ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/98 ojú ìwé 2
  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún October

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún October
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní October 5
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní October 12
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní October 19
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní October 26
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
km 10/98 ojú ìwé 2

Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún October

ÀKÍYÈSÍ: Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yóò ṣètò Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn fún ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan ní àkókò àpéjọpọ̀. Kí àwọn ìjọ ṣe àtúnṣe tí ó yẹ láti fàyè sílẹ̀ fún lílọ sí Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́,” lẹ́yìn náà, kí wọ́n sì ṣètò fún àtúnyẹ̀wò ọlọ́gbọ̀n ìṣẹ́jú lórí àwọn kókó ìtẹnumọ́ láti inú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ti ọ̀sẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e. Ṣíṣe àtúnyẹ̀wò ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ti àpéjọpọ̀ àgbègbè náà ni kí a yàn ṣáájú fún arákùnrin títóótun mẹ́ta tí yóò lè pọkàn pọ̀ sórí àwọn kókó pàtàkì. Àtúnyẹ̀wò tí a múra sílẹ̀ dáadáa yìí yóò ran ìjọ lọ́wọ́ láti rántí àwọn kókó pàtàkì fún ìfisílò fúnra ẹni àti fún lílò nínú pápá. Àlàyé èyíkéyìí láti ọ̀dọ̀ àwùjọ àti ìrírí tí a óò sọ gbọ́dọ̀ ṣe ṣókí, kí ó sì ṣe tààràtà.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní October 5

Orin 199

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.

15 min: “Jèhófà Ni Olùrànlọ́wọ́ Mi.” Ọ̀rọ̀ àsọyé ọlọ́yàyà tí ń fúnni níṣìírí láti ẹnu alàgbà kan.

20 min: “‘Fífúnrúgbìn Ìjọba’ ní Ipa Ọ̀nà Ìwé Ìròyìn.” Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Jẹ́ kí àwọn kan ṣàlàyé bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn tí wọ́n sì ń bá a nìṣó. Lẹ́yìn náà kí a ṣàṣefihàn ìfilọni ìwé ìròyìn níbi tí a ti ṣètò láti mú àwọn ìtẹ̀jáde tí yóò tẹ̀ lé e padà wá.

Orin 133 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní October 12

Orin 42

5 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ṣàyẹ̀wò àwọn kókó ìbánisọ̀rọ̀ nínú àwọn ìtẹ̀jáde ìwé ìròyìn wa tí ó dé kẹ́yìn. Sọ ìrírí tí ó wà nínú ìwé Yearbook 1997, ojú ìwé 45, àti Jí!, October 22, 1996, ojú ìwé 32. Fún gbogbo akéde níṣìírí láti nípìn-ín nínú ìpínkiri ìwé ìròyìn ní òpin ọ̀sẹ̀ yìí.

10 min: “Àwọn Alábòójútó Tí Ń Mú Ipò Iwájú—Akọ̀wé.” Ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu akọ̀wé ìjọ, kí ó ṣàtúnyẹ̀wò iṣẹ́ tí a yàn fún un. Ó tẹnu mọ́ ọn pé gbogbo akéde lè fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nípa fífi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn sílẹ̀ lọ́gán.

10 min: Wọ́n Ní Ẹ̀mí Aṣáájú Ọ̀nà Ọlọ́yàyà. Ọ̀rọ̀ àsọyé tí ń fúnni níṣìírí tí a gbé karí Yearbook ti ọdún 1998, ojú ìwé 104 sí 107. Ṣàlàyé ìdí tí ọ̀pọ̀ aṣáájú ọ̀nà fi wà ní Japan, ohun tí ó mú kí àwọn ìyàwó ilé tí ó wà níbẹ̀ máa fi àwọn ire tẹ̀mí sí ipò àkọ́kọ́, ohun tí ó ń sún ẹnì kọ̀ọ̀kan láti béèrè fún wíwọṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà, àti àwọn tí ó pọ̀ jù lọ nínú àwọn aṣáájú ọ̀nà náà. Ṣàpèjúwe agbára ìdarí tí àwọn òbí tí ń ṣe aṣáájú ọ̀nà máa ń ní. Tẹnu mọ́ ìdánilójú ìgbàgbọ́ tí ó máa ń béèrè láti ṣe àwọn àtúnṣe pípọndandan nínú ìgbésí ayé ẹni láti ṣe aṣáájú ọ̀nà. Fún gbogbo akéde níṣìírí láti ronú jinlẹ̀ tàdúràtàdúrà lórí ṣíṣeéṣe láti di aṣáájú ọ̀nà láìpẹ́.

20 min: “Ìwọ Ha Máa Ń Ka Àwọn Ìwé Ìròyìn Wa Bí?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn àbá gbígbéṣẹ́ nípa ṣíṣètò àkókò fún dídákàwé tí ó wà nínú Iwe-Amọna Ilé Ẹ̀kọ́, ìkẹ́kọ̀ọ́ 4, ìpínrọ̀ 5 àti 6.

Orin 107 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní October 19

Orin 16

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó.

15 min: Àìní àdúgbò.

