Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ sí Í Ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Àwọn Tá À Ń Fún Ní Ìwé Ìròyìn
1. Torí kí la ṣe ń fún àwọn èèyàn ní ìwé ìròyìn?
1 Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! la sábà máa ń lò nínú iṣẹ́ ìsìn pápá lọ́jọọjọ́ Sátidé. Àmọ́, ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ lèyí wulẹ̀ jẹ́ tá a bá ń ṣe ojúṣe wa, ìyẹn ni láti kọ́ àwọn ọlọ́kàn rere ní òtítọ́. Díẹ̀ lára àwọn àbá tó lè wúlò bá a bá ń lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni nígbà tá a bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò torí àtilè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wà nínú àpilẹ̀kọ yìí. Rántí pé o ní láti mú un bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu, kó o sì sọ ọ́ lọ́rọ̀ ara ẹ. Má bẹ̀rù láti lo ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn bó bá jẹ́ pé ìyẹn ló máa ń jẹ́ ẹ lọ́wọ́.
2. Báwo la ṣe lè lo àwọn ojú ìwé àkọ́kọ́ nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
2 Lo Àwọn Ojú Ìwé Àkọ́kọ́: Bó o bá padà lọ, o lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ báyìí: “Ìwé ìròyìn tó o gbà lọ́jọ́sí ṣàlàyé nípa ohun tó wà nínú Bíbélì. Ìwọ wo ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kéèyàn máa ka Bíbélì.” Ka Aísáyà 48:17, 18; Jòhánù 17:3 tàbí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mìíràn tó bá yẹ. Lẹ́yìn tó o bá sì ti fi ìwé náà han onílé, o lè fún un ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, kó o wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé:
◼ “Bíbélì jẹ́ ká ní ìrètí tó dájú nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú.” Fi ojú ìwé 4 àti 5 han onílé, kó o wá bi í pé, “Èwo lára àwọn ìlérí tó wà lójú ìwé yìí lo máa fẹ́ kí Ọlọ́run mú ṣẹ?” Fi àkòrí tó jíròrò ìlérí tí onílé fẹ́ kí Ọlọ́run mú ṣẹ hàn –án nínú ìwé náà, kó o sì jíròrò ìpínrọ̀ kan tàbí méjì ní ṣókí, bí onílé bá fẹ́ bẹ́ẹ̀.
◼ O sì lè sọ pé, “Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè tó ṣe kókó jù lọ nígbèésí ayé.” Fi ojú ìwé 6 han onílé, kó o wá bi í bóyá ó ti fìgbà kan rí ṣe kàyéfì nípa èyíkéyìí lára àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ ojú ewé yẹn. Ṣí ìwé náà sí àkòrí tó dáhùn ìbéèrè náà, kó o sì jíròrò ìpínrọ̀ kan tàbí méjì ní ṣókí.
◼ O sì lè ṣí ìwé náà sí ojú ìwé 2 lábẹ́ àkòrí tá a pè ní “Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí,” kó o wá bi í pé èwo ló wù ú jù nínú àwọn àkòrí tó wà níbẹ̀. Ṣí ìwé náà sí orí tó fọwọ́ kàn, kó o sì fi bá a ṣe ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́ hàn án ní ṣókí.
3. Báwo la ṣe lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèkẹ́kọ̀ọ́ ẹni tó gba ìwé ìròyìn tó sọ̀rọ̀ nípa (a) bí nǹkan ṣe ń burú sí i nínú ayé? (b) ìdílé? (d) ohun tó jẹ́ kí Bíbélì ṣeé gbára lé?
