Ṣàṣàyàn Àwọn Àpilẹ̀kọ Láti Fi Fa Àwọn Ènìyàn Mọ́ra Lórí Ohun Tí Wọ́n Ní Ọkàn-Ìfẹ́ sí Ní Pàtó
1 Gẹ́gẹ́ bí àwọn tafàtafà tí wọ́n máa ń fi ọfà wọn sun ohun tí wọ́n fẹ́ ta lọ́fà dáadáa, ọ̀pọ̀ akéde ìjọ àti aṣáájú ọ̀nà ń gbádùn àṣeyọrí títayọ ní lílo àwọn àpilẹ̀kọ tí wọ́n ṣàyàn láti inú Ilé Ìṣọ́ àti Jí! láti fi fa àwọn ènìyàn ní ìpínlẹ̀ wọn mọ́ra lórí ohun tí wọ́n ní ọkàn-ìfẹ́ sí ní pàtó. Wọ́n máa ń mọ ẹni tí ó ṣeé ṣe gan-an pé yóò fẹ́ láti ka àwọn àpilẹ̀kọ pàtó kan láti inú ìwé ìròyìn náà. Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe èyí?
2 Lákọ̀ọ́kọ́, wọ́n máa ń ka ìtẹ̀jáde kọ̀ọ̀kan tán pátápátá. Lẹ́yìn náà, wọn yóò bi ara wọn léèrè pé, Irú ẹni wo ni àpilẹ̀kọ kọ̀ọ̀kan yóò fà mọ́ra? Wọn yóò wá sapá láti bẹ àwọn tí ó ṣeé ṣe kí wọ́n ní ọkàn-ìfẹ́ nínú kíka àpilẹ̀kọ yẹn wò. Nígbà tí wọ́n bá fojú sọ́nà pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ìpínlẹ̀ wọn yóò fẹ́ ìtẹ̀jáde kan ní pàtó, wọ́n máa ń béèrè fún àfikún ẹ̀dà.
3 Àwọn Ènìyàn Ń Bọ̀wọ̀ Gidigidi fún Àwọn Ìwé Ìròyìn Wa: Ọ̀kan lára ẹni tí ó ń san àsansílẹ̀ owó fún ìwé ìròyìn wa, tí ó ń bá ilé iṣẹ́ tí ó ń ṣe ìwé ìròyìn Nàìjíríà tí àwọn ènìyàn ń kà jù lọ káàkiri àwọn orílẹ̀-èdè ṣiṣẹ́ sọ nípa Jí! pé: “Mo bá a yín yọ̀ fún ìwé ìròyìn yín tí ó dára jù lọ fún gbogbo ènìyàn yíká ayé.” Ẹnì kan tí ó máa ń fi ìyánhànhàn ka àwọn ìwé ìròyìn wa sọ pé: “Ẹ wo bí ó ti jẹ́ àgbàyanu ohun iyebíye ti ọgbọ́n tí kò ṣeé díye lé tó! Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé kò sí kókó ẹ̀kọ́ tí mo ní ọkàn-ìfẹ́ sí tí n kò ní rí kí a jíròrò rẹ̀ nínú àwọn ojú ìwé ọ̀kan nínú [ìwé ìròyìn] wọ̀nyí.”
4 Àwọn ìwé ìròyìn wọ̀nyí máa ń jíròrò kókó ẹ̀kọ́ púpọ̀ rẹpẹtẹ, títí kan Bíbélì, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú ayé, àwọn ọ̀ràn ìdílé, àwọn ìṣòro ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, ìtàn, sáyẹ́ǹsì, ẹranko àti ewéko, ká mẹ́nu kan díẹ̀ péré. Dájúdájú, ẹnì kan yóò túbọ̀ fẹ́ láti ka ohun kan nígbà tí ó bá ní í ṣe pẹ̀lú àwọn àìní, àyíká ipò, tàbí iṣẹ́ rẹ̀. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ènìyàn, tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ní ohun tí ó fẹ́ àti àwọn ìṣòro tirẹ̀ ní pàtó, ni a ń bá sọ̀rọ̀, ṣíṣàṣàyàn àwọn àpilẹ̀kọ ní pàtó láti fa àwọn ènìyàn tí a bá bá pàdé mọ́ra gbéṣẹ́ gidigidi.
5 Ṣàkíyèsí ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Àwọn Ẹlẹ́rìí méjì fi ìtẹ̀jáde Jí! September 8, 1996, lọ ẹnì kan tí ó máa ń kọ̀wé jáde nínú ìwé ìròyìn. Ó kọ̀wé pé: “Kí n tó ráyè sọ pé n kò ní ọkàn-ìfẹ́ sí i, ọ̀kan lára wọn fi kún un pé: ‘Àpilẹ̀kọ kan sọ nípa àwọn Àmẹ́ríńdíà. A mọ̀ pé o ti ń kọ̀wé gan-an nípa kókó ẹ̀kọ́ náà.’” Ó gba ìwé ìròyìn náà, ó sì ka àkójọ ọ̀rọ̀ nípa àwọn Íńdíà ní àkókò oúnjẹ àárọ̀, lẹ́yìn náà ó gbà pé “ó ta yọ” ó sì “jóòótọ́ látòkèdélẹ̀.”
