Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí!—Àwọn Àkànṣe Ìwé-Ìròyìn Òtítọ́ Bíbọ́sákòókò
“Ìwọ ni o ti rà mí padà, Oluwa Ọlọrun òtítọ́.”—ORIN DAFIDI 31:5.
1, 2. (a) Báwo ni ìmọ̀lára arábìnrin kan ti rí nípa ohun kan tí ó kà nínú Ilé-Ìṣọ́nà? (b) Àwọn ìbéèrè wo ni a béèrè nípa àwọn àkànṣe ìwé-ìròyìn wa?
KRISTIAN arábìnrin kan kọ̀wé pé: “Ẹ ṣeun lọ́pọ̀lọpọ̀ fún ìsọfúnni àgbàyanu tí ń bẹ nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ Ilé-Ìṣọ́nà ‘Iwọ Lè Ri Itunu Ni Awọn Akoko Idaamu.’a Ọ̀pọ̀ nínú àwọn kókó tí ẹ mú jáde ni àwọn ìmọ̀lára náà gan-an tí mo ti níláti dojúkọ; ńṣe ni ó dàbí ẹni pé èmi ni ẹ kọ ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ yìí sí ní tààràtà. Ní ìgbà tí mo kọ́kọ́ kà á, omi jáde ní ojú mi. Ohun ìyanu gbáà ni ó jẹ́ láti mọ̀ pé ẹlòmíràn kan mọ bí ìmọ̀lára mi ti rí! Mo dúpẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ pé mo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Ní ibòmíràn wo ni a ti lè rí àwọn ìlérí nípa ìyè àìnípẹ̀kun nínú Paradise ní ọjọ́ iwájú tí kò jìnnà mọ́ àti, nísinsìnyí, ìtùnú fún ọkàn wa! Ẹ ṣeun. Ẹ ṣeun, ṣeun.”
2 Ìwọ ha ti nímọ̀lára bẹ́ẹ̀yẹn rí bí? Ó ha ti fìgbà kan dàbí ẹni pé ohun kan nínú Ilé-Ìṣọ́nà tàbí àkànṣe ìwé-ìròyìn kejì rẹ̀, Jí!, ní a dìídì kọ nítorí rẹ bí? Kí ni ohun náà tí ó máa ń fa àwọn ènìyàn lọ́kàn mọ́ra nínú àwọn ìwé-ìròyìn wa? Báwo ni a ṣe lè ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti jàǹfààní láti inú ìhìn-iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà tí wọ́n ní nínú?—1 Timoteu 4:16.
Àwọn Ìwé-Ìròyìn tí Ń Ṣalágbàwí Òtítọ́
3. Fún ìdí dídára wo ni àwọn ìwé-ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! fi ń wọ ọ̀pọ̀ àwọn òǹkàwé lọ́kàn ṣinṣin?
3 Jehofa ni “Ọlọrun òtítọ́.” (Orin Dafidi 31:5) Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bibeli, jẹ́ ìwé òtítọ́. (Johannu 17:17) Àwọn ènìyàn aláìlábòsí-ọkàn ń dáhùnpadà sí òtítọ́. (Fiwé Johannu 4:23, 24.) Ìdí kan tí Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! fi ń wọ àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ àwọn òǹkàwé lọ́kàn ṣinṣin ni pé wọ́n jẹ́ àwọn àkànṣe ìwé-ìròyìn ìwàtítọ́ ati òtítọ́. Nítòótọ́, ọ̀rọ̀ àríyànjiyàn lórí ìdúróṣinṣin ti àwọn òtítọ́ Bibeli ni ó mú kí a bẹ̀rẹ̀ síí tẹ̀ Ilé-Ìṣọ́nà jáde.
4, 5. (a) Kí ni àwọn àyíká-ipò tí ó mú kí C. T. Russell máa tẹ Ile-Iṣọ Na? (b) Báwo ni “ẹrú olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú” ṣe ń lo àkànṣe ìwé-ìròyìn Ilé-Ìṣọ́nà?
