Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ March 30
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MARCH 30
Orin 57 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 22 ìpínrọ̀ 9 sí 17 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 1 Sámúẹ́lì 14-15 (8 min.)
No. 1: 1 Sámúẹ́lì 14:36-45 (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Kí Ló Túmọ̀ Sí Láti Kọ́ Èdè Mímọ́ Gaara Ká sì Máa Sọ Ọ́?—Sef. 3:9 (5 min.)
No. 3: Ìmúṣẹ Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Nípa Ọjọ́ Ìkẹyìn—igw ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 1 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
ẸṢIN Ọ̀RỌ̀ OṢÙ YÌÍ: “Gbára Dì fún Iṣẹ́ Rere Gbogbo.”—Títù 3:1.
15 min: Àwọn Fídíò Míì Lórí Ìkànnì Wa Tá A Lè Lò Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Ìjíròrò. Kọ́kọ́ fi fídíò náà, Báwo La Ṣe Máa Ń Ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? han àwọn ará. Kẹ́ ẹ wá jíròrò àwọn ọ̀nà tá a lè gbà lo fídíò yìí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́. Lẹ́yìn náà, tún ṣe ohun kan náà nípa fídíò náà, Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba? Ṣe àṣefihàn kan.
15 min: “Máa Fi Ìwé Náà, ‘Ohun Tó Wà Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run’ Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ní kí àwọn ará dábàá àwọn ọ̀nà míì tá a lè gbà lo ìwé “Ohun Tó Wà Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ṣe àṣefihàn kan.
Orin 114 àti Àdúrà