Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Múra Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Rẹ Sílẹ̀
Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì: Tí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ wa kò bá fa ẹni tá à ń wàásù fún mọ́ra, ó lè dá ọ̀rọ̀ mọ́ wa lẹ́nu, kó má sì jẹ́ ká wàásù fún òun. Nítorí náà, ọ̀pọ̀ àwọn akéde ló gbà pé ọ̀rọ̀ tá a bá fi bẹ̀rẹ̀ ìwàásù wa ló ṣe pàtàkì jù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àbá nípa bá a ṣe lè wàásù máa ń wà nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa àti nínú ìwé Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, kì í sábà kún rẹ́rẹ́, torí kí kálukú wa lè lo ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó máa fa ẹni tó fẹ́ wàásù fún mọ́ra. Ká tiẹ̀ wá sọ pé a rí àbá tó ní ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó kún tó, a lè pinnu láti yí i pa dà tàbí ká gbé ọ̀rọ̀ wa kalẹ̀ lọ́nà míì tó wù wá. Torí náà, ìwàásù wa máa túbọ̀ wọ àwọn èèyàn lọ́kàn tá a bá múra ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ wa sílẹ̀ dáadáa, dípò kó kàn jẹ́ pé ohunkóhun tó bá ṣáà ti wá sí wa lọ́kàn la máa sọ tá a bá fẹ́ wàásù fẹ́nì kan.—Òwe 15:28.
Gbìyànjú Èyí Lóṣù Yìí:
Nígbà Ìjọsìn Ìdílé yín, ẹ wáyè láti múra ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tẹ́ ẹ lè lò sílẹ̀ kí ẹ sì fi dánra wò.
Tó o bá wà lóde ẹ̀rí, sọ ohun tó o fẹ́ fi bẹ̀rẹ̀ ìwàásù rẹ fún àwọn akéde míì. (Òwe 27:17) Tó o bá rí i pé ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ kò gbéṣẹ́ tó, yí i pa dà.