ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/96 ojú ìwé 3-5
  • Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Wa Lọ́nà Tí Ó Dára Jù Lọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Wa Lọ́nà Tí Ó Dára Jù Lọ
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Fi Ìwé Ìròyìn Lọni Tó O Bá Ń Wàásù
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Àwọn Ìwé Ìròyìn Ń Kéde Ìjọba Náà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Pẹ̀lú Àwọn Tó Ò Ń Fún Ní Ìwé Ìròyìn Déédéé
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
  • Fi Ìwé Ìròyìn Lọni ní Gbogbo Ìgbà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1995
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
km 3/96 ojú ìwé 3-5

Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Wa Lọ́nà Tí Ó Dára Jù Lọ

1 Nígbà tí o bá lọ sí ìdí àtẹ ìtàwé, kí ni o máa ń rí? Ìwé ìròyìn. Kí ní ń fa ojú rẹ mọ́ra lọ́dọ̀ òǹtàwé? Ìwé ìròyìn. Àwọn ènìyàn, àtọmọdé àtàgbà, ti bẹ̀rẹ̀ sí í ka ìwé ìròyìn. Ìwé ìròyìn ń jẹ aráyé lọ́kàn.

2 A ha lè sọ àwọn ènìyàn aláìlábòsí ọkàn di ẹni tí Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! ń jẹ lọ́kàn bí? Bẹ́ẹ̀ ni, bí ÀWÁ bá jẹ́ ẹni tí Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! ń jẹ lọ́kàn. Kí ní lè ràn wá lọ́wọ́? Gbé àwọn àbá wọ̀nyí yẹ̀ wò:

◼ Ka Àwọn Ìwé Ìròyìn Náà: Alábòójútó arìnrìn àjò kan ròyìn pé, ní ìpíndọ́gba, akéde 1 péré nínú 3, ní àyíká rẹ̀ ní ń ka ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! kọ̀ọ̀kan láti ìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí. Ìwọ́ ha ń ṣe bẹ́ẹ̀ bí? Bí o ti ń ka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan, bi ara rẹ léèrè pé, ‘Ta ni yóò mọrírì ìsọfúnni yìí—ìyá, oníṣẹ́ ajé, èwe kan ha ni bí?’ Nínú ẹ̀dà tìrẹ, fi àmì sí kókó kan tàbí méjì tí o lè lò nígbà tí o bá ń fi ìwé ìròyìn náà lọni. Lẹ́yìn náà, ronú bí o ṣe lè ru ọkàn-ìfẹ́ sókè nínú kókó ẹ̀kọ́ náà, ní gbólóhùn kan tàbí méjì.

◼ Ní Ìṣètò Gúnmọ́ fún Gbígba Ìwé Ìròyìn: Forúkọ sílẹ̀ lọ́dọ̀ arákùnrin tí ń bójú tó ìwé ìròyìn fún gbígba iye ẹ̀dà gúnmọ́ nínú ìtẹ̀jáde kọ̀ọ̀kan. Ní ọ̀nà yìí, ìwọ àti ìdílé rẹ yóò ní ìpèsè ìwé ìròyìn tí ó ṣe déédéé tí ó sì tó. Ìṣètò ìgbawé yìí yẹ kí ó ní ìwé ìròyìn lédè Gẹ̀ẹ́sì àti ní àwọn èdè míràn tí àwọn ènìyàn ń sọ ní ìpínlẹ̀ yín nínú.

◼ Ṣètò fún Ọjọ́ Ìwé Ìròyìn Tí Ó Ṣe Déédéé: Ọ̀pọ̀ ìjọ ti ya ọjọ́ kan pàtó sọ́tọ̀ fún ìjẹ́rìí ìwé ìròyìn ní pàtàkì. Ìwọ́ ha lè ti Ọjọ́ Ìwé Ìròyìn ìjọ lẹ́yìn bí? Bí o kò bá lè ṣe bẹ́ẹ̀, gbìyànjú láti lo àkókò fún iṣẹ́ ìsìn lóòrèkóòrè fún ìjẹ́rìí ìwé ìròyìn ní òpópónà àti pípín ìwé ìròyìn kiri fún àwọn ènìyàn, láti ilé dé ilé àti ní ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn.

