Máa Fáwọn Èèyàn Ní Ìwé Ìròyìn Tó Ń Jẹ́rìí sí Òtítọ́
1. Kí là ń lo Ilé Ìṣọ́ àti Jí! fún?
1 Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jèhófà àti ìwé ìròyìn tó ṣìkejì rẹ̀, ìyẹn Jí! ló ń múpò iwájú nínú àwọn ìwé tá à ń lò fún iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run àti sísọ àwọn èèyàn dọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 24:14; 28:19, 20) Inú wa máa ń dùn nígbà tá a bá ń fàwọn ìwé ìròyìn méjèèjì tó bágbà mu wọ̀nyí lọni, bá a ti ń kópa nínú onírúurú apá iṣẹ́ ìsìn Ìjọba Ọlọ́run.
2. Àwọn ìyípadà wo ló ti bá Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, kí ló sì fa àwọn ìyípadà náà?
2 Látìgbà tá a ti ń tẹ àwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyí, ìyípadà ti bá bí wọ́n ṣe tóbi sí, àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú wọn àti bá a ṣe ń lò wọ́n. Àwọn ìyípadà yìí ti jẹ́ kí ìrísí àwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyí túbọ̀ máa fani mọ́ra kí wọ́n sì wúlò gidigidi, kí ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run lè wọ “onírúurú ènìyàn” lọ́kàn “kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.”—1 Tím. 2:4.
3. Báwo la ṣe fẹ́ máa lo Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lóde ẹ̀rí?
3 Láti January ọdún 2006, a ti túbọ̀ já fáfá nínú lílo onírúurú ọ̀nà ìgbékalẹ̀ láti fi Jí! ẹlẹ́ẹ̀mẹrin lọ́dún lọni. Láti ìsinsìnyí lọ, onírúurú ọ̀nà ìgbékalẹ̀ náà la ó máa lò láti fi ọ̀kan ṣoṣo lára Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jèhófà tá à ń tẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì lóṣù lọni tá a bá ń wàásù láti ilé dé ilé. Onírúurú ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ lórí bá a ṣe lè fàwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyí lọni máa ń wà lójú ìwé tó gbẹ̀yìn nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Lọ́pọ̀ ìgbà àwọn àpilẹ̀kọ tó wà níbẹ̀rẹ̀ àwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyí ni ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ máa ń dá lé, àmọ́ nígbà míì a máa ń lo àwọn àpilẹ̀kọ tó bá fa àwọn èèyàn lọ́kàn mọ́ra. A lè lo àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tá a dábàá lọ́nà tó múná dóko tá a bá ka àpilẹ̀kọ tí wọ́n dá lé lórí dáadáa, tá a sì wá lo ọ̀rọ̀ ara wa láti fi gbé wọn kalẹ̀ lọ́nà tó máa bá ipò àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa mu.
4. Àǹfààní wo ló wà nínú lílo ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ míì tó yàtọ̀ sí ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tá a dábàá nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa?
4 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la dábàá sínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa fún ìwé ìròyìn kọ̀ọ̀kan, ẹ ò jayò pa tẹ́ ẹ bá lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tó yàtọ̀ séyìí tá a dábàá wọ̀nyẹn. Ìdí ni pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé lára àwọn àpilẹ̀kọ tá ò sọ bá a ṣe máa gbọ́rọ̀ inú ẹ̀ kalẹ̀ ló máa wúlò jù lọ fáwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Ó sì lè jẹ́ pé àpilẹ̀kọ tó o nífẹ̀ẹ́ sí jù lọ, tó o rò pó máa wọ onílé lọ́kàn lo fẹ́ kí ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ dá lé lórí.
5. Kí ló yẹ kó o ṣe kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí múra ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tó dá lórí ìwé ìròyìn tó o fẹ́ lò lóde ẹ̀rí?
5 Bó O Ṣe Lè Múra Ìgbékalẹ̀ Ọ̀rọ̀ Rẹ: Ohun àkọ́kọ́ ni pé kó o mọ tìfun tẹ̀dọ̀ àpilẹ̀kọ tó o fẹ́ lò. Àmọ́ ṣá o, ó lè má ṣeé ṣe fún ẹ láti mọ gbogbo àpilẹ̀kọ tó wà nínú ìwé ìròyìn kan dunjú kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó lóde ẹ̀rí. Síbẹ̀, fi ìtara sọ̀rọ̀ kó o má sì ṣe mẹ-in mẹ-in bó o bá ń ṣe ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tó dá lórí àpilẹ̀kọ tó o fẹ́ lò. Èyí lè má ṣeé ṣe tó ò bá lóye àwọn ìsọfúnni tó wà nínú àpilẹ̀kọ yẹn dáadáa.