4 Ní 1876, Charles T. Russell darapọ̀ mọ́ Nelson H. Barbour, ti Rochester, New York. Russell ń pèsè owó-àkànlò láti mú kí títẹ ìwé-ìròyìn-àtìgbàdégbà ìsìn ti Barbour náà Herald of the Morning máa báa lọ, pẹ̀lú Barbour gẹ́gẹ́ bí olóòtú àgbà tí Russell sì jẹ́ olùrànlọ́wọ́ olóòtú. Bí ó ti wù kí ó rí, ní nǹkan bíi ọdún kan àti ààbọ̀ lẹ́yìn náà, nínú ìtẹ̀jáde Herald ti August 1878, Barbour kọ ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ kan tí ó sẹ́ ìníyelórí ìràpadà ikú Kristi. Russell, ẹni tí ó fi ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 30 ọdún kéré sí Barbour lọ́jọ́ orí, dáhùnpadà pẹ̀lú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ kan tí ó gbé ìràpadà lárugẹ nínú ìtẹ̀jáde tí ó tẹ̀lé e gan-an, èyí tí ó tọ́kasí gẹ́gẹ́ bí “ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀kọ́ ṣíṣe pàtàkì jùlọ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun.” (Matteu 20:28) Lẹ́yìn ìsapá àṣetúnṣe láti bá Barbour ronú papọ̀ lọ́nà tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu, Russell pinnu nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín láti dáwọ́ gbogbo àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Herald dúró. Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìtẹ̀jáde àkànṣe ìwé-ìròyìn yẹn ti June 1879, orúkọ Russell kò tún farahàn gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ olóòtú mọ́. Ní oṣù kan lẹ́yìn náà, Russell ọmọ ọdún 27 bẹ̀rẹ̀ síí tẹ Zion’s Watch Tower and Herald of Christ’s Presence (tí a mọ̀ sí Ilé-Ìṣọ́nà tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa nísinsìnyí), èyí tí ó ti ń gbé àwọn òtítọ́ Ìwé Mímọ́, bíi ìràpadà lárugẹ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá.
5 Fún ọdún 114 tí ó ti kọjá, Ilé-Ìṣọ́nà, bíi ọ̀jáfáfá agbẹjọ́rò kan, ti gbé araarẹ̀ kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùgbèjà òtítọ́ àti ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ Bibeli. Lẹ́nu èyí, ó ti jèrè ìgbọ́kànlé àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ àwọn òǹkàwé onímọrírì. Ó ṣì ń fi tagbára-tagbára ṣètìlẹ́yìn fún ìràpadà. (Fún àpẹẹrẹ, wo ìtẹ̀jáde February 15, 1991.) Ó ṣì ń báa lọ síbẹ̀ láti jẹ́ irin-iṣẹ́ pàtàkì ti “ẹrú olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú” àti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso rẹ̀ fún kíkéde Ìjọba Jehofa tí a ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ àti pípín oúnjẹ tẹ̀mí fúnni “ní àkókò yíyẹ.”—Matteu 24:14, 45, NW.
6, 7. Kí ní ète-ìlépa tí a sọ pé ó wà fún The Golden Age, kí ni ó sì fihàn pé àwọn onírònú ènìyàn dáhùnpadà sí ìhìn-iṣẹ́ rẹ̀?
6 Ìwé-ìròyìn Jí! ńkọ́? Láti ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀, Jí! pẹ̀lú ti ṣalágbàwí òtítọ́. Ìwé-ìròyìn yìí tí a ń pè ní The Golden Age ní ìpilẹ̀sẹ̀, ni a wéwèé fún ìpínkiri fún gbogbo ènìyàn. Níti ète-ìlépa rẹ̀, ìtẹ̀jáde àkọ́kọ́, tí ó ní déètì náà October 1, 1919, ṣàlàyé pé: “Ète rẹ̀ ni láti ṣàlàyé ìtumọ̀ tòótọ́ ti àrà-mérìíyìírí gígadabú ti ìsinsìnyí nínú ìmọ́lẹ̀ ọgbọ́n Àtọ̀runwá àti láti fihàn fún ọkàn àwọn onírònú nípa ẹ̀rí tí kò ṣeéjiyàn sí tí ó sì dájú pé àkókò ìbùkún títóbi jù fún aráyé ti kù sí dẹ̀dẹ̀ nísinsìnyí.” Àwọn onírònú ènìyàn dáhùnpadà sí ìhìn-iṣẹ́ The Golden Age. Fún àwọn ọdún mélòókan, ìlọkáàkiri rẹ̀ tilẹ̀ pọ̀ ju ti Ilé-Ìṣọ́nà lọ.b
7 Bí ó ti wù kí ó rí, ìfanimọ́ra Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí!, lọ rékọjá òtítọ́ náà pé wọ́n ń kéde òtítọ́ ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ tí wọ́n sì ń ṣàlàyé ìjẹ́pàtàkì alásọtẹ́lẹ̀ ti àwọn ipò ayé. Ní pàtàkì jùlọ ní ẹ̀wádún kan tàbí méjì sẹ́yìn, àwọn ìwé-ìròyìn wa ti fa ọkàn-àyà àwọn ènìyàn mọ́ra fún ìdí mìíràn pẹ̀lú.
Àwọn Ọ̀rọ̀-Ẹ̀kọ́ Abọ́sákòókò tí Ń Nípalórí Ìgbésí-Ayé Àwọn Ènìyàn
8. Ìyípadà wo ni Juda ṣe nínú ohun tí ó fẹ́ láti kọ, ní rírọ àwọn òǹkàwé rẹ̀ láti dènà àwọn agbára-ìdarí wo láàárín ìjọ?
8 Ní nǹkan bíi 30 ọdún lẹ́yìn ikú àti àjíǹde Jesu Kristi, Juda òǹkọ̀wé Bibeli dojúkọ ipò-ọ̀ràn kan tí ń peniníjà. Àwọn ènìyàn oníwà-pálapàla, oníwà-bí-ẹranko ti yọ́ wọ àárín àwọn Kristian. Juda ti pètepèrò láti kọ̀wé sí àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nípa kókó-ẹ̀kọ́ kan tí ó jẹ́ ti ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́—ìgbàlà tí gbogbo àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró jọ dìmú. Kàkà bẹ́ẹ̀, bí ẹ̀mí mímọ́ ti darí rẹ̀, ó ríi pé ó pọndandan láti rọ àwọn òǹkàwé rẹ̀ láti dènà àwọn agbára-ìdarí tí ń sọnidìbàjẹ́ nínú ìjọ. (Juda 3, 4, 19-23) Juda mú ara rẹ̀ bá ipò-ọ̀ràn náà mu ó sì pèsè ìmọ̀ràn bíbọ́sákòókò tí ó kúnjú ìwọ̀n àìní àwọn Kristian arákùnrin rẹ̀.
9. Kí ni ó wémọ́ pípèsè àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ bíbọ́sákòókò fún àwọn àkànṣe ìwé-ìròyìn wa?
9 Bákan náà, pípèsè àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ bíbọ́sákòókò fún àwọn àkànṣe ìwé-ìròyìn wa jẹ́ ẹrù-iṣẹ́ kan tí ń peniníjà. Ìgbà a máa yípadà, bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn ènìyàn—àìní wọn àti àwọn ohun tí wọ́n lọ́kàn-ìfẹ́ sí kìí ṣe ọ̀kan-náà pẹ̀lú ohun tí wọ́n jẹ́ ní ọdún mẹ́wàá tàbí ogún ọdún sẹ́yìn. Alábòójútó arìnrìn-àjò kan ṣàkíyèsí láìpẹ́ yìí pé: “Nígbà tí mo di Ẹlẹ́rìí nígbà náà lọ́hùn-ún ní àwọn ọdún 1950, ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ ni olórí ohun tí a máa ń fi kọ́ àwọn ènìyàn nínú Bibeli—ní kíkọ́ wọn ní òtítọ́ nípa Mẹ́talọ́kan, iná ọ̀run-àpáàdì, ọkàn, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ó jọ pé, àwọn ìṣòro àti ìnira pọ̀ gan-an nínú ìgbésí-ayé àwọn ènìyàn tí ó fi jẹ́ pé a níláti kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè gbé ìgbésí-ayé.” Èéṣe tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀?
10. Èéṣe tí kò fi gbọ́dọ̀ yà wá lẹ́nu pé ìjẹràbàjẹ́ tí kò dáwọ́dúró ti bá àwọn àlámọ̀rí ènìyàn láti 1914 wá?
10 Nípa àwọn “ìkẹyìn ọjọ́,” Bibeli sọtẹ́lẹ̀ pé: “Àwọn ènìyàn búburú, àti àwọn ẹlẹ́tàn yóò máa gbilẹ̀ síwájú síi, wọn óò máa tannijẹ, a ó sì máa tàn wọ́n jẹ.” (2 Timoteu 3:1, 13) Nítorí náà, kò yẹ kí ó yà wá lẹ́nu pé ìjẹràbàjẹ́ tí kò dáwọ́dúró ti bá àwọn àlámọ̀rí ènìyàn láti ìgbà ti àkókò òpin ti bẹ̀rẹ̀ ní 1914. Satani, ẹni tí àkókò rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù kúrú ju ti ìgbàkígba rí lọ, ń tu ìbínú rẹ̀ jáde sórí ẹgbẹ́-àwùjọ ènìyàn ju ti ìgbàkígbà rí lọ. (Ìfihàn 12:9, 12) Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí, àwọn ìdíyelé ìwàrere àti ti ìdílé ti yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí wọ́n jẹ́ ní kìkì 30 tàbí 40 ọdún sẹ́yìn. Àwọn ènìyàn ní gbogbogbòò kò ní ìtẹ̀sí síhà ìsìn mọ́ bí ó ti rí ní àwọn ẹ̀wádún tí ó kọjá. Ìwà-ọ̀daràn tànkálẹ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ènìyàn fí ń lo àwọn ìṣọ́ra tí a kò gbọ́ nípa wọn rí ní kìkì 20 tàbí 30 ọdún sẹ́yìn.—Matteu 24:12.
11. (a) Irú àwọn kókó-ẹ̀kọ́ wo ni ó wà lọ́kàn àwọn ènìyàn, báwo sì ni ẹgbẹ́-agbo ẹrú olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ṣe dáhùnpadà sí àwọn àìní náà? (b) Fúnni ní àpẹẹrẹ ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ Ilé-Ìṣọ́nà tàbí Jí! kan tí ó ti nípalórí ìgbésí-ayé rẹ.
