Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ May 12
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MAY 12
Orin 49 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 7 ìpínrọ̀ 1 sí 8 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Ẹ́kísódù 27-29 (10 min.)
No. 1: Ẹ́kísódù 29:19-30 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Bí A Ṣe Lè Ní Ayọ̀—lr orí 17 (5 min.)
No. 3: Inú Ọlọ́run Ò Dùn Sí Kéèyàn Máa Ṣe Àmúlùmálà Ìsìn—td 5A (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
15 min: Gbogbo Àwọn Orílẹ̀-Èdè Yóò Máa Wọ́ Tìrítìrí Lọ Sórí Rẹ̀. (Aísá. 2:2) Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde méjì, kí ẹni àkọ́kọ́ jẹ́ ẹni tó ti wà nínú òtítọ́ fún ọ̀pọ̀ ọdún, kí èkejì sì jẹ́ ẹni tí kò tíì pẹ́ púpọ̀ tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Kí ló mú kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́? Àwọn ìṣòro wo ni wọ́n kojú? Kí ló wú wọn lórí nígbà àkọ́kọ́ tí wọ́n wá sí ìpàdé ìjọ? Kí ni wọ́n rántí nípa ìgbà àkọ́kọ́ tí wọ́n jáde òde ẹ̀rí? Báwo làwọn míì nínú ìjọ ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run?
15 min: “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Múra Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Rẹ Sílẹ̀.” Ìjíròrò. Ní ṣókí, ṣe àṣefihàn alápá méjì. Kí apá àkọ́kọ́ dá lórí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí akéde kan lò láìronú jinlẹ̀, kí apá kejì sì jẹ́ ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ti múra sílẹ̀ dáadáa. Bí àkókò bá ṣe wà sí, sọ àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú ìwé Jàǹfààní ojú ìwé 215 sí 219.
Orin 117 àti Àdúrà