Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ May 31
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ MAY 31
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: 2 Sámúẹ́lì 16-18
No. 1: 2 Sámúẹ́lì 17:1-13
No. 2: Ìdí Tá A Fi Pe Jésù Ní “Olúwa Sábáàtì” (Mát. 12:8)
No. 3: Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Àwọn Áńgẹ́lì Tó Ṣọ̀tẹ̀ (td 10D)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn ìfilọ̀.
10 min: “Ǹjẹ́ O Ti Fi Bá A Ṣe Ń Ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Han Àwọn Èèyàn Nígbà Àkọ́kọ́?” Àsọyé. Lẹ́yìn tó o bá ti ṣàlàyé àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ náà, ṣe àṣefihàn rẹ̀.
20 min: “Bá A Ṣe Lè Kọ́ Àwọn Ẹni Tuntun Láti Máa Wàásù.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Lẹ́yìn tó o bá jíròrò ìpínrọ̀ 5, ṣe àṣefihàn bí alàgbà kan ṣe ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú akéde tuntun kan lóde ẹ̀rí. Akéde tuntun náà gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kalẹ̀, àmọ́ kò ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kankan. Lẹ́yìn tí wọ́n fi ibẹ̀ sílẹ̀, alàgbà náà fi ọgbọ́n fún akéde náà ní àbá tó máa ràn án lọ́wọ́ kó lè máa lo Bíbélì nígbà tó bá ń wàásù.