3 Bi Onílé ní Ìbéèrè Kan Tẹ́ Ẹ Lè Jíròrò Nígbà Míì: Nǹkan míì tó o tún lè ṣe ni pé kó o wá ìbéèrè kan bi onílé lẹ́yìn ìjíròrò àkọ́kọ́, tó máa jẹ́ kó fẹ́ kó o padà wá. Bí onílé bá ti gba ìwé ìròyìn tó o fún un, bi í ní ìbéèrè kan kó o sì sọ fún un pé ìgbà tó o bá padà wá lo máa dáhùn rẹ̀. Gbìyànjú láti ṣètò tó mọ́yán lórí tó máa jẹ́ kó o lè padà lọ, kó o sì rí i pé o ò yẹ àdéhùn. (Mát. 5:37) Nígbà tó o bá padà débẹ̀, rán onílé létí ìbéèrè tó o béèrè lọ́jọ́ tẹ́ ẹ kọ́kọ́ jọ jíròrò, kó o wá ka ìdáhùn ìbéèrè náà látinú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, kó o sì jíròrò rẹ̀ ní ṣókí. Fún un ní ẹ̀dà kan, kóun náà lè máa fojú bá a lọ. Àpẹẹrẹ mélòó kan rèé:
◼ Bó bá jẹ́ pé ìwé ìròyìn tó sọ̀rọ̀ nípa bí nǹkan ṣe ń burú sí i nínú ayé lẹni náà gbà, o lè sọ pé, “Nígbà míì tí n bá padà wá, a lè jíròrò bí Bíbélì ṣe dáhùn ìbéèrè yìí, Àwọn àtúnṣe wo ni Ọlọ́run máa ṣe sórí ilẹ̀ ayé wa yìí?” Bó o bá padà débẹ̀, mú ọ̀rọ̀ látinú ìpínrọ̀ 4 àti 5. O sì lè bi í ní ìbéèrè náà, “Ṣé àmúwá Ọlọ́run làwọn àjálù?” Nígbà tó o bá padà débẹ̀, fi orí 1 ìpínrọ̀ 7 àti 8 hàn án.
◼ Bó bá jẹ́ pé ìwé ìròyìn tó sọ̀rọ̀ nípa ìdílé ló gbà, kó o tó kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, o lè bi í pé, “Kí ló yẹ kí bàbá, ìyá àtàwọn ọmọ máa ṣe kí wọ́n bàa lè láyọ̀?” Nígbà tó o bá padà débẹ̀, jíròrò orí 14, ìpínrọ̀ 4.
◼ Bó bá jẹ́ pé ìwé ìròyìn tó sọ̀rọ̀ nípa ohun tó jẹ́ kí Bíbélì ṣeé gbára lé ló gbà, o lè bi í pé, “Ṣé Bíbélì máa ń tọ̀nà nígbà tó bá sọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì?” Nígbà tó o bá padà lọ, jíròrò orí 2, ìpínrọ̀ 8.
4. Kí ni ṣíṣe bí ẹni tá a wàásù fún bá lóun ò gba ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni?
4 Bó o bá ti fẹ́ kúrò lọ́dọ̀ ẹni náà, bi í ní ìbéèrè tó o máa dáhùn nígbà tó o bá padà lọ sọ́dọ̀ rẹ̀. Nígbà tí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà bá sì ti fẹsẹ̀ múlẹ̀, bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe é ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé, ìyẹn ni pé látorí àkọ́kọ́ títí dé orí tó kẹ́yìn. Bí ẹni tá a wàásù fún náà ò bá gba ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni ńkọ́? O ṣì lè máa mú ìwé ìròyìn lọ fún un, kó o sì máa fi Ìwé Mímọ́ bá a jíròrò. Bó o ṣe ń jẹ́ kí ìfẹ́ tó ní jinlẹ̀ sí i, ó lè wá dẹni tó máa nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́.
5. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ ṣe ju pé ká kàn fún àwọn èèyàn ní ìwé ìròyìn lọ?
5 Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lè wọ ẹnì kan lọ́kàn débi tó fi máa fẹ́ láti mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gan-an. Nítorí náà, gbìyànjú láti rí i pé o bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèkẹ́kọ̀ọ́ ẹni tó bá gba ìwé ìròyìn lọ́wọ́ rẹ. Nípa báyìí, a ó lè máa ṣègbọràn sí ìtọ́ni tí Jésù fún wa pé ká ‘máa sọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn,’ ká sì “máa kọ́ wọn.”—Mát. 28:19, 20.