20 min: Bí A Ṣe Lè Múra Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ Sílẹ̀. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tí olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ darí, tí a gbé karí Ilé-Ìṣọ́nà, February 1, 1987, ojú ìwé 30 àti 31, ìpínrọ̀ 16 sí 18 àti Iwe-Amọna Ile Ẹkọ, ìkẹ́kọ̀ọ́ 7, ìpínrọ̀ 11, àti ìkẹ́kọ̀ọ́ 18, ìpínrọ̀ 4 sí 6. Béèrè fún àlàyé sí àwọn ìbéèrè tí ó tẹ̀ lé e yìí: (1) Kí ni ìdí tí ó fi ṣe kókó pé kí a jàǹfààní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ láti inú gbogbo àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó wà nínú Ilé Ìṣọ́? (2) Kí ló yẹ kí a ṣe nígbà tí a bá gba ìtẹ̀jáde tuntun? (3) Ọ̀nà dídára wo ni a lè gbà múra Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ sílẹ̀? (4) Àfiyèsí wo ni ó yẹ kí a fún àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí àti ẹṣin ọ̀rọ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ náà? (5) Báwo ni a ṣe lè ṣàtúnyẹ̀wò ohun tí a kẹ́kọ̀ọ́? (6) Àwọn kókó pàtàkì wo ni ó yẹ kí a ronú lé lórí nígbà tí a bá parí ìdákẹ́kọ̀ọ́ nínú ẹ̀kọ́ náà? (7) Báwo ni ó ṣe yẹ kí a múra ìdáhùn sílẹ̀? (8) Báwo ni a ṣe lè ṣe onírúurú àlàyé lórí ìbéèrè kan ṣoṣo? Jẹ́ kí àwọn mélòó kan ṣàlàyé ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ti ṣe láti mú kí wọ́n jàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀ láti inú Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́.—Tún wo ìwé Iṣetojọ Lati Ṣaṣepari Iṣẹ Ojiṣẹ Wa, ojú ìwé 65 sí 67.

Orin 95 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní October 26

Orin 98

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Dárúkọ àwọn ìtẹ̀jáde ògbólógbòó tí ó wà lọ́wọ́ nínú ìjọ tí a sì lè fi lọni nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá bí àǹfààní bá ti ṣí sílẹ̀. Níwọ̀n bí àkókò ọlidé yóò ti wà ní oṣù December, èyí yóò jẹ́ àkókò tí ó dára fún àwọn èwe tí ó ti ṣe batisí àti àwọn ẹlòmíràn láti ronú nípa ṣíṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.

20 min: Ìgbọràn Oníwà-Bí-Ọlọ́run Nínú Ìdílé Tí Ó Yapa Ní Ti Ìsìn. Ọ̀rọ̀ àsọyé tí a gbé karí Ilé-Ìṣọ́nà, June 1, 1995, ojú ìwé 26 sí 29. Fi inú rere fúnni níṣìírí àti ìṣílétí tí yóò ran àwọn tí ó ní alábàáṣègbéyàwó tí kò gbà gbọ́ lọ́wọ́ láti ní ìṣarasíhùwà rere kí wọ́n sì máa dara pọ̀ mọ́ ìjọ déédéé.

15 min: Dídé sí Ìpàdé Lákòókò. Ìjíròrò láàárín àwọn méjì tàbí mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ nípa ìṣòro tí ó wà nínú kí a máa pẹ́ dé ìpàdé. Wọ́n ṣàlàyé pé àwọn ipò tí kì í máa fi ìgbà gbogbo wáyé, irú bí ohun pàjáwìrì, ojú ọjọ́, ètò ìrìnnà ọkọ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ lè mú kí ẹnikẹ́ni pẹ́ dé. Ṣùgbọ́n, àwọn kan ti sọ pípẹ́dé dàṣà. Lọ́nà tí ń fúnni níṣìírí, àwùjọ náà jíròrò ohun tí ó pọndandan fún dídé lákòókò, wọ́n sì ṣàpèjúwe rẹ̀: (1) Ìmọrírì àtọkànwá fún àǹfààní tí a ní láti wá sí àwọn ìpàdé àti fún oúnjẹ tẹ̀mí àti ìbákẹ́gbẹ́ tí a ń pèsè níbẹ̀, (2) ìwéwèé dáadáa ṣáájú àti ṣíṣètò àwọn àlámọ̀rí ẹni, (3) ìfọwọ́sowọ́pọ̀ onímùúratán láàárín àwọn mẹ́ńbà ìdílé, (4) títètè gbéra àti fífi àlàfo àkókò sílẹ̀ fún àwọn ìṣòro tí a kò retí, àti (5) níní ojúlówó àníyàn láti má ṣe fa ìpínyà ọkàn fún àwọn ẹlòmíràn tí ó pésẹ̀. Gbogbo wọn fohùn ṣọ̀kan pé a lè ṣàtúnṣe ìṣòro pípẹ́dé yìí nípa sísapá nígbà gbogbo láti sunwọ̀n sí i.

Orin 86 àti àdúrà ìparí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́