6. Báwo la ṣe lè múra ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tiwa sílẹ̀?
6 Lẹ́yìn náà, rí i pé irú ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tó o múra ẹ̀ sílẹ̀ á ṣe é lò lóríṣiríṣi ọ̀nà. O lè bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìbéèrè tó máa wọ onílé lọ́kàn tó sì dá lórí àpilẹ̀kọ tó o fẹ́ lò. Kó o sì máa ní ìgbọ́kànlé pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lágbára láti wọni lọ́kàn. (Héb. 4:12) Wá ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, tó bá kókó tó o fẹ́ jíròrò mu sílẹ̀. Á dáa kó jẹ́ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nínú àpilẹ̀kọ tó o fẹ́ lò, yálà wọ́n fa ọ̀rọ̀ inú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà yọ tàbí wọn ò fà á yọ. Kó o wá wá bí wàá ṣe so ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà mọ́ àpilẹ̀kọ yẹn.
7. Báwo la ṣe lè jẹ́ kí ọ̀nà tá a gbà ń gbọ́rọ̀ kalẹ̀ sunwọ̀n sí i?
7 Máa Lò Ó ní Gbogbo Ìgbà: Tó o bá fẹ́ kí ọ̀nà tó o gbà ń gbọ́rọ̀ kalẹ̀ túbọ̀ dán mọ́rán sí i àfi kó o máa lò ó. Máa bá ìjọ jáde òde ẹ̀rí láti pín ìwé ìròyìn lọ́jọ́ Sátidé. O lè fáwọn tó ti ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa lọ́wọ́ níwèé ìròyìn. Máa fáwọn tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn míì tó o bá bá nílé nígbà tó o bá padà lọ sọ́dọ̀ wọn. O tún lè fún àwọn tó o bá bá pàdé lọ́jà, àwọn tẹ́ ẹ bá jọ wọkọ̀ tàbí àwọn tẹ́ ẹ jọ ń dúró de dókítà. Máa tún ọ̀nà tó o gbà ń gbọ́rọ̀ kalẹ̀ ṣe bó o ṣe ń lò ó jálẹ̀ oṣù yẹn.
8. Àwọn ọ̀nà wo ni Ilé Ìṣọ́ àti Jí! gbà jẹ́ ìwé ìròyìn tí kò lẹ́gbẹ́?
8 Kò sẹ́lẹgbẹ́ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! À ń lò wọ́n láti gbé Jèhófà ga gẹ́gẹ́ bí Ọba aláṣẹ ayé òun ọ̀run. (Ìṣe 4:24) Ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run tó wà nínú wọn ń tu àwọn èèyàn nínú, ó sì ń jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ gba Jésù Kristi gbọ́. (Mát. 24:14; Ìṣe 10:43) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn àlàyé tí wọ́n ń ṣe nípa bí ipò nǹkan ṣe ń yí padà láyé jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ń nímùúṣẹ. (Mát. 25:13) Ẹ ò rí i pé èyí tó nǹkan tá à ń múra sílẹ̀ fún dáadáa, káwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa lè jàǹfààní ẹ̀ bá a ṣe ń lò ó nígbàkigbà tá a bá bá wọn pàdé!
9. Kí la lè ṣe láti múra àwọn èèyàn sílẹ̀ fún ìpadàbẹ̀wò?
9 Tó o bá fún ẹnì kan ní ìwé ìròyìn, tàbí tó o kàn jíròrò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú ẹnì kan, gbára dì láti lo ìbéèrè tàbí gbólóhùn kan tó máa jẹ́ kó sọ tinú ẹ̀ jáde, tó o lè fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò nígbà tó o bá padà bẹ̀ ẹ́ wò tàbí tẹ́ ẹ bá tún jọ sọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti gbin òtítọ́ sáwọn èèyàn lọ́kàn, kò sí àníàní pé Jèhófà á jẹ́ kó dàgbà lọ́kàn àwọn tó fẹ́ mọ̀ ọ́n tí wọ́n sì fẹ́ sìn ín tọkàntọkàn.—1 Kọ́r. 3:6.