◼ Jẹ́ Ẹni Tí “Ilé-Ìṣọ́nà” àti “Jí!” Ń Jẹ Lọ́kàn: Mú àwọn ẹ̀dà ìwé ìròyìn lọ́wọ́ nígbà tí o bá ń rìnrìn àjò tàbí nígbà tí o bá ń lọ rajà. Fi wọ́n lọni bí o ti ń bá àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ, àwọn aládùúgbò rẹ, àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ, tàbí àwọn olùkọ́ sọ̀rọ̀. Tọkọtaya kan tí wọ́n sábà máa ń rìnrìn àjò nínú ọkọ̀ òfuurufú máa ń lo kókó kan nínú ọ̀kan lára àwọn ìwé ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú ẹni tí ó bá jókòó tì wọ́n. Wọ́n ti gbádùn ọ̀pọ̀ ìrírí tí ń múni lọ́kàn yọ̀. Àwọn ọ̀dọ́ kan máa ń mú àwọn ẹ̀dà tí wọ́n ronú pé àwọn olùkọ́ tàbí àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn yóò nífẹ̀ẹ́ sí lọ sí ilé ẹ̀kọ́ déédéé. Mú àwọn ẹ̀dà lọ́wọ́ nígbà tí o bá ń lọ ra nǹkan, kí o sì fi wọ́n lọ àwọn oníṣòwò náà nígbà tí o bá parí ohun tí o bá wá. Ọ̀pọ̀ nínú wa máa ń ra epo mọ́tò déédéé; èé ṣe tí a kò fi àwọn ìwé ìròyìn lọ àwọn tí wọ́n ń ta epo fún wa? Jẹ́ kí wọ́n wà lárọ̀ọ́wọ́tó nígbà tí àwọn mọ̀lẹ́bí bá ṣèbẹ̀wò, nígbà tí o bá wọ ọkọ̀ èrò, tàbí nígbà tí o bá ń dúró láti rí ẹnì kan. O ha lè ronú àwọn àkókò yíyẹ mìíràn bí?

◼ Múra Ìgbékalẹ̀ Kúkúrú fún Fífi Ìwé Ìròyìn Lọni Sílẹ̀: Wéwèé láti sọ ọ̀rọ̀ díẹ̀, ṣùgbọ́n kí o sọ ọ́ dáradára. Jẹ́ onítara ọkàn. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ wọni lọ́kàn. Ṣe ṣàkó. Fa èrò kan jáde nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ kan, ṣàlàyé rẹ̀ ní ṣókí, kí o sì fi àwọn ìwé ìròyìn náà lọni. Ọ̀nà tí ó dára jù lọ láti gbé wọn kalẹ̀ ni láti gbé ìbéèrè dìde lórí kókó ẹ̀kọ́ kan tí ó fani mọ́ra, kí o sì wá tọ́ka sí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó dáhùn ìbéèrè náà ní ìbámu pẹ̀lú Ìwé Mímọ́. Gbé díẹ̀ lára àwọn àpẹẹrẹ bí a ṣe lè ṣe èyí yẹ̀ wò:

3 Bí ó bá jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ kan lórí bí ìwà ọ̀daràn ti ń peléke sí i ni o ń gbé jáde, o lè sọ pé:

◼ “Kí ni a nílò láti mú kí ó ṣeé ṣe fún wa láti lè sùn ní alẹ́ láìbẹ̀rù ìwà ọ̀daràn?” Onílé náà lè ṣàìfojú sọ́nà pé nǹkan yóò dára. O lè dáhùn pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ó ń ronú lọ́nà kan náà, sì fi kún un pé o ní ìsọfúnni kan tí o gbà gbọ́ pé yóò nífẹ̀ẹ́ sí. Lẹ́yìn náà, tọ́ka sí kókó kan tí ó bá a mu nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà.

