ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/98 ojú ìwé 1
  • Ìwọ Ha Máa Ń Ka Àwọn Ìwé Ìròyìn Wa Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìwọ Ha Máa Ń Ka Àwọn Ìwé Ìròyìn Wa Bí?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Fi Ìwé Ìròyìn Lọni Tó O Bá Ń Wàásù
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Ilé-Ìṣọ́nà àti Jí!—Àwọn Àkànṣe Ìwé-Ìròyìn Òtítọ́ Bíbọ́sákòókò
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Àwọn Ìwé Ìròyìn Ń Kéde Ìjọba Náà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Ṣàṣàyàn Àwọn Àpilẹ̀kọ Láti Fi Fa Àwọn Ènìyàn Mọ́ra Lórí Ohun Tí Wọ́n Ní Ọkàn-Ìfẹ́ sí Ní Pàtó
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
km 10/98 ojú ìwé 1

Ìwọ Ha Máa Ń Ka Àwọn Ìwé Ìròyìn Wa Bí?

1 Tọkọtaya míṣọ́nnárì kan ní Áfíríkà sọ nípa àwọn ìwé ìròyìn wa pé: “Ilé Ìṣọ́ ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa wà lójúfò nípa tẹ̀mí ní ìpínlẹ̀ wa. A ń rí ìṣírí àti okun gbà láti inú ìtẹ̀jáde kọ̀ọ̀kan.” O ha ní ìmọrírì jíjinlẹ̀ kan náà fún àwọn ìwé ìròyìn wa bí? Ṣé o sì máa ń hára gàgà lọ́nà kan náà láti kà wọ́n?

2 Ó máa ń gba àkókò púpọ̀ láti ṣètò àwọn àpilẹ̀kọ ìwé ìròyìn tí a lè kà láàárín ìṣẹ́jú díẹ̀. Ní mímọ èyí, ìwọ yóò ha wulẹ̀ ka àwọn àpilẹ̀kọ náà gààràgà, kí o wo àwọn àwòrán, tàbí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan kí o ka àpilẹ̀kọ tí ó bá gba àfiyèsí rẹ? A óò jẹ́ ọlọgbọ́n bí a bá ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó yẹ kí a fara balẹ̀ ka gbogbo àpilẹ̀kọ tí ó wà nínú ìtẹ̀jáde ìwé ìròyìn wa kọ̀ọ̀kan, kí a sì ṣe ìfọ́síwẹ́wẹ́ wọn. Ilé Ìṣọ́ ni olórí ìwé ìròyìn wa fún oúnjẹ tẹ̀mí tí ó bá àkókò mu. Jí! máa ń gbé àwọn àpilẹ̀kọ tí ó fani lọ́kàn mọ́ra tí ó sì kún fún ẹ̀kọ́ nípa onírúurú àwọn kókó jáde. Kì í ṣe pé àwọn ohun tí a ń kọ́ nípa kíka ìwé ìròyìn wọ̀nyí ń fún wa lókun nípa tẹ̀mí nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún ń múra wa sílẹ̀ fún nínípìn-ín tí ó túbọ̀ gbéṣẹ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Bí àwa fúnra wa bá ń ka àwọn ìwé ìròyìn wa dáadáa, ara yóò yá wa láti fi wọ́n lọ àwọn ẹlòmíràn.

3 Bí O Ṣe Lè Mú Ìwé Kíkà Rẹ Sunwọ̀n Sí I: Ṣé ó lè mú bí o ṣe ń ka àwọn ìwé ìròyìn wa déédéé sunwọ̀n sí i? Àbá méjì nìyí tí ó ti wúlò fún ọ̀pọ̀lọpọ̀. (1) Ṣètò ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìwé kíkà déédéé. Nípa yíya kìkì ìṣẹ́jú 10 tàbí 15 sọ́tọ̀ lóòjọ́ fún ìwé kíkà, yóò yà ọ́ lẹ́nu bí ìwé tí ìwọ yóò kà láàárín ọ̀sẹ̀ kan yóò ṣe pọ̀ tó. (2) Wá ọ̀nà bí ìwọ yóò ṣe máa mọ ohun tí o ti kà. Bóyá o lè máa sàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ kọ̀ọ̀kan tí o bá ti kà. Bí o kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe kí o fo àwọn àpilẹ̀kọ kan tàbí odindi ìwé ìròyìn kan pàápàá. Ó ṣe pàtàkì pé kí o ṣètò bí ìwọ yóò ṣe máa kàwé déédéé lọ́nà tí ó gbéṣẹ́ fún ọ kí o sì máa tẹ̀ lé e.—Fi wé Fílípì 3:16.

4 “Ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ti fi ọgbọ́n hùwà padà sí àkókò tí ń yí padà nípa títẹ àwọn àpilẹ̀kọ jáde, èyí tí ń bójú tó àìní gidi tí àwọn ènìyàn ní. (Mát. 24:45) Ní tòótọ́, àwọn ìwé ìròyìn náà ti ní ipa lórí ìgbésí ayé wa. Dé ìwọ̀n àyè gíga, bí a ṣe ń ka àwọn ìwé ìṣàkóso Ọlọ́run dáadáa tó ní ń pinnu bí ìtẹ̀síwájú wa nípa tẹ̀mí ṣe ń yára tó. Ìbùkún tẹ̀mí dídọ́ṣọ̀ wà ní ìpamọ́ fún àwọn tí ń wá àyè láti ka gbogbo ìwé ìròyìn wa.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́