ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/98 ojú ìwé 7
  • Kíkọ́ Àwọn Àgbà Bí A Ṣe Ń Kàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kíkọ́ Àwọn Àgbà Bí A Ṣe Ń Kàwé
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
km 5/98 ojú ìwé 7

Kíkọ́ Àwọn Àgbà Bí A Ṣe Ń Kàwé

Mímọ̀wèékà ń mú ayọ̀ inú lọ́hùn-ún àti òye tí ó pọ̀ sí i wá. Èyí tí ó túbọ̀ ń mérè wá ni kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti fífi í sílò tí ń mú ìyè àìnípẹ̀kun wá. (Ìṣí. 1:3) Ọ̀pọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí sin Jèhófà ní ọjọ́ ogbó wọn. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn wọ̀nyí máa ń gbádùn ìtẹ́lọ́rùn inú lọ́hùn-ún nígbà tí wọ́n bá lè ‘fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ ní ti pé bóyá bẹ́ẹ̀ ni nǹkan wọ̀nyí rí.’ (Ìṣe 17:11) Nítorí náà, ó yẹ kí gbogbo wa ní ọkàn-ìfẹ́ láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ẹlòmíràn tí ó ṣeé ṣe kí wọ́n má fi bẹ́ẹ̀ ní àǹfààní láti kàwé fúnra wọn. Àwọn kókó tí ó tẹ̀ lé e yìí yóò ran àwọn tí wọ́n ní àǹfààní láti bójú tó kíláàsì mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà lọ́wọ́.

◼ Má ṣe béèrè ohun tí ó pọ̀ jù, má sì ṣe da ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àkójọ ọ̀rọ̀ bo akẹ́kọ̀ọ́ ní ìjókòó kan ṣoṣo. Èyí lè mú kí akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀wẹ̀sì, kí ó sì ṣíwọ́ wíwá sí kíláàsì.

◼ Máa fúnni níṣìírí, kí o sì máa fojú sọ́nà fún rere nígbà gbogbo. A máa ń mú òye ìwé kíkà dàgbà díẹ̀díẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé ni. Ó yẹ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa rí ìtẹ́lọ́rùn nínú ìtẹ̀síwájú wọn. Fún àwọn akéde níṣìírí láti máa fi ohun tí wọ́n ń kọ́ sílò bí ó bá ti lè yá tó. Àwọn olùkọ́ lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ka ìdáhùn tàbí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ní àwọn ìpàdé Kristẹni tàbí láti ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Èyí yóò fi bí kíláàsì mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà ti wúlò tó hàn lọ́nà lílágbára.

◼ Má ṣe fi àkókò ṣòfò lórí àwọn ọ̀ràn mìíràn. Ọwọ́ àwọn àgbàlagbà máa ń dí. Lo àwọn àkókò ìjókòó ní kíláàsì lọ́nà tí ó dára jù lọ láti kọ́ wọn ní àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì.

◼ Máa bọ̀wọ̀ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nígbà gbogbo, máa fún wọn ní iyì tí ó tọ́ sí wọn. Má ṣe dójú tì wọ́n, má sì ṣe tẹ́ńbẹ́lú wọn. Wà lójúfò nípa ìṣòro ẹnì kọ̀ọ̀kan. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan lè má lè ka àwọn lẹ́tà kéékèèké nítorí pé wọ́n nílò awò ojú. Àwọn mìíràn lè má lè gbọ́rọ̀ dáadáa. Ó yẹ kí a fi ìgbatẹnirò àti òye bá gbogbo wọn lò.

◼ Láti tẹ̀ síwájú, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ gbọ́dọ̀ fi ọ̀pọ̀ wákàtí ṣe iṣẹ́ ilé lórí ìtọ́ni tí a fún wọn ní kíláàsì ní wákàtí kọ̀ọ̀kan. Olùkọ́ lè ké sí àwọn ẹlòmíràn láti ran àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ilé wọn.

Paríparí rẹ̀, ní sùúrù, máa fúnni níṣìírí, máa fìgbà gbogbo gbóríyìn fúnni gidigidi. Nípa fífi àwọn ìlànà tí ó wà lókè yìí sílò, ìwọ yóò fi kún ìdùnnú àwọn àgbà tí wọ́n nílò ìrànwọ́ láti mọ bí a ti í kàwé.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́