Mímúra Bá A Ṣe Máa Lo Ìwé Ìròyìn Sílẹ̀
1. Kí nìdí tó fi dáa jù láti múra ọ̀nà tá a máa gbà gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀ tá a bá ń fi ìwé ìròyìn lọ àwọn èèyàn dípò ká kàn há àbá kan látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa sórí?
1 O lè máa béèrè pé, ‘Kí nìdí tá a tún fi ni láti múra bá a ṣe máa lo ìwé ìròyìn sílẹ̀ nígbà tó jẹ́ pé Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa máa ń gbé àbá jáde lóṣooṣù lórí ọ̀nà tá a lè gbà gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀?’ Bó tilẹ̀ jẹ́ pé irú ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a dábàá bẹ́ẹ̀ ti ṣèrànwọ́ fún ọ̀pọ̀, síbẹ̀ ó ṣì pọn dandan pé ká máa múra sílẹ̀. Ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó máa jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa wọ àwọn èèyàn létí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù kan lè máà wúlò ní ìpínlẹ̀ ìwàásù mìíràn. Nítorí náà, a ò gbọ́dọ̀ wá sọ ọ́ di dandan mọ́ra wa lọ́wọ́ láti máa há àwọn àbá náà sórí ká lè sọ ọ́ gẹ́lẹ́ bó ṣe wà níbẹ̀. Kódà bá a bá fẹ́ lo ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a dábàá, ohun tó dáa jù ni pé ká sọ ọ́ lọ́rọ̀ ara wa.
2. Kí làwọn nǹkan tó yẹ kó o ṣe láti lè mọ àpilẹ̀kọ tó o máa lò?
2 Yan Àpilẹ̀kọ Kan: Lẹ́yìn tó o bá ti ka ìwé ìròyìn náà tán, yan àpilẹ̀kọ kan tó o mọ̀ pó máa bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu tíwọ alára sì nífẹ̀ẹ́ sí. Bó o bá jẹ́ kí àlàyé rẹ lórí àpilẹ̀kọ náà fi hàn pé ohun tó ò ń sọ dá ọ lójú tó o sì sọ ọ́ bó ṣe rí lára ẹ, ó ṣeé ṣe kó o mú kó wu ẹni náà láti kà á. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àpilẹ̀kọ táwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín nífẹ̀ẹ́ sí lo máa fẹ́ lò, síbẹ̀ gbogbo àpilẹ̀kọ tó wà nínú ìwé ìròyìn náà ló yẹ kó yé ọ dáadáa. Èyí á jẹ́ kó o lè yí ọ̀rọ̀ rẹ padà bó o bá bá ẹnikẹ́ni pàdé tó ṣeé ṣe kó nífẹ̀ẹ́ sí kókó ọ̀rọ̀ mìíràn nínú ìwé ìròyìn yẹn.
3. Ọ̀nà wo lo ti rí pé ó dáa jù láti gbà nasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ káwọn èèyàn bàa lè gbọ́ ohun tó o fẹ́ sọ?
3 Bi Í Ní Ìbéèrè Kan: Ohun tó kàn ni pé kó o fara balẹ̀ múra ọ̀rọ̀ tó o máa kọ́kọ́ sọ. Ọ̀rọ̀ tó o máa kọ́kọ́ sọ ṣe pàtàkì o. Ó lè jẹ́ pé ohun tó máa rọ̀ ẹ́ lọ́rùn jù ni pé kó o bi ẹni náà ní ìbéèrè kan tó máa jẹ́ kó ronú jinlẹ̀, èyí táá jẹ́ kó nífẹ̀ẹ́ sí àpilẹ̀kọ tó o fẹ́ fi hàn án. Ó sábà máa ń dáa jù láti lo àwọn ìbéèrè tó máa jẹ́ kẹ́ni náà lè sọ èrò rẹ̀. Má ṣe bi í nípa àwọn nǹkan tó lè nira fún un láti dáhùn tàbí èyí tó lè mú kó jiyàn bóyá torí àtigba ara ẹ̀ kalẹ̀.
4. Àwọn àǹfààní wo ló wà nínú kéèyàn ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan fún ẹni téèyàn ń wàásù fún bí ààyè bá wà?
4 Ka Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Kan: Lákòótán, ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, bóyá ọ̀kan lára àwọn tó wà nínú àpilẹ̀kọ tó o fẹ́ fi hàn án, ìyẹn bí ipò tó o bá ẹni náà bá gbà bẹ́ẹ̀. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó o bá kà á jẹ́ kẹ́ni tó ò ń bá sọ̀rọ̀ rí i pé orí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ìwàásù wa dá lé. (1 Tẹs. 2:13) Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà á sì tún jẹ́rìí fún un kódà bó bá kọ̀ láti gba ìwé ìròyìn tó o fún un. Ọ̀pọ̀ ló ti jẹ́ kẹ́ni tí wọ́n ń bá sọ̀rọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wọn nítorí pé wọ́n kọ́kọ́ ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan kí wọ́n tó béèrè ìbéèrè pàtó kan lọ́wọ́ rẹ̀. O lè nasẹ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan nípa sísọ pé: “Á wù mí kó o sọ èrò rẹ lórí ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ.” Fi kókó tó bá a mu nínú ìwé ìròyìn náà hàn án kó o sì ṣàlàyé ráńpẹ́ tó máa mú kí ọkàn rẹ̀ fà sí i kó o tó fún un ní ìwé ìròyìn náà.
5. Ohun pàtàkì wo lo gbọ́dọ̀ máa fi sọ́kàn nígbà tó o bá ń múra sílẹ̀ láti lo ìwé ìròyìn?
5 Kò sí òfin kan tó sọ pé ọ̀rọ̀ kan pàtó lèèyàn gbọ́dọ̀ sọ nígbà téèyàn bá ń lo ìwé ìròyìn. Ohun tó ṣe pàtàkì ni pé kó o jẹ́ kí ọ̀nà tó o máa gbà gbé ọ̀rọ̀ ẹ kalẹ̀ rọrùn láti lóye kó sì ṣe ṣókí. Ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó bá rọ̀ ẹ́ lọ́rùn tó sì máa jẹ́ kẹ́ni tó ò ń bá sọ̀rọ̀ gba ìwé ìròyìn ni kó o lò. Máa jẹ́ káwọn èèyàn rí i pé àwọn ìwé ìròyìn wa ṣeyebíye gan-an, kó sì máa hàn nínú ọ̀nà tó o máa gbà sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Bó o bá múra sílẹ̀ dáadáa, wàá mọ bó ṣe yẹ kó o máa fún “àwọn tí wọ́n” ní “ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun,” ní ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí!—Ìṣe 13:48.