Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Máa Fi Bí A Ṣe Ń Ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Nínú Ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni Han Àwọn Èèyàn
Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì: Ó lè má yé ọ̀pọ̀ èèyàn tá a bá sọ fún wọn pé a fẹ́ fi hàn wọ́n bí a ṣe máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́. Wọ́n lè rò pé ńṣe là ń sọ pé kí àwọn wá dara pọ̀ mọ́ àwùjọ kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí kí àwọn wá forúkọ sílẹ̀ fún ètò ẹ̀kọ́ kan. Dípò tí a ó kàn máa fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ àwọn èèyàn, ohun tó dáa ni pé ká fi hàn wọ́n bí a ṣe máa ń ṣe é. A lè lo ìṣẹ́jú díẹ̀ lẹ́nu ọ̀nà ẹni tí à ń wàásù fún, ká fi hàn án bí a ṣe máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́nà tó rọrùn táá sì lóye ohun tó ń kọ́.
Gbìyànjú Èyí Lóṣù Yìí:
Gbàdúrà fún ìbùkún Jèhófà lórí ìsapá rẹ láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tuntun.—Fílí. 2:13.
Tó o bá wà lóde ẹ̀rí, lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni láti fi bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì han ẹni tó o wàásù fún tàbí kó o fi fídíò náà Báwo La Ṣe Máa Ń Ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? hàn án, o lè ṣe bẹ́ẹ̀ ó kéré tán ní ẹ̀ẹ̀kan lóṣù yìí.