ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 4/98 ojú ìwé 8
  • Àwọn Ìwé Ìròyìn Ń Kéde Ìjọba Náà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìwé Ìròyìn Ń Kéde Ìjọba Náà
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Wa Lọ́nà Tí Ó Dára Jù Lọ
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Máa Fi Ìwé Ìròyìn Lọni Tó O Bá Ń Wàásù
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí!—Àwọn Àkànṣe Ìwé-Ìròyìn Òtítọ́ Bíbọ́sákòókò
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Máa Fáwọn Èèyàn Ní Ìwé Ìròyìn Tó Ń Jẹ́rìí sí Òtítọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
km 4/98 ojú ìwé 8

Àwọn Ìwé Ìròyìn Ń Kéde Ìjọba Náà

1 Gẹ́gẹ́ bí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a mọ̀ wá dáadáa fún ìwàásù onítara wa nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tí a ń pín kiri ń kó ipa gíga lọ́lá nínú ríran àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn lọ́wọ́ láti mọ̀ nípa àwọn ète Ọlọ́run. Ìhìn iṣẹ́ tí ó wà nínú wọn jẹ́ ìhìn rere ní tòótọ́, nítorí ó ń kéde Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìrètí kan ṣoṣo fún aráyé.

2 Àwọn ìwé ìròyìn yìí ń sọ̀rọ̀ nípa àìní àwọn ènìyàn gan-an—ti èrò ìmọ̀lára, ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, àti tẹ̀mí. Bí ìwà rere àti ìjẹ́pàtàkì ìdílé ṣe ń wó lulẹ̀ níbi gbogbo, Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ń ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti mú kí ìgbésí ayé wọn sunwọ̀n sí i nípa fífi bí wọ́n ṣe lè fi ìlànà Bíbélì sílò hàn wọ́n. Inú wa yóò dùn láti fi àsansílẹ̀ owó ìwé ìròyìn lọni ní oṣù April àti May.

3 Wọ́n Fani Mọ́ra Gan-an: Ilé Ìṣọ́ àti Jí! fẹ́rẹ̀ẹ́ wà ní èdè tí gbogbo àwọn olùgbé ayé ń sọ. Nítorí èyí, a mọ àwọn ìwé ìròyìn wa dáadáa. Ìdí díẹ̀ tí wọ́n fi ń fa àwọn ènìyàn mọ́ra nìyí:

◼ Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn aláìlábòsí àti olóòótọ́, wọ́n ń fi ìyàtọ̀ hàn gbangba láàárín rere àti búburú.

◼ Wọ́n ń pèsè ìrètí nípa párádísè òdodo kan tí ń bọ̀, tí a gbé karí ìlérí Ọlọ́run láti mú ilẹ̀ ayé wá sábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba rẹ̀.

◼ Wọ́n ń gbé onírúurú àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ gbígbòòrò tí ó bá àkókò mu jáde, èyí tí ń fa àwọn ènìyàn láti onírúurú ipò àtilẹ̀wá àti àṣà mọ́ra.

◼ Àwọn àpilẹ̀kọ máa ń ṣe ṣókí, wọ́n ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, a gbé wọn karí òkodoro òtítọ́, láìní ẹ̀tanú àti àmúlùmálà.

◼ Àwọn àwòrán àrímáleèlọ ń fa ọkàn-ìfẹ́ mọ́ra lójú ẹsẹ̀, ọ̀nà ìkọ̀wé rírọrùn sì mú kí àwọn ìwé ìròyìn náà rọrùn láti kà.

4 Pín Wọn Kiri Lọ́nà Gbígbòòrò: Pípín ìwé ìròyìn kiri lọ́nà gbígbéṣẹ́ sinmi gidigidi lórí bí a bá ṣe jẹ́ aláápọn tó nínú mímúra àwọn ìgbékalẹ̀ wa sílẹ̀, ṣíṣètò àkókò wa, àti ṣíṣètò ìgbòkègbodò ìwàásù wa. A pèsè àwọn àbá gbígbéṣẹ́ nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti September 1995 àti October 1996, yóò dára kí a ṣàtúnyẹ̀wò wọn kí a sì fi wọ́n sílò.

5 Dojúlùmọ̀ Àwọn Ìwé Ìròyìn Náà: Bí o ti ń ka ìtẹ̀jáde kọ̀ọ̀kan, ronú nípa ẹni tí yóò mọrírì níní ẹ̀dà kan. Wá àwọn kókó pàtó tàbí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí o lè ṣàyọlò nínú ìgbékalẹ̀ rẹ. Ronú nípa ìbéèrè kan tí o lè béèrè láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò kí o sì ru ọkàn-ìfẹ́ sókè nínú kókó ẹ̀kọ́ náà.

