Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Pẹ̀lú Àwọn Tó Ò Ń Fún Ní Ìwé Ìròyìn Déédéé
1. Kí nìdí tí ètò Jèhófà ti fi máa ń fún àwọn akéde níṣìírí láti ní àwọn tí wọ́n á máa fún ní ìwé ìròyìn déédéé?
1 Àwọn kan kì í fẹ́ ká máa wá kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ wọ́n máa ń fẹ́ ka àwọn ìwé ìròyìn wa. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ọjọ́ pẹ́ tí ètò Jèhófà ti ń fún wa níṣìírí pé ká máa mú àwọn ìwé ìròyìn wa lọ fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ déédéé. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tó bá ń ka àwọn ìwé ìròyìn wa déédéé máa ń bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìyánhànhàn fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (1 Pét. 2:2) Tó bá yá, wọ́n lè ka ohun kan tó máa wọ̀ wọ́n lọ́kàn gan-an, èyí sì lè mú kí wọ́n gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
2. Báwo la ṣe lè jẹ́ kí àwọn tá à ń fún ní ìwé ìròyìn déédéé nífẹ̀ẹ́ sí ìwàásù wa?
2 “Bomi Rin” Irúgbìn Òtítọ́: Dípò kó o kan fi ìwé ìròyìn náà sílẹ̀ kó o sì yísẹ̀ pa dà, bá onítọ̀hún sọ̀rọ̀ bóyá ẹ lè bẹ̀rẹ̀ sí í mọwọ́ ara yín. Èyí á jẹ́ kó o lè mọ ipò tí onítọ̀hún wà, ohun tó nífẹ̀ẹ́ sí àti ohun tó gbà gbọ́, wàá sì lè máa fi ìjìnlẹ̀ òye bá a sọ̀rọ̀. (Òwe 16:23) Gbogbo ìgbà tó o bá ti fẹ́ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ni kó o máa múra sílẹ̀. Tó bá ṣeé ṣe, ní ṣókí sọ kókó kan látinú ìwé ìròyìn náà àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ti ọ̀rọ̀ rẹ lẹ́yìn, o máa tipa báyìí bomi rin irúgbìn òtítọ́ tó bá wà lọ́kàn rẹ̀. (1 Kọ́r. 3:6) Máa ṣàkọsílẹ̀ ọjọ́ tó o lọ síbẹ̀, ìwé tó o fún un, kókó tẹ́ ẹ sọ̀rọ̀ lé lórí àtàwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tẹ́ ẹ jíròrò.
3. Báwo ló ṣe yẹ ká máa pa dà lọ sọ́dọ̀ àwọn tá a máa ń fún ní ìwé ìròyìn déédéé tó?
3 Báwo Ló Ṣe Yẹ Kó O Máa Pa Dà Lọ Tó? Ẹ̀ẹ̀kan lóṣù ló yẹ kó o máa pa dà lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ò ń fún ní àwọn ìwé ìròyìn déédéé, kó o lè fún wọn ní àwọn ìwé ìròyìn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dé. Àmọ́, tó o bá rí i pé onítọ̀hún nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ, o lè máa lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ léraléra bí o bá ṣe ráyè sí. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀sẹ̀ kan tàbí méjì lẹ́yìn tó o bá fún un ní àwọn ìwé ìròyìn náà, o lè pa dà lọ kó o sì sọ pé, “Mo ní kí n yà kí n lè fi nǹkan kan hàn ẹ́ nínú ìwé ìròyìn tí mo fún ẹ lọ́jọ́ yẹn.” Èyí máa jẹ́ kó wu ẹni náà láti ka àpilẹ̀kọ náà. Tó bá jẹ́ pé ó ti kà á, o lè béèrè èrò rẹ̀ nípa àpilẹ̀kọ náà, ẹ sì lè jọ jíròrò rẹ̀ ní ṣókí. Tó bá jẹ́ pé ẹnì náà máa ń ka àwọn ìwé wa míì, o lè pa dà lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ kó o sì fún un ní ìwé àṣàrò kúkúrú, ìwé pẹlẹbẹ tàbí ìwé tá a fi ń lọni lóṣù yẹn.
4. Látìgbàdégbà, kí la lè ṣe láti mọ̀ bóyá àwọn tá à ń fún ní ìwé ìròyìn déédéé máa fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
4 Má ṣe dúró dìgbà tí onílé bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ní kó o wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́. Ìwọ ni kó o wá bó o ṣe máa bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́. Tó bá tiẹ̀ ti sọ tẹ́lẹ̀ pé òun ò fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, o lè máa fi àpilẹ̀kọ náà, “Ohun Tí Bíbélì Sọ,” tó máa ń wà nínú Ilé Ìṣọ́ hàn án látìgbàdégbà, kó o wò ó bóyá ó máa fẹ́ kẹ́ ẹ jọ jíròrò rẹ̀. O lè gbìyànjú láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ẹnu ọ̀nà. Àmọ́, tí o kò bá lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú ẹni náà, o ṣì le máa mú àwọn ìwé ìròyìn wa lọ fún un, bóyá lọ́jọ́ kan ó máa gbà ká bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.