4 Nígbà tí o bá ń fi ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ lórí ìgbésí ayé ìdílé lọni, o lè sọ pé:

◼ “Ọ̀pọ̀ ènìyàn ń rí i pé ìpèníjà ńlá ni ó jẹ́ láti rí owó gbọ́ bùkátà àti láti tọ́ àwọn ọmọ ní òde òní. Ọ̀pọ̀ ìwé ni a ti kọ lórí kókó ẹ̀kọ́ yìí, ṣùgbọ́n àwọn ìjìmì pàápàá kò fohùn ṣọ̀kan lórí ojútùú sí àwọn ìṣòro wa. Ibì kan ha wà tí a lè yíjú sí fún ìtọ́sọ́nà tí ó ṣeé gbára lé bí?” Lẹ́yìn náà, tọ́ka sí kókó kan pàtó nínú ìwé ìròyìn náà tí ó fi ọgbọ́n tí a rí nínú Bibeli hàn.

5 O lè lo ìyọsíni yìí, nígbà tí o bá ń gbé ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ kan lórí ìṣòro ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà jáde lákànṣe:

◼ “Ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ó wà lábẹ́ ìkìmọ́lẹ̀ lónìí. Ọlọrun kò fìgbà kan rí pète pé kí a gbé ìgbésí ayé ní ọ̀nà yìí.” Lẹ́yìn náà, fi bí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí a gbé ka orí Bibeli, tí ó wà nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ nísinsìnyí láti kojú àwọn ìṣòro inú ìgbésí ayé, kí ó sì pèsè ìrètí fún ojútùú wíwà pẹ́ títí ní ọjọ́ iwájú.

6 Ìjẹ́rìí Òpópónà Gbéṣẹ́: Nínú ìtẹ̀jáde Informant (Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa) ti January 1940 ni a ti kọ́kọ́ fún àwọn akéde níṣìírí láti ṣètò fún ọjọ́ àkànṣe kan lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ fún ìjẹ́rìí òpópónà ní lílo àwọn ìwé ìròyìn. Ìwọ ha máa ń lọ́wọ́ nínú ìjẹ́rìí òpópónà láti ìgbà dé ìgbà bí? Bí o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀nà tí o ń lò ha gbéṣẹ́ ní tòótọ́ bí? A ti kíyè sí àwọn akéde kan, tí wọ́n ń dúró sí igun òpópónà tí ó kún fún èrò, tí wọ́n ń rojọ́, láìkọbiara sí ọ̀pọ̀ èrò tí ń kọjá lọ. Dípò dídúró pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìwé ìròyìn lọ́wọ́, ó túbọ̀ gbéṣẹ́ láti pínyà, kí ẹ sì tọ àwọn ènìyàn lọ. Àwọn àjèjì lè dúró, kí wọ́n sì rọra fetí sílẹ̀, bí ó bá jẹ́ pé ẹnì kan ṣoṣo ni ó tọ̀ wọ́n wá, ṣùgbọ́n kì í ṣe ọ̀pọ̀ ènìyàn ni ó lè lo àtinúdá láti tọ àwùjọ tí ọ̀rọ̀ ti wọ̀ lára lọ. Níwọ̀n bí a ti máa ń pe ọ̀pọ̀ àfiyèsí ní òpópónà, àìní àkànṣe wà fún wa láti múra dáradára, kí a sì wọṣọ níwọ̀ntúnwọ̀nsì bí ó ti yẹ àwọn òjíṣẹ́ Ọlọrun.—1 Tim. 2:9, 10.

7 Ipa Ọ̀nà Ìwé Ìròyìn: Àwọn tí ó ní ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn máa ń fi ọ̀pọ̀ ìwé ìròyìn síta, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, a máa ń kárí àwọn ìpínlẹ̀ náà déédéé. Ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn jẹ́ orísun títayọ lọ́lá fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé lọ́jọ́ iwájú.