6 Mú Kí Ìgbékalẹ̀ Bá Ẹni Náà Mu: Múra ìgbékalẹ̀ tí ó rọrùn, tí ó ṣe é yí padà tí o lè ṣàtúnṣe láti bá ọkùnrin, obìnrin, àgbà, èwe, mu yálà ojúlùmọ̀ tàbí àjèjì.

7 Jẹ́ Kí Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Jẹ Ọ́ Lọ́kàn: Níwọ̀n bí ó ti máa ń rọrùn fún ìwé ìròyìn láti gba inú àpò, àpamọ́wọ́, tàbí àpò ẹ̀wù, a lè kó àwọn ẹ̀dà dání nígbà tí a bá ń rìnrìn àjò tàbí nígbà tí a bá ń lọ rajà. Fi wọ́n lọni nígbà tí o bá ń bá àwọn ìbátan, aládùúgbò, alábàáṣiṣẹ́, akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni, tàbí olùkọ́ sọ̀rọ̀. Ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ fún ìjẹ́rìí ìwé ìròyìn.

8 Fi Ìmọrírì Hàn fún Àwọn Ìwé Ìròyìn: Ìjẹ́pàtàkì wọn kì í sọnù. Bí wọ́n ṣe pẹ́ sí kì í dín bí ìhìn iṣẹ́ tí ó wà nínú wọn ṣe ṣe pàtàkì tó kù. Ní tòótọ́, bí a bá ṣe ìsapá àkànṣe láti fi gbogbo ìwé ìròyìn tí a bá gbà sóde, kò yẹ kí àwọn ìtẹ̀jáde tí ó ti pẹ́ ṣẹ́ jọ sórí àwọn àpótí ìwé wa.

9 Ìjẹ́rìí Òpópónà Gbéṣẹ́: Èyí jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọ̀nà tí ó dára jù lọ láti fi àwọn ìwé ìròyìn lọ iye ènìyàn tí ó pọ̀ gidigidi. Àwọn akéde kan máa ń ṣiṣẹ́ déédéé ní àwọn òpópónà tí ó kún fọ́fọ́ ní ọjọ́ tí àwọn ènìyàn máa ń lọ rajà.

10 Ìpínlẹ̀ Iṣẹ́ Ajé Máa Ń Méso Jáde: Nígbà tí a bá ń jẹ́rìí láti ilé ìtajà dé ilé ìtajà, àwọn díẹ̀ ni a kì í bá. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn oníṣẹ́ ajé máa ń bọ̀wọ̀ fúnni, ọ̀pọ̀ sì máa ń fayọ̀ gba àwọn ìwé ìròyìn. Gbé àwọn àpilẹ̀kọ tí ó bá irú ibi iṣẹ́ ajé tí o ń kàn sí mu jáde lákànṣe.

11 Ó Ṣeé Ṣe Kí Àwọn Ipa Ọ̀nà Ìwé Ìròyìn Gbà Á: Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀mejì lóṣù ni a ń tẹ àwọn ìwé ìròyìn náà jáde, ó bá a mu láti padà dé ọ̀dọ̀ àwọn tí ó ń kà wọ́n kí a sì fi àwọn ìtẹ̀jáde tí ó tẹ̀ lé e lọ̀ wọ́n. Ó yẹ kí a máa ṣe ìpadàbẹ̀wò déédéé, kì í ṣe láti fi àwọn ìwé ìròyìn sóde nìkan ni, ṣùgbọ́n láti mú kí ọkàn-ìfẹ́ ẹni náà nínú Bíbélì dàgbà pẹ̀lú. Àwọn ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn jẹ́ orísun dídára jù lọ tí ó lè di ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

12 Lo Oṣù April àti May Lọ́nà Tí Ó Dára Jù Lọ: Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ti jèrè ìgbọ́kànlé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn òǹkàwé onímọrírì. Wọ́n gbéṣẹ́ gidigidi ní kíkéde Ìjọba náà tí ó fi jẹ́ pé ó yẹ kí a fi ṣe góńgó láti máa kó wọn dání kí a sì fi àsansílẹ̀ owó lọni ní gbogbo ìgbà tí àǹfààní bá ṣí sílẹ̀. Ǹjẹ́ kí oṣù April àti May jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ fún fífi àsansílẹ̀ owó ìwé ìròyìn lọni!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́