ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/07 ojú ìwé 7
  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
km 12/07 ojú ìwé 7

Àtúnyẹ̀wò Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run

Àwọn ìbéèrè àtúnyẹ̀wò tó wà nísàlẹ̀ yìí la óò gbé yẹ̀ wò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run lọ́sẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ ní December 31, 2007. Àtúnyẹ̀wò yìí dá lórí àwọn iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ tá a ṣe lọ́sẹ̀ November 5 sí December 31, 2007, alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ yóò sì darí rẹ̀ fún ọgbọ̀n ìṣẹ́jú.

ÀNÍMỌ́ Ọ̀RỌ̀ SÍSỌ

1. Àwọn kókó wo ló yẹ ká fi sọ́kàn kí ìparí ọ̀rọ̀ wa bàa lè múná dóko? [be-YR ojú ìwé 220 ìpínrọ̀ 4 sí ojú ìwé 221 ìpínrọ̀ 3]

2. Kí la lè ṣe láti rí i dájú pé ọ̀rọ̀ tó jóòótọ́ délẹ̀ là ń sọ lóde ẹ̀rí? [be-YR ojú ìwé 223 ìpínrọ̀ 2 sí 4]

3. Nígbà tá a bá ń sọ̀rọ̀ ní ìpàdé ìjọ, báwo la ṣe lè fi hàn pé a fọwọ́ pàtàkì mú jíjẹ́ tí ìjọ jẹ́ “ọwọ̀n àti ìtìlẹ́yìn òtítọ́”? (1 Tím. 3:15) [be-YR ojú ìwé 224 ìpínrọ̀ 1 sí 4]

4. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa wádìí bóyá àwọn àlàyé tá a fẹ́ ṣe nínú ọ̀rọ̀ wa ṣeé gbára lé, báwo la sì ṣe lè ṣe é? [be-YR ojú ìwé 225 ìpínrọ̀ 1 sí 2]

5. Báwo la ṣe lè jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa tètè yé àwọn ẹlòmíì nígbà tá a bá ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́? [be-YR ojú ìwé 226 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 227 ìpínrọ̀ 1]

IṢẸ́ AKẸ́KỌ̀Ọ́ KÌÍNÍ

6. Àwọn ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú ìwé Jónà? [w89-YR 4/15 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 2 sí 5]

7. Àwọn ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú ìwé Míkà? [w89-YR 5/1 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 1 sí 7]

8. Àwọn ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú ìwé Hábákúkù? [w89-YR 5/15 ojú ìwé 25 ìpínrọ̀ 2 sí 5]

9. Àwọn ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú ìwé Hágáì? [w89-YR 6/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 5 sí 7]

10. Àwọn ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú ìwé Málákì? [w89-YR 7/1 ojú ìwé 31 ìpínrọ̀ 6]

BÍBÉLÌ KÍKÀ Ọ̀SỌ̀Ọ̀SẸ̀

11. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì nípa àwọn kòkòrò tó ya bolẹ̀ ṣe nímùúṣẹ ní ọ̀rúndún kìíní àti lóde òní? (Jóẹ́lì 2:1-10, 28) [w07-YR 10/1 “Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè—Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jóẹ́lì àti Ámósì”]

12. Kí ni “apẹ̀rẹ̀ èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn” túmọ̀ sí? (Ámósì 8:1, 2) [w07-YR 10/1 “Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè—Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jóẹ́lì àti Ámósì”]

13. Lọ́nà wo la fi lè gbà sọ pé Jèhófà ‘pèrò dà lórí ìyọnu àjálù tó ti sọ pé òun á mú bá àwọn ará Nínéfè,’ báwo ló sì ṣe kàn wá? (Jónà 3:10) [w03-YR 7/15 ojú ìwé 17 àti 18]

14. Kí ló túmọ̀ sí láti máa rìn ní orúkọ Jèhófà? (Míkà 4:5) [w03-YR 8/15 ojú ìwé 17 ìpínrọ̀ 19]

15. Ìgbà wo ni Jèhófà wá sí “tẹ́ńpìlì” rẹ̀ fún ìdájọ́, báwo ló sì ṣe wá? (Mál. 3:1-3) [re-YR ojú ìwé 32 àpótí; jd-YR ojú ìwé 179 ìpínrọ̀ 3 sí ojú ìwé 181 ìpínrọ̀ 6]

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́