11 Abájọ, nígbà náà, tí ó fi jẹ́ pé àwọn ọ̀ràn níti èrò-ìmọ̀lára, ti ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà, àti ti ìdílé wà lọ́kàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn. Ẹgbẹ́-agbo ẹrú olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú náà ti fi ìgboyà dáhùnpadà nínú Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! nípa títẹ àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ bíbọ́sákòókò tí ó ti bójútó àwọn àìní gidi náà tí àwọn ènìyàn ní tí ó sì ti nípalórí ìgbésí-ayé wọn jáde. Gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀wò.
12. (a) Èéṣe tí a fi pèsè àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ lórí àwọn ìdílé òbí anìkàntọ́mọ nínú Ilé-Ìṣọ́nà ní 1980? (b) Báwo ni arábìnrin kan ṣe fi ìmọrírì rẹ̀ hàn fún àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ lórí àwọn ìdílé òbí anìkàntọ́mọ?
12 Àwọn ọ̀ràn ìdílé. Nígbà tí ìròyìn kárí-ayé fi ìbísí tí ń yárakánkán hàn nínú iye àwọn ìdílé òbí ànìkàntọ́mọ, àwọn àkọ̀tun ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ lórí ẹṣin-ọ̀rọ̀ náà “Awọn Idile Olobi-Kan—Ndojukọ Awọn Iṣoro Naa” ni a wéwèé fún ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà March 15, 1981. Àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà ní ète alápá-méjì: (1) láti ran àwọn òbí anìkàntọ́mọ lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro aláìlẹ́gbẹ́ tí wọ́n ń dojúkọ àti (2) láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ní òye tí ó sàn síi kí wọ́n baà lè fi ‘ìbákẹ́dùn’ hàn kí wọ́n sì fi tinútinú “bójútó” àwọn ìdílé òbí anìkàntọ́mọ. (1 Peteru 3:8; Jakọbu 1:27) Ọ̀pọ̀ àwọn òǹkàwé kọ̀wé láti fi ìmọrírì hàn fún àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà. “Nítòótọ́ ní o mú mi da omi lójú nígbà tí mo rí èèpo ẹ̀yìn ìwé náà,” ni òbí anìkàntọ́mọ kan kọ̀wé, “nígbà tí mo sì ṣí ìwé-ìròyìn náà tí mo ka ìsọfúnni náà, ọkàn-àyà mi kún àkúnwọ́sílẹ̀ fún ọpẹ́ sí Jehofa fún pípèsè irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ ní àkókò tí a nílò rẹ̀.”
13. Ìjíròrò gbígbòòro wo lórí ìsoríkọ́ ni a tẹ̀jáde nínú Jí! ní 1981, kí sì ni òǹkàwé kan ní láti sọ nípa rẹ̀?
13 Àwọn ọ̀ràn nípa èrò-ìmọ̀lára. Kókó-ẹ̀kọ́ ìsoríkọ́ ni a ti ń jíròrò nínú Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! láti àwọn ọdún 1960. (1 Tessalonika 5:14) Ṣùgbọ́n a fi ojú titun tí ó sì gbéṣẹ́ wo kókó-ẹ̀kọ́ náà nínú ọ̀wọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìwé-ìròyìn náà “Ìwọ Lè Kojú Ìsoríkọ́!” nínú Jí! September 8, 1981 (Gẹ̀ẹ́sì). Kò pẹ́ tí àwọn lẹ́tà ìmọrírì fi rọ́ wọlé sọ́dọ̀ Watch Tower Society láti apá ibi gbogbo lágbàáyé. “Báwo ni mo ṣe lè kọ àwọn ìmọ̀lára tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà mi sórí ìwé?” ni arábìnrin kan kọ̀wé. “Mo jẹ́ ọmọ ọdún 24, ní ọdún mẹ́wàá tí ó sì ti kọjá, mo ti ní ìsoríkọ́ ní ìgbà púpọ̀. Ṣùgbọ́n nísinsìnyí mó nímọ̀lára pé mo súnmọ́ Jehofa pẹ́kípẹ́kí síi mo sì dúpẹ́ pé ó dáhùnpadà sí àìní àwọn tí ó soríkọ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó fi ìfẹ́ hàn wọ̀nyí, mo sì fẹ́ láti sọ fún yín bẹ́ẹ̀.”
14, 15. (a) Báwo ni a ṣe bójútó kókó-ẹ̀kọ́ lílo àwọn ọmọdé nílòkulò nínú àwọn àkànṣe ìwé-ìròyìn wa? (b) Àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ ìwé-ìròyìn wo ni wọ́n wú agẹṣindíje kan ní Australia lórí?