8 Nígbà tí o bá ṣe ìpadàbẹ̀wò déédéé láti fi àwọn ìwé ìròyìn fúnni, ìwọ yóò rí i pé ẹ̀mí ọ̀yàyà àti ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tí ó wà láàárín ìwọ àti onílé náà yóò máa gbèrú sí i. Bí ẹ bá ti túbọ̀ ń di ojúlùmọ̀ ara yín sí i tó, bẹ́ẹ̀ ni yóò túbọ̀ máa rọrùn fún yín tó láti jíròrò pa pọ̀ lórí àwọn kókó ọ̀rọ̀ láti inú Ìwé Mímọ́. Èyí lè ṣamọ̀nà sí bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli inú ilé tí ó méso jáde. Fi àsansílẹ̀-owó lọni ní àwọn ìpadàbẹ̀wò tí ó ti hàn kedere pé a ní ìmọrírì fún àwọn ìwé ìròyìn náà. Sì rántí pé, o lè ròyìn ìpadàbẹ̀wò ní gbogbo ìgbà tí o bá lọ rí onílé náà.

9 Arábìnrin kan máa ń mú àwọn ìwé ìròyìn lọ fún obìnrin kan tí ó máa ń gbà wọ́n ní gbogbo ìgbà, ṣùgbọ́n tí ó máa ń wí pé: “Èmi kò gba ohun tí o ń sọ fún mi gbọ́.” Nígbà ìbẹ̀wò kan, arábìnrin náà bá ọkọ rẹ̀ nílé. Lẹ́yìn sísọ̀rọ̀ bí ọ̀rẹ́, wọ́n ṣètò láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Arábìnrin náà bá àwọn ọmọkùnrin wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí wọ́n dara pọ̀ nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ṣọ̀rẹ́. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ìyá náà àti àwọn ọmọ rẹ̀ ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jehofa, a sì batisí wọn. Di báyìí, àwọn ẹni 35 nínú ìdílé wọn ni ó ti tẹ́wọ́ gba òtítọ́. Gbogbo èyí jẹ́ nítorí pé arábìnrin náà padà ṣiṣẹ́ lórí ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn rẹ̀!

10 Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni ó wà tí a lè gbà bẹ̀rẹ̀ ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn. O lè bẹ̀rẹ̀ ipa ọ̀nà kan nípa wíwulẹ̀ pa àkọsílẹ̀ àwọn ìwé ìròyìn tí o fi síta mọ́, kí o sì ṣètò láti padà lọ lọ́sẹ̀ méjì méjì pẹ̀lú àwọn ẹ̀dà tí ó dé kẹ́yìn. Lílo ìsọfúnni abẹ́ ìsọ̀rí náà “Nínú Ìtẹ̀jáde Wa Tí Ń Bọ̀” jẹ́ ọ̀nà kan. Nígbà tí o bá padà lọ, sọ fún onílé náà pé o ní ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí o mẹ́nu kàn ní ìṣáájú lọ́wọ́. Tàbí, nígbà tí o bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò, o lè sọ pé: “Nígbà tí mo ka ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí, mo ronú pé ìwọ́ lè nífẹ̀ẹ́ sí i . . .” Lẹ́yìn náà, ṣàlàyé ṣókí lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà kí o sì fi lọ̀ ọ́. Lẹ́yìn tí o bá ti parí ìbẹ̀wò náà, kọ àwọn kókó rírọrùn márùn-ún sórí àkọsílẹ̀ ilé-dé-ilé rẹ: (1) orúkọ onílé, (2) àdírẹ́sì onílé, (3) ọjọ́ ìbẹ̀wò, (4) àwọn ìtẹ̀jáde tí o fi síta, àti (5) ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí o gbé jáde lákànṣe. Àwọn akéde kan ti ṣàṣeyọrí gidi nínú níní ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn, tí wọ́n ń ní tó 40 tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ láti ké sí!

