù ọjọ́ náà.
Nígbà tí ẹni tó máa darí ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá bá ń múra sílẹ̀, ó yẹ kó ronú nípa ohun tó máa gbé àwọn tó ń lọ sóde ẹ̀rí lọ́jọ́ yẹn ró àti ohun tó máa mú kí wọ́n gbára dì
8. Kí ló máa dára jù kí ẹni tó máa darí ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá jíròrò láwọn ọjọ́ Saturday àti Sunday?
8 Bí àpẹẹrẹ, láwọn ọjọ́ Saturday, ọ̀pọ̀ àwọn akéde máa ń lo ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lóde ẹ̀rí. Ọ̀pọ̀ àwọn tó máa ń jáde lọ́jọ́ Saturday ni kì í jáde láàárín ọ̀sẹ̀, torí náà ó lè má rọrùn fún wọn láti rántí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tí wọ́n fi dánra wò nígbà Ìjọsìn Ìdílé wọn. Torí náà, ó máa dáa tí ẹni tó máa darí ìpàdé yìí bá tún rán àwọn ará létí ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó wà lẹ́yìn Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. A tún lè jíròrò àwọn ohun tá a lè mú wọnú ìjíròrò wa nígbà tá a bá ń fi ìwé ìròyìn lọni, irú bí ohun tá a gbọ́ nínú ìròyìn ilẹ̀ wa, ìṣẹ̀lẹ̀ kan ládùúgbò tàbí ayẹyẹ kan. A tún lè jíròrò ohun tá a lè sọ láti múra ọkàn ẹni tá a wàásù fún sílẹ̀ de ìgbà tá a bá pa dà wá, tó bá gba ìwé ìròyìn. Tí àwọn kan bá wà nípàdé ìṣẹ́ ìsìn pápá náà tí wọ́n ti ń lo ìwé ìròyìn tá à ń lò lóṣù yẹn, ẹni tó ń darí ìpàdé náà lè ní kí wọ́n sọ àwọn ọ̀nà kan tí wọ́n ti gbà fi àwọn ìwé ìròyìn náà lọni tàbí kí wọ́n sọ àwọn ìrírí tó ń gbéni ró. Láwọn ọjọ́ Sunday, ẹni tó ń darí lè ṣe ohun kan náà nípa ìwé tá a fi ń lọni lóṣù yẹn. A lè fi àwọn ìwé tá a fi ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́, irú bí Ìròyìn Ayọ̀ àti Tẹ́tí sí Ọlọ́run àti Bíbélì Fi Kọ́ni lọ àwọn èèyàn nígbàkigbà, torí náà ẹni tó máa darí ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá lè sọ̀rọ̀ ṣókí nípa bá a ṣe lè lo ọ̀kan lára àwọn ìtẹ̀jáde yìí.
9. Kí la lè jíròrò láwọn òpin ọ̀sẹ̀ tá a bá ń ṣe àkànṣe ìpolongo?
9 Tó bá jẹ́ pé ìjọ wa ń ṣe àkànṣe ìpolongo kan lópin ọ̀sẹ̀, ẹni tó ń darí ìpàdé náà lè jíròrò bá a ṣe lè fi àwọn ìwé ìròyìn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé lọni pa pọ̀ mọ́ ìwé ìkésíni tàbí ìwé àṣàrò kúkúrú, ó sì lè jíròrò ohun tá a lè ṣe tá a bá rẹ́ni tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa. Ohun míì tún ni pé ká sọ àwọn ìrírí tó fi hàn bí irú àwọn ìpolongo bẹ́ẹ̀ ti ṣe pàtàkì tó.
10, 11. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn akéde máa múra sílẹ̀ kí ìpàdé iṣẹ́ ìsìn lè nítumọ̀?
10 Bí Àwọn Akéde Ṣe Lè Múra Sílẹ̀: Àwọn akéde náà ní ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe kí ìpàdé náà lè nítumọ̀. Tí wọ́n bá ń múra òde ẹ̀rí sílẹ̀, bóyá nígbà ìjọsìn ìdílé wọn, wọ́n á lè sọ ohun tó máa ṣàǹfààní fáwọn akéde tó kù. Ara ìmúrasílẹ̀ tó dáa ni pé ká ti gba àwọn ìwé ìròyìn àtàwọn ìwé tá a máa lò lóde ẹ̀rí ká tó lọ sí ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá, èyí á jẹ́ kí gbogbo wa lè lọ sí ìpínlẹ̀ ìwàásù wa láìfi àkókò ṣòfò.