14 Àwọn ọ̀ràn ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà. Bibeli sọtẹ́lẹ̀ pé ní “ìkẹyìn ọjọ́” àwọn ènìyàn “yóò jẹ́ olùfẹ́ ti ara wọn, . . . aláìnífẹ̀ẹ́, . . . aláìlè-kó-ra-wọn-níjàánu, òǹrorò, aláìnífẹ̀ẹ́-ohun-rere.” (2 Timoteu 3:1-3) Nítorí náà, kò yẹ kí ó yà wá lẹ́nu pé lílo àwọn ọmọdé nílòkulò ní a ń hù níwà lọ́nà gbígbòòrò lónìí. Kókó-ẹ̀kọ́ yìí ni a bójútó láìfọ̀rọ̀-sábẹ́-ahọ́n nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà “Iranlọwọ fun Awọn Ẹran-Ijẹ Ibalopọ Takọtabo Laarin Ibatan” nínú Ilé-Ìṣọ́nà ti April 1, 1984. Ní ọdún mẹ́jọ lẹ́yìn náà, ọ̀wọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìwé-ìròyìn náà “Wíwo Ọgbẹ́ Ìlòkulò Ọmọde Sàn” nínú Jí! ti March 8, 1992, ní a fẹ̀sọ̀ kọ láti pèsè òye àti ìrètí fún àwọn òjìyà-ìpalára kí ó sì tún fún àwọn mìíràn ní ìlàlóye kí wọ́n baà lè nawọ́ ìrànlọ́wọ́ wíwúlò síni. Ọ̀wọ́ àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ wọ̀nyí fa ìdáhùnpadà tí ó pọ̀ jùlọ jáde láti ọ̀dọ̀ àwọn òǹkàwé nínú ọ̀rọ̀-ìtàn àwọn àkànṣe ìwé-ìròyìn wa. Òǹkàwé kan kọ̀wé pé: “Ohun tí ó nípa títóbi jùlọ lórí ìjèrè okun padà mi ni àwọn èrò tí ń tuninínú àti àwọn ìtọ́kasí Ìwé Mímọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ wọ̀nyí. Láti mọ̀ pé Jehofa kò ronú lọ́nà yẹpẹrẹ nípa mi jẹ́ ìtura ńláǹlà kan. Láti mọ̀ pé n kò dá wà ní èmi nìkanṣoṣo tún jẹ́ ìtùnú fún mi bákan náà.”
15 Agẹṣindíje kan ní Melbourne, Australia, ṣe ìkésíni ọ̀nà jíjìn lórí fóònù sí ọ́fíìsì Watch Tower Society ní Sydney, ní sísọ̀rọ̀ nípa bí àyíká ibi tí a ti ń fi ẹṣin sáré ti kó o nírìíra tó. Ó sọ pé òun ṣẹ̀ṣẹ̀ ka Jí! March 8, 1993 tí ó sọ̀rọ̀ lórí “Ifipa-Bóbinrin-Lopọ—Iṣẹlẹ Bibanilẹru Awọn Obinrin” ni àti pé agbára káká ni òun fi lè gbàgbọ́ pé irú ìwé-ìròyìn ṣíṣeyebíye bẹ́ẹ̀ wà. Ó béèrè àwọn ìbéèrè fún nǹkan bíi 30 ìṣẹ́jú inú rẹ̀ sì dùn láti gbọ́ àwọn ìdáhùn tí a fifún un.
16. Ni àwọn ọ̀nà wo ni ìwọ lè gba fi ìmọrírì rẹ hàn fún àwọn àkànṣe ìwé-ìròyìn wa?
16 Ìwọ ń kọ́? Ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ pàtó kan tí a tẹ̀jáde nínú Ilé-Ìṣọ́nà tàbí Jí! ha ti nípalórí ìgbésí-ayé rẹ bí? Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, kò sí iyèméjì pé o ní ẹ̀mí ìmoore jíjinlẹ̀ fún àwọn àkànṣe ìwé-ìròyìn wa. Báwo ni o ṣe lè fi ìmọrírì rẹ hàn? Dájúdájú ó jẹ́ nípa kíka ìtẹ̀jáde kọ̀ọ̀kan fúnraàrẹ. O tún lè nípìn-ín nínú fífún àwọn àkànṣe ìwé-ìròyìn ṣíṣeyebíye wọ̀nyí ní ìpínkiri gbígbòòrò jùlọ bí ó bá ti lè ṣeéṣe tó. Báwo ni ó ṣe lè ṣe èyí?
Ṣàjọpín Wọn Pẹ̀lú Àwọn Ẹlòmíràn!