11 Àwọn Agbègbè Iṣẹ́ Ajé: Àwọn akéde tí ń wàásù ní àwọn agbègbè iṣẹ́ ajé máa ń fi àwọn ìwé ìròyìn púpọ̀ síta. O ha ti gbìyànjú ṣíṣiṣẹ́ láti ìsọ̀ dé ìsọ̀ bí? Ìròyìn fi hàn pé ní àwọn ìjọ kan, ìkópa nínú ẹ̀ka iṣẹ́ ìsìn yìí kéré jọjọ. Ní ìbẹ̀rẹ̀, àwọn kan ń bẹ̀rù láti lọ wàásù fún àwọn oníṣẹ́ ajé, ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí wọ́n gbìyànjú rẹ̀ wò fún ìgbà díẹ̀, wọ́n rí i pé ó lárinrin, ó sì ń mérè wá. Èé ṣe tí o kò sọ fún akéde onírìírí kan tàbí aṣáájú ọ̀nà kan láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀?

12 Ọ̀pọ̀ àǹfààní ni ó wà nínú ṣíṣiṣẹ́ láti ìsọ̀ dé ìsọ̀. Àwọn díẹ̀ ni kì í sí nísọ̀, pàápàá ní àwọn àkókò iṣẹ́! Àwọn oníṣẹ́ ajé sábà máa ń ṣàyẹ́sí ènìyàn, àní bí wọn kò bá tilẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ lọ́kàn-ìfẹ́ nínú Bibeli. Bẹ̀rẹ̀ ní òwúrọ̀ kùtù; ó ṣeé ṣe kí a tẹ́wọ́ gbà ọ́ dáradára. Lẹ́yìn sísọ ẹni tí o jẹ́, o lè sọ pé ó máa ń ṣòro fún ọ láti rí àwọn oníṣẹ́ ajé nílé, nítorí náà ni o ṣe ń bẹ̀ wọ́n wò fún àkókò díẹ̀ ní ibi iṣẹ́ wọn láti fi ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! tí ó dé kẹ́yìn lọ̀ wọ́n. Ṣàlàyé pé púpọ̀ nínú àwọn oníṣẹ́ ajé mọrírì àwọn ìwé ìròyìn wa nítorí pé wọ́n gbọ́dọ̀ mọ ohun tí ń lọ lọ́wọ́ nínú ayé, ṣùgbọ́n wọn kò ní àkókò tí ó pọ̀ tó láti kàwé. Àwọn ìwé ìròyìn náà máa ń gbé àwọn ìsọfúnni tí ń múni ronú kalẹ̀ lọ́nà àkọ̀tun, láìsí ẹ̀tanú ìsìn, ti òṣèlú, tàbí ti ìṣòwò. A lè bẹ̀rẹ̀ ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn pẹ̀lú àwọn olùfìfẹ́hàn tí a rí ní agbègbè iṣẹ́ ajé.

13 Ẹ Múra Sílẹ̀ Gẹ́gẹ́ bí Ìdílé Kan: Ẹ lè ya àkókò kan sọ́tọ̀ nígbà tí ẹ bá ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé láti jíròrò àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ inú àwọn ìwé ìròyìn tí ó dé kẹ́yìn tí ó lè bá a mu láti lò ní ìpínlẹ̀ yín. Àwọn mẹ́ḿbà ìdílé—títí kan àwọn ọmọdé—lè ṣe ìfidánrawò àwọn ìgbékalẹ̀ wọn, kí wọ́n sì ṣẹ́pá àwọn àtakò tí a sábà máa ń gbé dìde, irú bí: “Ọwọ́ mí dí,” “A ní ìsìn tiwa,” tàbí “Èmi kò lọ́kàn-ìfẹ́ sí i.” Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tí ó dára lè mú kí ó ṣeé ṣe fún gbogbo ìdílé láti ṣàjọpín déédéé nínú pípín ìwé ìròyìn.

