Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a ó lò lóṣù December: Ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí la máa lò. Àwọn ìwé àfirọ́pò ni ìwé Sún Mọ́ Jèhófà tàbí Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. January: Ẹ lè lo ìwé èyíkéyìí tó bá ti wà ṣáájú ọdún 1991 tàbí ìwé tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ tó bá wà lọ́wọ́. Ìwé míì tẹ́ ẹ lè lò bí àfirọ́pò ni ìwé Ìmọ̀ tàbí ìwé pẹlẹbẹ Ẹ Máa Ṣọ́nà! February: Ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. March: Ẹ lo ìwé Kí ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá gidigidi láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
◼ Kí ẹnì kan tí alága àwọn alábòójútó bá yàn ṣàyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ láwọn oṣù September, October àti November. Ẹni náà ò gbọ́dọ̀ máa jẹ́ ẹnì kan náà ṣáá. Bó bá ti parí àyẹ̀wò náà, ẹ ṣèfilọ̀ rẹ̀ fún ìjọ lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti ka ìròyìn ìnáwó ti oṣù tó ń bọ̀.—Ẹ wo ìwé tó ṣàlàyé nípa bó ṣe yẹ ká bójú tó àkáǹtì ìjọ, ìyẹn Instructions for Congregation Accounting (S-27).
◼ Ọjọ́ Thursday, April 9 la máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi lọ́dún 2009 lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀. Tó bá jẹ́ pé ìjọ tẹ́ ẹ jọ ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba pọ̀ gan-an tó fi jẹ́ pé ẹ lè máà ráyè ṣe tiyín ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, a fẹ́ kẹ́ ẹ tètè bẹ̀rẹ̀ sí ṣètò ibòmíì tẹ́ ẹ bá máa lò la ṣe tètè ṣèfilọ̀ yìí. Káwọn alàgbà jọ̀wọ́ tètè lọ rí àwọn tó ń bójú tó ibi tí ìjọ bá máa lò, kí wọ́n sì rí i dájú pé ètò ọ̀hún gún dáadáa àti pé kò ní sí ètò míì lọ́gbà yẹn tó máa fariwo dí Ìrántí Ikú Kristi lọ́wọ́ kí àwọn ará lè ṣe é ní ìrọ̀wọ́-rọsẹ̀.