17. Kí ni àwọn ìjọ lè ṣe láti mú ìpínkiri ìwé-ìròyìn pọ̀ síi?
17 Lákọ̀ọ́kọ́, ohun kan wà tí ìjọ kọ̀ọ̀kan lè ṣe. Ìtẹ̀jáde Informant (Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa nísinsìnyí) ti October 1952 sọ pé: “Ọ̀nà gbígbéṣẹ́ jùlọ tí a lè gbà pín àwọn ìwé-ìròyìn náà jẹ́ láti ilé dé ilé àti láti ilé-ìtajà dé ilé-ìtajà. Fún ìdí yìí Society dámọ̀ràn pé kí àwọn ọ̀nà ìgbà pín ìwé-ìròyìn wọ̀nyí jẹ́ apá tí a ń ṣe déédéé nínú ìgbòkègbodò Ọjọ́ Ìwé-Ìròyìn.” Ìmọ̀ràn yẹn ṣì lẹ́sẹ̀nílẹ̀ lónìí. Àwọn ìjọ lè ṣètò Ọjọ́ Ìwé-Ìròyìn tí a ń ṣe déédéé, ọjọ́ kan tí a yàsọ́tọ̀ ní pàtàkì fún jíjẹ́rìí pẹ̀lú ìwé-ìròyìn. Fún ọ̀pọ̀ àwọn ìjọ, kò sí iyèméjì pé àwọn ọjọ́ Saturday tí a yàsọ́tọ̀ ní pàtó yóò jẹ́ àkókò tí ó dára. Bẹ́ẹ̀ni, ẹ jẹ́ kí ìjọ kọ̀ọ̀kan ya àwọn ọjọ́ tàbí ìrọ̀lẹ́ àkànṣe kan sọ́tọ̀ fún jíjẹ́rìí pẹ̀lú ìwé ìròyìn—láti ilé dé ilé, láti ilé-ìtajà dé ilé-ìtajà, nínú iṣẹ́ òpópónà, àti ní àwọn ipa-ọ̀nà ìwé-ìròyìn. Ní àfikún, kí ni ìwọ, akéde Ìjọba, lè ṣe láti mú ìpínkiri ìwé-ìròyìn pọ̀ síi?
18, 19. (a) Báwo ni níní ọkàn-ìfẹ́ sí Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fi àwọn ìwé-ìròyìn sóde? (b) Kí ni àǹfààní ìgbékalẹ̀-ọ̀rọ̀ kúkúrú, tí ó lọ tààràtà sórí kókó nígbà tí o bá ń fi àwọn ìwé-ìròyìn lọni? (d) Ki ni ó fi ìníyelórí mímú àwọn ìwé-ìròyìn náà dé inú ilé àwọn ènìyàn hàn?
18 Jíjẹ́ ẹni tí ó lọ́kàn-ìfẹ́ sí “Ilé-Ìṣọ́nà” àti “Jí!” ni ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́. Ka àwọn ìwé-ìròyìn náà ṣáájú àkókò. Bí o ti ń ka ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan, bi araàrẹ pé, ‘Ta ni yóò lọ́kàn-ìfẹ́ sí ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ yìí?’ Ronú nípa àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀ tí o lè sọ láti ru ọkàn-ìfẹ́ sókè nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà. Yàtọ̀ sí ṣíṣètìlẹ́yìn fún Ọjọ́ Ìwé-Ìròyìn tí a ń ṣe déédéé, èéṣe tí o kò fi máa mú àwọn ẹ̀dà lọ́wọ́ kí o baà lè lo gbogbo àkókò tí ó bá ṣí sílẹ̀ láti ṣàjọpín wọn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn lọ́nà rere—nígbà tí o bá ń rìnrìn-àjò tàbí tí o bá ń nájà àti nígbà tí o bá ń bá àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ, aládùúgbò, àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tàbí àwọn olùkọ́ sọ̀rọ̀?