14 Àwọn Olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ Lè Ṣèrànwọ́: Nígbàkigbà tí ó bá ti ṣeé ṣe, ẹ ṣètò àwọn ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn ní Ọjọ́ Ìwé Ìròyìn sí àwọn ibi tí ẹ ti ń pàdé fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ, dípò jíjẹ́ kí gbogbo ìjọ pé jọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Àwọn tí ń bójú tó àwọn ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá ní láti múra sílẹ̀ dáradára, kí wọ́n sì ní àwọn àbá gúnmọ́ fún àwùjọ náà. Àwọn àbá wọ̀nyí lè ní àpẹẹrẹ ìgbékalẹ̀ kan àti kókó kan tàbí méjì láti inú àwọn ìtẹ̀jáde ti lọ́ọ́lọ́ọ́ tí a lè lò láti ru ọkàn-ìfẹ́ sókè ní àdúgbò nínú. Ìpàdé fún iṣẹ́ ìsìn pápá—títí kan ṣíṣètò àwùjọ—ní láti ṣe ṣókí, kí ó má sì ju ìṣẹ́jú 10 sí 15 lọ. Àwọn olùdarí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ ní láti rí i dájú pé a ní àwọn ìpínlẹ̀ tí ó pọ̀ tó láti ṣiṣẹ́, kí ọwọ́ àwùjọ náà lè dí ní gbogbo àkókò iṣẹ́ ìsìn pápá náà. Lẹ́yìn náà, a lè gbàdúrà ṣáájú tàbí lẹ́yìn tí a bá ti pín àwọn akéde láti bá ara wọn ṣiṣẹ́.

15 Fi Ìmọrírì Hàn fún Àwọn Ìwé Ìròyìn Náà: Ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ náà, “Lílo Ilé-Ìṣọ́nà ati Jí! Lọna Rere,” tí a tẹ̀ jáde nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti July 1993, sọ kókó pàtàkì yìí: “Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! kò padanu iniyelori wọn, àní bi a kò bá tíì fi gbogbo wọn sode laaarin oṣu kan tabi meji si ìgbà ti a tẹ̀ wọn jade paapaa. Isọfunni ti wọn ní ninu kò dinku ni ijẹpataki nitori akoko ti o ti kọja . . . Jijẹ ki awọn iwe-irohin ti o ti pẹ́ sẹ́jọ láláìlò wọn rara fi aini imọriri hàn fun awọn ohun-eelo iyebiye wọnyi. . . . Dipo yíyọ awọn itẹjade ti o ti pẹ́ silẹ ki a sì gbagbe nipa wọn, kò ha ni dara ju lati lo isapa akanṣe lati fi wọn sode lọdọ awọn olufifẹhan bi?”

16 Ọ̀pọ̀ àwọn aláìlábòsí ọkàn wà lónìí tí ń wá òtítọ́ kiri. Ìsọfúnni tí ó wà nínú ìwé ìròyìn kan ṣoṣo lè jẹ́ ohun gan-an tí wọ́n nílò láti ṣamọ̀nà wọn sínú òtítọ́! Jehofa ti fún wa ní ìhìn iṣẹ́ alárinrin láti pòkìkí, àwọn ìwé ìròyìn wa sì ń kó ipa pàtàkì nínú mímú ìhìn iṣẹ́ náà dé ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Ìwọ yóò ha jẹ́ kí pípín ìwé ìròyìn kiri túbọ̀ jẹ ọ́ lọ́kàn ní ọjọ́ iwájú bí? Ìwọ yóò ha lo díẹ̀ lára àwọn àbá wọ̀nyí ní òpin ọ̀sẹ̀ tí a wà yìí bí? A óò bù kún ọ ní jingbinni bí o bá ṣe bẹ́ẹ̀.

Àwọn Àbá Gbígbéṣẹ́:

◼ Ka àwọn ìwé ìròyìn náà ṣáájú àkókò, kí o sì dojúlùmọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ inú wọn.

