Orin 37
Ọlọ́run Mí sí Ìwé Mímọ́
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ńtàn yòò,
Ó sì ńmọ́lẹ̀ lókùnkùn.
Tí a bá ńtẹ̀ lée láìyẹsẹ̀,
Yóò sọ wá di òmìnira.
2. Ó nímìísí Ọlọ́run,
Ó ńsọ nǹkan tó yẹ ká ṣe.
Ó sì ńmú ohun gbogbo tọ́,
Ká lè gbàbáwí Ọlọ́run.
3. A rí ìfẹ́ Ọlọ́run,
Nínú Ìwé Mímọ́ yìí.
Aó di ọlọ́gbọ́n táa báń kàá,
Yóò fi ọ̀nà ìyè hàn wá.
(Tún wo Sm. 119:105; Òwe 4:13.)