6 Kí Ni Àwọn Ènìyàn Ní Ọkàn-Ìfẹ́ sí Ní Ìpínlẹ̀ Rẹ? Kí ni o ti rí nínú àwọn ìwé ìròyìn ní lọ́ọ́lọ́ọ́ tí ó lè fa àwọn onílé ìtajà àti àwọn amọṣẹ́dunjú ní ìpínlẹ̀ rẹ mọ́ra tàbí tí ó lè fa aládùúgbò, alábàáṣiṣẹ́, tàbí ọmọ kíláàsì rẹ mọ́ra? Kí ni àwọn agbẹjọ́rò, olùkọ́, àwọn olùgbaninímọ̀ràn ní ilé ẹ̀kọ́, àwọn òṣìṣẹ́ afẹ́nifẹ́re, àti àwọn òṣìṣẹ́ ìlera yóò lọ́kàn-ìfẹ́ sí? Níní àwọn tí o ń wàásù fún lọ́kàn bí o ṣe ń ṣàyẹ̀wò ìtẹ̀jáde kọ̀ọ̀kan yóò fún ọ ní ọ̀nà títayọ láti tan ọ̀rọ̀ òtítọ́ kálẹ̀.
7 Nígbà tí o bá rí ẹni tí ó fi àkànṣe ọkàn-ìfẹ́ hàn nínú àpilẹ̀kọ kan pàtó nínú Ilé Ìṣọ́ tàbí Jí! tí ó sì gba ìwé ìròyìn náà, o lè sọ pé: “Bí àpilẹ̀kọ kan bá wà nínú ìtẹ̀jáde mìíràn lọ́jọ́ iwájú tí mo ronú pé ìwọ yóò lọ́kàn-ìfẹ́ sí, èmi yóò láyọ̀ láti mú ẹ̀dà kan wá fún ọ.” Ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti fi ẹni náà kún ipa ìwé ìròyìn rẹ, kí o máa mú ìtẹ̀jáde àwọn ìwé ìròyìn tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé lọ síbẹ̀ nígbàkúùgbà. Ìyẹn jọ ohun tí a ti ṣe láti gba ìkésíni láti máa ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n ti lè ní ọkàn-ìfẹ́ ní pàtàkì nínú àwọn àpilẹ̀kọ kan tí ó wà nínú àwọn ìwé ìròyìn wa.
8 Ní Ète Ìlépa Tẹ̀mí: Ní ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, ọkùnrin kan tí ó fara jin iṣẹ́ ìgbésí ayé gba ìwé ìròyìn Jí! kan nípa kókó ẹ̀kọ́ tí ó lọ́kàn-ìfẹ́ sí. Ṣùgbọ́n, ọkùnrin onísìn yìí tún ka ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ tí a fi pẹ̀lú rẹ̀, tí ó ní àpilẹ̀kọ kan tí ó sún un láti ṣàyẹ̀wò kínníkínní nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀ ọlọ́jọ́ pípẹ́ nínú Mẹ́talọ́kan. Ní oṣù mẹ́fà lẹ́yìn náà, a batisí rẹ̀! Nítorí náà, má ṣe lọ́ tìkọ̀ láti bá àwọn tí ń ka ìwé ìròyìn wa jíròrò nípa Ìwé Mímọ́. O lè nasẹ̀ ìwé pẹlẹbẹ náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? kí o sì fi lọ̀ ọ́ pé ìwọ yóò máa lo ìṣẹ́jú díẹ̀ láti jíròrò ẹ̀kọ́ kan nígbà ìbẹ̀wò kọ̀ọ̀kan tí ó bá kó àwọn ìwé ìròyìn tuntun wá.
9 Ronú jinlẹ̀ nípa àwọn tí yóò mọrírì níní àwọn ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tí ó jẹ́ ti lọ́ọ́lọ́ọ́ nínú àwọn ìpadàbẹ̀wò rẹ àti àwọn tí o ń pàdé lẹ́nu iṣẹ́ ajé. Lẹ́yìn náà, sapá taápọntaápọn láti dé ọ̀dọ̀ wọn. Mú àwọn ìwé ìròyìn ṣíṣeyebíye wọ̀nyí dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀ ènìyàn bí o bá ti lè ṣe é tó. Má sì ṣe gbàgbé pé bí o ti ń sakun láti ran àwọn ènìyàn púpọ̀ sí i lọ́wọ́ láti ka àwọn ìwé ìròyìn wa, o ń “fọ́n oúnjẹ rẹ sí ojú omi.” Bí àkókò ti ń lọ, o lè ṣàṣeyọrí ní rírí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹlẹgbẹ́ rẹ ọjọ́ iwájú.—Oníw. 11:1, 6.