19 Mú kí ó rọrùn ni ìdámọ̀ràn kejì. Ilé-Ìṣọ́nà December 1957, ojú-ìwé 370 sọ pé: “Ó dára jùlọ láti sọ̀rọ̀ níwọ̀n nígbà tí a bá ń pín ìwé-ìròyìn wọ̀nyí kiri. Ohun tí a ń lépa ni láti pín ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn. Kò wá ọ̀rọ̀ púpọ̀, àwọn ni yóò ‘sọ̀rọ̀’ fúnraawọn.” Àwọn akéde kan ti ríi pé ó gbéṣẹ́ láti fa èrò kan yọ láti inú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ kan, kí wọ́n sọ ọ́ ní ọ̀rọ̀ ṣókí, kí wọ́n sì fi ìwé-ìròyìn náà lọni. Ní gbàrà tí wọ́n bá ti wọ inú ilé, àwọn ìwé-ìròyìn náà lè “sọ̀rọ̀” fún àwọn ẹlòmíràn ní àfikún sí ẹni náà tí ó gbà wọ́n lọ́wọ́ rẹ. Ní Ireland ọ̀dọ́ àkẹ́kọ̀ọ́ kan ní yunifásítì ka ìtẹ̀jáde Ilé-Ìṣọ́nà ti September 1, 1991, tí baba rẹ̀ gbà lọ́wọ́ Ẹlẹ́rìí kan. Àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ náà lórí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ àti àwọn kókó-ẹ̀kọ́ mìíràn ta ọkàn-ìfẹ́ rẹ̀ jí. Ní kété lẹ́yìn tí ó ka ìwé-ìròyìn náà tán, ó késí àwọn Ẹlẹ́rìí lórí fóònù, ní lílo nọ́ḿbà tí a tòlẹ́sẹẹsẹ sínú ìwé tẹlifóònù. Kò pẹ́ tí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli kan bẹ̀rẹ̀, a sì baptisi ọ̀dọ́mọbìnrin náà ní Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá” ní July 1993. Ní gbogbo ọ̀nà, ẹ jẹ́ kí a mú àwọn ìwé-ìròyìn náà dé inú àwọn ilé, níbi tí wọ́n ti lè bá àwọn ènìyàn “sọ̀rọ̀”! Alábòójútó arìnrìn-àjò kan fúnni ní ìdámọ̀ràn rírọrùn mìíràn: “Mú ìwé-ìròyìn náà jáde láti inú àpò rẹ.” Nítòótọ́, bí ohun tí o sọ kò bá jèrè ìfẹ́-ọkàn onílé náà, nígbà náà bóyá àwọn àwòrán wọn fífanimọ́ra tí ó wà lára èèpo ẹ̀yìn ìwé náà yóò fi ìwé-ìròyìn náà sóde fún ọ.
20, 21. (a) Báwo ní ó ṣe lè jẹ́ olùmọwọ́ọ́yípadà nígbà tí o bá ń nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìwé-ìròyìn? (b) Kí ni ìwọ lè ṣe láti lè fi ìwé-ìròyìn púpọ̀ síi sóde lóṣooṣù?
20 Ìdámọ̀ràn kẹta ni láti jẹ́ olùmọwọ́ọ́yípadà. (Fiwé 1 Korinti 9:19-23.) Múra ìgbékalẹ̀ ṣókí díẹ̀ sílẹ̀. Ní ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ kan lọ́kàn tí yóò fa ọkàn àwọn ọkùnrin mọ́ra, àti òmíràn àwọn obìnrin. Fún àwọn èwe, o lè gbé ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . .” kan jáde lákànṣe. Jẹ́ olùmọwọ́ọ́yípadà, pẹ̀lú, níti ìgbà tí o ń nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìwé-ìròyìn. Ní àfikún sí Ọjọ́ Ìwé-Ìròyìn, ó lè ríi pé ìjẹ́rìí ìrọ̀lẹ́ fún ọ ní àǹfààní tí ó tayọlọ́lá láti fi àwọn ìwé-ìròyìn lọni láti ilé dé ilé.
21 Ìdámọ̀ràn kẹrin ni láti gbé góńgó ti ara-ẹni kalẹ̀. Àkìbọnú náà “Awọn Iwe-irohin Ntọka si Ọna Iye,” èyí tí ó farahàn nínú Iṣẹ́-Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti July 1984, sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ìdábàá kan, àwọn akéde lè ní góńgó kan, ki a sọ pé ìwé-ìròyìn 10 lóṣù, gẹ́gẹ́ bi ipò nǹkan bá ṣe rí fún wọn; àwọn aṣáájú-ọ̀nà lè lépa 90. Àmọ́ ṣáá ó, àwọn akéde kan ni ó lè ṣeéṣe fún láti fi àwọn ìwé-ìròyìn púpọ̀ síi sóde lóṣooṣù tí àwọn nítorí náà yóò sì gbé góńgó ara-ẹni tí ó ga jù bẹ́ẹ̀ lọ kalẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, nítorí àìlera ara, irú ìpínlẹ̀ tí a ní tàbí àwọn ìdí rere mìíràn, góńgó àwọn mìíràn lè jẹ́ èyí tí ó rẹlẹ̀ sí èyíinì. Síbẹ̀ iṣẹ́-ìsìn wọn sí Jehofa níyelórí bákan náà gẹ́gẹ́. (Matt. 13:23; Luku 21:3, 4) Ohun tí ó ṣe pàtàkì ni láti ní góńgó ara-ẹni kan.”
