Máa Fi Ìwé Náà, “Ohun Tó Wà Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” Bẹ̀rẹ̀ Ìjíròrò
1. Ìwé tuntun wo la gbà tó máa wúlò lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́?
1 Báwo la ṣe lè lo ìwé tuntun náà, “Ohun Tó Wà Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,” nígbà tá a bá ń múra àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a máa lò lóde ẹ̀rí? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé a to àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ sábẹ́ onírúurú àwọn àkòrí ọ̀rọ̀ Bíbélì, ó máa wúlò gan-an láti fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò.
2. Báwo la ṣe lè lo ìwé “Ohun Tó Wà Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́?
2 O lè lo ìbéèrè 8 kó o sì sọ pé: “À ń ṣèbẹ̀wò ráńpẹ́ sọ́dọ̀ àwọn aládùúgbò wa torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń béèrè pé, ‘Ṣé Ọlọ́run ló lẹ̀bi ìyà tó ń jẹ aráyé?’ [Láwọn orílẹ̀-èdè kan, ohun tó máa dára ni pé ká fi ìbéèrè náà han ẹni tá a fẹ́ wàásù fún.] Kí lèrò rẹ? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì fún wa ní ìdáhùn tó ń tẹ́ni lọ́rùn sí àwọn ìbéèrè yìí.” Ka ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀ kó o sì ṣàlàyé wọn. Tí onítọ̀hún bá nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ, o lè fi àwọn ìbéèrè ogun tó wà lójú ìwé 1 hàn án, kó o sì ní kó mú èyí tó máa fẹ́ kẹ́ ẹ jíròrò nígbà tó o bá pa dà wá. Tàbí kó o fún un ni ọ̀kan lára àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa tó ní àwọn ìsọfúnni púpọ̀ sí i nípa ohun tẹ́ ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ jíròrò.
3. Báwo la ṣe lè fi ìwé “Ohun Tó Wà Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò láwọn ìpínlẹ̀ ìwàásù tó jẹ́ pé àwọn tó wà níbẹ̀ kì í ṣe ẹlẹ́sìn Kristẹni?
3 Ìbéèrè 4 àti 13 sí 17 lè wúlò gan-an tá a bá ń wàásù láwọn ìpínlẹ̀ tó jẹ́ pé àwọn tó wà níbẹ̀ kì í ṣe ẹlẹ́sìn Kristẹni. Bí àpẹẹrẹ, o lè lo ìsọfúnni tó wà ní ìbéèrè 17 kó o wá sọ pé: “À ń ṣèbẹ̀wò ráńpẹ́ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn láti sọ ohun kan tó máa ṣe àwọn ìdílé láǹfààní. Ṣé ẹ̀yin náà gbà pé oríṣiríṣi ìṣòro làwọn ìdílé ń dojú kọ lóde-òní? [Jẹ́ kó fèsì.] Ọ̀pọ̀ tọkọtaya ti rí i pé ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n yìí wúlò gan-an: “Kí aya ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.” [Má ṣe sọ pé inú Éfésù 5:33 lo ti mú ọ̀rọ̀ yìí jáde. Tó bá jẹ́ pé obìnrin lò ń bá sọ̀rọ̀, o lè lo ọ̀rọ̀ tó wà ní Éfésù 5:28.] Ṣẹ́ ẹ rò pé táwọn tọkọtaya bá ń fi ìmọ̀ràn yìí sílò, ó máa ṣàǹfààní fún ìgbéyàwó wọn?”
4. Kí lo ṣe lópin ìjíròrò rẹ pẹ̀lú ẹnì kan tí kì í ṣe ẹlẹ́sìn Kristẹni?
4 Lópin ìjíròrò yín, ẹ ṣètò bẹ́ ẹ ó ṣe máa bá ìjíròrò yín lọ nígbà míì. O sì lè ṣètò láti sọ̀rọ̀ nípa ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà lábẹ́ ìbéèrè tó o lò. Nígbà tó o bá rí i pé o yẹ bẹ́ẹ̀, o lè wá sọ fún onítọ̀hún pé inú Bíbélì lo ti ń mú àwọn ọ̀rọ̀ ọlọgbọ́n tí ò ń bá a sọ látọjọ́ yìí. Fún un ní ìtẹ̀jáde kan tó o ronú pé ó máa nífẹ̀ẹ́ sí, èyí á sinmi lórí àwọn nǹkan tẹ́ ẹ ti jíròrò tẹ́lẹ̀ àti èrò onítọ̀hún nípa Bíbélì.—Wo àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti December 2013.