Ìníyelórí Ìwé Ìròyìn Jí! Kan
Ní August 1993, ọkùnrin kan ní São Paulo, Brazil, rí ẹ̀dà Jí! kan nínú ibi ìdàdọ̀tísí. Lẹ́yìn tí ó kà á pẹ̀lú ìmọrírì, ó lo àdírẹ́sì ti Brazil láti kọ lẹ́tà sí Watch Tower Society. Ó kọ̀wé pé: “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi ìsọfúnni nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́ ránṣẹ́ sí mi. Ó dá mi lójú pé yóò ràn mí lọ́wọ́ gidigidi.”
A fi ohun tí ọkùnrin náà béèrè fún ránṣẹ́ sí ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan nítòsí ibi tí ó ń gbé. A ké sí ọkùnrin náà, a sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú rẹ̀. Ní September 1995, ọkùnrin náà fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ rẹ̀ sí Ọlọ́run hàn nípa ìrìbọmi ní àpéjọpọ̀ àgbègbè àwọn Ẹlẹ́rìí kan.
Kò yẹ kí a fojú kéré ìníyelórí ìwé ìròyìn Jí! kan. Ohun tí ó wà nínú rẹ̀ ń nípa lórí ìgbésí ayé lọ́nà ti ara ẹni. Bí o bá fẹ́ láti máa gba ìwé àtìgbàdégbà yìí déédéé, béèrè lọ́wọ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí kí ó kọ̀wé sí àdírẹ́sì tí ó yẹ lára àwọn tí a tò sí ojú ìwé 5.