ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 2/05 ojú ìwé 8
  • Máa Fi Ìwé Ìròyìn Lọni Tó O Bá Ń Wàásù

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Fi Ìwé Ìròyìn Lọni Tó O Bá Ń Wàásù
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Wa Lọ́nà Tí Ó Dára Jù Lọ
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Àwọn Ìwé Ìròyìn Ń Kéde Ìjọba Náà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí!—Àwọn Àkànṣe Ìwé-Ìròyìn Òtítọ́ Bíbọ́sákòókò
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ṣàṣàyàn Àwọn Àpilẹ̀kọ Láti Fi Fa Àwọn Ènìyàn Mọ́ra Lórí Ohun Tí Wọ́n Ní Ọkàn-Ìfẹ́ sí Ní Pàtó
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
km 2/05 ojú ìwé 8

Máa Fi Ìwé Ìròyìn Lọni Tó O Bá Ń Wàásù

1, 2. Báwo ni Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ṣe yí àwọn èèyàn lọ́kàn padà?

1 “Wọ́n máa ń gbádùn mọ́ni, wọ́n ń bọ́ sákòókò, wọ́n sì ń gbéni ró.” “Àwọn ni ìwé ìròyìn tí ń gbéni ró jù lọ tí mo tíì kà rí.” Àwọn gbólóhùn yìí jẹ́ ká mọ ojú táwọn òǹkàwé jákèjádò ayé fi ń wo Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Ká sòótọ́, àwọn ìwé ìròyìn wa wúlò gan-an, torí pé wọ́n ń jẹ́ kí ìhìn rere détígbọ̀ọ́ “gbogbo onírúurú ènìyàn.”—1 Tím. 2:4.

2 Ọkùnrin oníṣòwò kan gba ìwé ìròyìn Jí! kan tó sọ̀rọ̀ lórí kókó kan tó fẹ́ràn gan-an. Lẹ́yìn èyí, ó ka Ilé Ìṣọ́ tó gbà pa pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, èyí tó ní àpilẹ̀kọ kan tó mú kó ronú jinlẹ̀ lórí ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan tó ti gbà gbọ́ láti kékeré. Ohun tó kà yìí jẹ́ kí òùngbẹ òtítọ́ túbọ̀ máa gbẹ ẹ́ sí i. Oṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà ló ṣèrìbọmi. Ọkùnrin mìíràn tún wà tó máa ń gba ìwé ìròyìn wa déédéé àmọ́ kì í kà wọ́n. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyàwó rẹ̀ kì í fẹ́ rí àwọn Ẹlẹ́rìí sójú, òun ní tirẹ̀ máa ń ka àwọn ìwé ìròyìn tí ọkọ rẹ̀ bá gbà. Ìlérí tí Bíbélì ṣe nípa Párádísè orí ilẹ̀ ayé, níbi táwọn olódodo yóò máa gbé, wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, obìnrin náà, ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti àbúrò obìnrin náà di ìránṣẹ́ Jèhófà.

3. Kí ni àǹfààní tó wà nínú fífi ìwé ìròyìn méjèèjì lọni pa pọ̀?

3 Fi Méjèèjì Lọni Pa Pọ̀: Àwọn àpẹẹrẹ òkè yìí jẹ́ ká rí i pé a ò lè sọ pé ẹni báyìí ló máa ka àwọn ìwé ìròyìn wa tàbí ẹni báyìí ni ò ní kà á, àti pé a ò lè mọ ohun táwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ sí nínú wọn. (Oníw. 11:6) Nítorí náà, ńṣe ló yẹ ká máa fi Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọni pa pọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀kan lára wọn la máa sọ̀rọ̀ lé lórí tá a bá ń fi wọ́n lọni. Láwọn ìgbà míì, ó máa dára ká fi oríṣiríṣi ìwé ìròyìn lọ àwọn èèyàn lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.

4. Ètò wo la lè ṣe ká lè máa lọ pín ìwé ìròyìn?

4 Ó dára ká máa ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ tí a ó fi máa lọ pín ìwé ìròyìn. Nínú kàlẹ́ńdà ọdún yìí, 2005 Calendar of Jehovah’s Witnesses, gbogbo ọjọ́ Saturday la pè ní “Ọjọ́ Pínpín Ìwé Ìròyìn.” Síbẹ̀, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé bí nǹkan ṣe rí lágbègbè kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ síra, àti pé ohun tó rọrùn fún ẹnì kan lè má rọrùn fún ẹlòmíràn, àwọn akéde kan lè ya ọjọ́ mìíràn sọ́tọ̀ láti fi pín àwọn ìwé ìròyìn wa. Ǹjẹ́ iṣẹ́ pínpín ìwé ìròyìn wà lára ohun tó o máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀?

5. Àwọn àǹfààní wo la lè lò láti fi ìwé ìròyìn lọni, kí ló sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti lo àǹfààní wọ̀nyí?

5 Pinnu Iye Ìwé Ìròyìn Tó O Fẹ́ Máa Fi Síta: Bí a bá pinnu iye ìwé ìròyìn tá a fẹ́ máa fi síta lóṣooṣù, a ó lè túbọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀ràn fífi ìwé ìròyìn síta. Ǹjẹ́ ẹnì kan wà tó o máa ń fún ní ìwé ìròyìn déédéé? Ǹjẹ́ o máa ń fi ìwé ìròyìn lọ àwọn èèyàn tó o bá bá pàdé lóde ẹ̀rí? Ǹjẹ́ o lè máa fi ìwé ìròyìn lọ àwọn èèyàn nígbà tó o bá ń wàásù ní òpópónà, níbi táwọn èèyàn ti ń ṣiṣẹ́ ajé, tàbí láwọn ibi tí èrò máa ń pọ̀ sí? Ǹjẹ́ o máa ń kó ìwé ìròyìn dání nígbà tó o bá ń rìnrìn àjò, nígbà tó o bá ń lọ rajà, tàbí nígbà tó o bá ń lọ sáwọn ibòmíràn? Lo gbogbo àǹfààní tó o bá ní láti fi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè jàǹfààní nínú Ilé Ìṣọ́ àti Jí!

6. Báwo la ṣe lè lo àwọn ìwé ìròyìn wa tí ọjọ́ wọn ti pẹ́?

6 Síwájú sí i, a lè pinnu pé a fẹ́ máa fi àwọn ìwé ìròyìn wa tí ọjọ́ wọn ti pẹ́ tá a bá ní lọ́wọ́ síta. Kódà bí kò bá ṣeé ṣe láti fi ìwé ìròyìn síta láàárín oṣù kan tàbí méjì lẹ́yìn tá a ti tẹ̀ ẹ́ jáde, ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ṣì wúlò. Ẹ jẹ́ ká fún àwọn olùfìfẹ́hàn wa láwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyí. “Ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó tọ́” ni ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! jẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn. (Òwe 25:11) Ẹ jẹ́ ká lò wọ́n láti fi túbọ̀ ran ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn sí i lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ Jèhófà kí wọ́n sì wá sìn ín.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́