◼ Yan ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ohun kan tí àwọn ènìyàn àdúgbò rẹ máa ń nífẹ̀ẹ́ sí.

◼ Múra ìgbékalẹ̀ kan tí yóò bá onírúurú ènìyàn mu, bí ọkùnrin, obìnrin, tàbí àwọn èwe. Fi bí ìwé ìròyìn náà ṣe kan onílé náà hàn án, àti bí gbogbo ìdílé yóò ṣe gbádùn rẹ̀.

◼ Wéwèé láti nípìn-ín nínú ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn pápá nígbà tí èyí tí ó pọ̀ jù lọ lára àwọn ènìyàn bá wà nílé. Àwọn ìjọ kan máa ń ṣètò fún ìjẹ́rìí ìrọ̀lẹ́ pẹ̀lú àwọn ìwé ìròyìn.

◼ Jẹ́ kí ìgbékalẹ̀ rẹ ṣe ṣókí, kí ó sì sọ ojú abẹ níkòó.

◼ Má ṣe sáré sọ̀rọ̀. Bí olùgbọ́ rẹ kò bá fìfẹ́ hàn, sísáré sọ̀rọ̀ kì í yóò ṣèrànwọ́. Gbìyànjú láti sinmẹ̀dọ̀, kí o sì fún onílé láǹfààní láti fèsì.

◼ Mú kí ìwé ìròyìn ní àwọn èdè míràn wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún àwọn ènìyàn tí yóò nílò wọn.

Fífi Àwọn Ìwé Ìròyìn Lọni Láti Ilé dé Ilé:

◼ Rẹ́rìn-ín músẹ́ bí ọ̀rẹ́ kí o sì sọ̀rọ̀ jẹ́jẹ́.

◼ Jẹ́ onítara ọkàn nípa àwọn ìwé ìròyìn náà.

◼ Sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ kí ó sì ṣe ketekete.

◼ Sọ̀rọ̀ lórí kókó ẹ̀kọ́ kan ṣoṣo; ru ọ̀kan-ìfẹ́ sókè nínú rẹ̀, kí o sì fi ìníyelórí rẹ̀ han onílé.

◼ Tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ kan ṣoṣo.

◼ Sọ̀rọ̀ lórí ìwé ìròyìn kan ṣoṣo, ní fífi èkejì kún un gẹ́gẹ́ bí amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.

◼ Fi àwọn ìwé ìròyìn náà lé onílé lọ́wọ́.

◼ Jẹ́ kí onílé náà mọ̀ pé o wéwèé láti padà wá.

◼ Parí ọ̀rọ̀ rẹ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ bí ọ̀rẹ́ àti ìgbéniró, bí a kò bá gba àwọn ìwé ìròyìn náà.

◼ Kọ orúkọ gbogbo àwọn tí ó fi ìfẹ́ hàn àti àwọn ìwé tí o fi síta sílẹ̀ sínú àkọsílẹ̀ ilé-dé-ilé rẹ.

Àwọn Àǹfààní Tí Ó Ń Ṣí Sílẹ̀ Láti Fi Àwọn Ìwé Ìròyìn Lọni:

◼ Ìjẹ́rìí ilé-dé-ilé

◼ Ìjẹ́rìí òpópónà

◼ Iṣẹ́ ìsọ̀-dé-ìsọ̀

◼ Ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn

◼ Ìjẹ́rìí ìrọ̀lẹ́

◼ Nígbà tí a bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò

◼ Ṣíṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli àtijọ́

◼ Nígbà tí a bá ń rìnrìn àjò, tí a bá ń lọ rajà

◼ Nígbà tí a bá ń bá àwọn mọ̀lẹ́bí, àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni, àwọn aládùúgbò, àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni, àwọn olùkọ́ sọ̀rọ̀

◼ Nínú ọkọ̀ èrò, nínú àwọn iyàrá tí a ti ń dúró láti rí ẹnì kan

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́