22. Ni ọ̀nà wo ni a lè gbà fihàn pé a kún fún ọpẹ́ fún Jehofa fún àwọn àkànṣe ìwé-ìròyìn òtítọ́ bíbọ́sákòkókò wa?
22 Ẹ wo bí a ti kún fún ọpẹ́ tó pé Jehofa, “Ọlọrun òtítọ́,” ti lo ẹgbẹ́-agbo ẹrú olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú àti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso rẹ̀ láti pèsè àwọn àkànṣe ìwé-ìròyìn bíbọ́sákòókò wọ̀nyí fún wa! (Orin Dafidi 31:5) Bí ó bá ṣì ń jẹ́ ìfẹ́-inú Jehofa, àwọn ìwé-ìròyìn wọ̀nyí yóò máa báa lọ láti kápá àwọn àìní gidi náà tí àwọn ènìyàn ní. Wọ́n yóò máa báa lọ láti máa gbé àwọn ìlànà ìwàhíhù gíga ti Jehofa lárugẹ. Wọn kì yóò ṣíwọ́ láti máa gbé ẹ̀kọ́-ìgbàgbọ́ tòótọ́ ga síwájú. Wọn yóò sì tẹpẹlẹ mọ́ ọn láti máa darí àfiyèsí sí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ tí ó sàmìsí àwọn ọjọ́ wa gẹ́gẹ́ bí àkókò náà nígbà tí Ìjọba Ọlọrun ń ṣàkóso tí a sì ń ṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun lórí ilẹ̀-ayé lọ́nà tí a kò tíì gbà ṣeé rí nípasẹ̀ iye àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ ti Jehofa tí ń bísíi. (Matteu 6:10; Ìfihàn 11:15) Ẹ wo ìṣúra aláìṣeédíyelé tí Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! jẹ́ fún wa! Ẹ jẹ́ kí a lo gbogbo àkókò tí ó bá ṣí sílẹ̀ lọ́nà rere láti ṣàjọpín àwọn àkànṣe ìwé-ìròyìn pàtàkì wọ̀nyí tí ń nípalórí ìgbésí-ayé àwọn ènìyàn tí ó sì ń gbèjà àwọn òtítọ́ Ìjọba pẹ̀lú àwọn onínútútù.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a July 15, 1992, ojú-ìwé 19 sí 22.
b Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún Ilé-Ìṣọ́nà ni a ti wò gẹ́gẹ́ bí ìwé-ìròyìn kan tí ó wà fún àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró ní pàtàkì. Bí ó ti wù kí ó rí, bẹ̀rẹ̀ láti 1935, ìtẹnumọ́ tí ń ga síi ni a gbékarí fífún “ogunlọ́gọ̀ ńlá,” tí ìrètí rẹ̀ jẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀-ayé ní ìṣírí, láti gba Ilé-Ìṣọ́nà kí wọ́n sì kà á. (Ìfihàn 7:9) Ní ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, ní 1940, Ilé-Ìṣọ́nà ni a ń fi lọ àwọn ènìyàn déédéé ní àwọn òpópónà. Lẹ́yìn ìgbà náà, ìlọkáàkiri bísíi lọ́nà tí ó yárakánkán.
Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?
◻ Kí ni ó fihàn pé Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! jẹ́ àwọn àkànṣe ìwé-ìròyìn òtítọ́?
◻ Báwo ní Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! ti ṣe nípalórí ìgbésí-ayé àwọn ènìyàn?
◻ Kí ni àwọn ìjọ lè ṣe láti mú ìpínkiri ìwé-ìròyìn pọ̀ síi?
◻ Àwọn ìdámọ̀ràn wo ni ó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fi àwọn ìwé-ìròyìn púpọ̀ síi sóde?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 22]
Àwọn Ọ̀rọ̀-Ẹ̀kọ́ Díẹ̀ tí Wọ́n Nípalórí Ìgbésí-Ayé Àwọn Ènìyàn
Láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òǹkàwé ti kọ̀wé láti fi ìmọrírì hàn fún àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ pàtó kan tí a tẹ̀jáde nínú Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí! Èyí tí a tò sísàlẹ̀ yìí wulẹ̀ jẹ́ ìwọ̀nba díẹ̀ nínú ọ̀pọ̀ àwọn kókó-ẹ̀kọ́ tí ó nípalórí àwọn òǹkàwé wa. Ìwọ̀nyí tàbí àwọn ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ mìíràn ha ti yí ìgbésí-ayé rẹ padà bí?
Ilé-Ìṣọ́nà
“Tẹ́wọ́gba Iranlọwọ Ọlọrun lati Ṣẹ́pá Awọn Àríwísí Ìkọ̀kọ̀” (October 15, 1985)
“Sisọ Ifọkansin Oniwa-bi-Ọlọrun Dàṣà Si Awọn Obi Agbalagba” (June 1, 1987)
“Ẹkọ-Iwe Pẹlu Ète Kan” (November 1, 1992)
Jí!
“Ìwọ Lè Kojú Ìsoríkọ́!” (September 8, 1981 [Gẹ̀ẹ́sì])
“Nigba Tí Ẹnikan Tí Iwọ Fẹran Bá Kú . . .” (October 22, 1986)
“Dáàbòbo Awọn Ọmọ Rẹ!” (October 8, 1993)
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ní Canada—fífi àwọn ìwé-ìròyìn wàásù láti ilé dé ilé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Ní Myanmar—fífi àwọn ìwé-ìròyìn tí ó tọ́kasí ọ̀nà ìyè lọni