11 Ó tún ṣe pàtàkì pé ká múra láti dé sí ìpàdé iṣẹ́ ìsìn ní ìṣẹ́jú díẹ̀ kí ìpàdé náà tó bẹ̀rẹ̀. Lóòótọ́, a máa ń sapá láti dé sí gbogbo àwọn ìpàdé ìjọ lásìkò. Àmọ́, ńṣe ló máa ń da ètò rú tá a bá ń pẹ́ ká tó dé ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá. Lọ́nà wo? Ọ̀pọ̀ nǹkan ni arákùnrin tó ń darí ìpàdé máa ronú nípa rẹ̀ kó tó di pé ó ṣètò àwọn tó ń lọ sóde ẹ̀rí. Tó bá jẹ́ pé àwọn akéde díẹ̀ ló wà nípàdé náà, ó lè yàn láti ní kí gbogbo wọn lọ sí ìpínlẹ̀ ìwàásù kan tí wọ́n ti ṣe lápá kan tẹ́lẹ̀. Tó bá jẹ́ pé ẹsẹ̀ làwọn kan fi rìn wá sí ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá, tí ìpínlẹ̀ ìwàásù tí wọ́n ti máa ṣiṣẹ́ sì jìnnà, ó lè pín wọn mọ́ àwọn tó gbé mọ́tò wá. Tó bá jẹ́ àdúgbò tí ìwà ọ̀daràn ti sábà máa ṣẹlẹ̀ ni wọ́n ti máa ṣiṣẹ́, ó lè ní kí àwọn arákùnrin kan ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn arábìnrin tàbí kí wọ́n ṣiṣẹ́ nítòsí àwọn arábìnrin náà. Ó lè ní kí àwọn akéde tí wọ́n jẹ́ aláìlera ṣiṣẹ́ ní òpópónà tó tẹ́jú tàbí láwọn àdúgbò tí ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì kò ti pọ̀. Ó lè ní kí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di akéde ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn akéde onírìírí. Àmọ́, táwọn akéde bá pẹ́ kí wọ́n tó dé, ó máa gba pé kí ẹni tó darí ìpàdé náà tún àwọn ètò yìí ṣe nítorí àwọn tó pẹ́ lẹ́yìn. Òótọ́ ni pé láwọn ìgbà míì, a máa ń ní ìdí tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ tó mú ká pẹ́ dé. Àmọ́, tó bá ti mọ́ wa lára láti máa pẹ́ dé, a lè ṣàyẹ̀wò ara wa láti mọ̀ bóyá ńṣe la ò fojú pàtàkì wo ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá tàbí a ò ṣètò ara wa dáadáa ká lè dé lásìkò.
12. Tó bá jẹ́ pé o sábà máa ń ṣe ètò ara ẹni, kí lo lè ṣe?
12 Àwọn ará tó wá sí ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá lè yàn láti ṣètò ẹni tí wọ́n máa bá ṣiṣẹ́ kí ìpàdé iṣẹ́ ìsìn tó bẹ̀rẹ̀ tàbí kí ẹni tó darí pín ẹnì kan mọ́ wọn. Tó bá jẹ́ pé o sábà máa ń ṣe ètò ara ẹni, ṣé o lè “gbòòrò síwájú” nípa bíbá àwọn míì nínú ìjọ ṣiṣẹ́ dípò kó o máa bá àwọn ọ̀rẹ́ rẹ kan ṣiṣẹ́ ní gbogbo ìgbà? (2 Kọ́r. 6:11-13) Ǹjẹ́ o lè ṣètò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti máa bá akéde tuntun kan ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí kó o lè ràn án lọ́wọ́ láti mú ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ sunwọ̀n sí i? (1 Kọ́r. 10:24; 1 Tím. 4:13, 15) Máa tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa sí ìtọ́ni tí ẹni tó darí ìpàdé bá fún yín, títí kan ìtọ́ni nípa ibi tí ẹ ti máa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lóde ẹ̀rí. Tí ìpàdé náà bá ti parí, má ṣe yí ètò tó ti wà nílẹ̀ pa dà, kó o sì tètè máa lọ sí ìpínlẹ̀ ìwàásù.
13. Tí kálukú bá ṣe ipa tirẹ̀ tọkàntọkàn, báwo ni ìpàdé iṣẹ́ ìsìn ṣe máa ṣe wá láǹfààní?
13 Lẹ́yìn táwọn àádọ́rin tí Jésù rán lọ sẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wàásù tán, wọ́n “padà dé pẹ̀lú ìdùnnú.” (Lúùkù 10:17) Kò sí àní-àní pé ìpàdé tí Jésù ṣe pẹ̀lú wọn kí wọ́n tó lọ wàásù mú kí wọ́n ṣàṣeyọrí. Lóde òní, àwọn ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá lè ṣe wá láǹfààní bíi tìgbà yẹn. Tí kálukú bá ṣe ipa tirẹ̀ tọkàntọkàn, àwọn ìpàdé iṣẹ́ ìsìn á máa gbé wa ró, á mú wa gbára dì, á sì mú ká wà létòlétò ká lè ṣàṣeparí iṣẹ́ tá a gbé lé wa lọ́wọ́ láti ‘jẹ́rìí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.’—Mát. 24:14.