Ǹjẹ́ O Ti Fi Bá A Ṣe Ń Ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Han Àwọn Èèyàn Nígbà Àkọ́kọ́?
Nígbà tá a bá fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ àwọn onílé kan, wọ́n máa ń sọ pé àwọn ò nífẹ̀ẹ́ sí i tàbí pé àwọn ti ní ètò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ṣọ́ọ̀ṣì àwọn. Tórí pé ojú bí wọ́n ṣe máa ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní àwọn ilé ìjọsìn wọn ni wọ́n fi ń wo ọ̀rọ̀ náà, wọn kò mọ àǹfààní tí wọ́n máa jẹ nígbà tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọn ò sì mọ bó ṣe máa gbádùn mọ́ wọn tó. Nítorí náà, dípò ká kàn fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ̀ wọ́n, ó máa dáa tá a bá lo ìṣẹ́jú mélòó kan láti fi bá a ṣe ń ṣe é hàn wọ́n nígbà àkọ́kọ́ tá a wàásù fún wọn. Ká sọ ọ lọ́nà àpèjúwe, dípò kó o kàn sọ fún wọn pé o mọ oúnjẹ sè dáadáa àti pé wàá gbé oúnjẹ wá fún wọn tó o bá pa dà wá, o ò ṣe kúkú fún wọn ní ìtọ́wò oúnjẹ náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀! Àpẹẹrẹ bó o ṣe lè ṣe é láàárín ìṣẹ́jú mélòó kan nìyí, a gbé e ka àbá tó wà ní ojú ìwé 6 nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti March 2006:
“Ṣó o rò pé ọjọ́ kan á jọ́kan tí ọ̀rọ̀ yìí á nímùúṣẹ? [Ka Aísáyà 33:24, kó o sì jẹ́ kó fèsì.] Jẹ́ kí n fi ohùn kan tí wàá nífẹ̀ẹ́ sí nípa ọ̀rọ̀ yìí hàn ẹ́.” Fún onílé ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, kó o sì ní kó wo ìpínrọ̀ 22 ní ojú ìwé 36. Ka ìbéèrè tó wà ní ìsàlẹ̀ ojú ìwé yẹn, kó o wá ní kí onílé máa fojú wá ìdáhùn nígbà tó o bá ń ka ìpínrọ̀ náà. Lẹ́yìn tó o bá kà á tán, bi í ní ìbéèrè náà lẹ́ẹ̀kan sí i, kó o sì fetí sí ìdáhùn rẹ̀. Ẹ tún jọ ka òmíràn lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀. Bi í ní ìbéèrè kan tí ẹ máa dáhùn nígbà tó o bá pa dà wá, kó o sì ṣètò tó ṣe gúnmọ́ láti pa dà lọ bẹ̀ ẹ́ wò. O ti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn!