Bá A Ṣe Lè Fi Ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Kọ́ Àwọn Èèyàn Lẹ́kọ̀ọ́
1. Báwo la ṣe ṣe ìwé Ìròyìn Ayọ̀?
1 Bá a ṣe sọ nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù July, ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ìwé tá a fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ ni ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! A kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe àyọkà àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ nínú ìwé yìí torí kí àwọn tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lè rí i pé inú Bíbélì ni ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń kọ́ ti wá ní tààràtà. Ọ̀pọ̀ ìwé tá a fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ la ṣe lọ́nà tí àwọn tó ń kà á fi lè lóye rẹ̀ láìjẹ́ pé ẹnì kan ṣàlàyé rẹ̀ fún wọn. Àmọ́, a ṣe ìwé Ìròyìn Ayọ̀ lọ́nà tó fi jẹ́ pé àwa la máa fi kọ́ onítọ̀hún lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Torí náà, tá a bá fún àwọn èèyàn ní ìwé yìí, ó yẹ ká fi bá a ṣe máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀ han ẹni tá a bá fún lọ́nà táá fi máa wù ú láti mọ ìròyìn ayọ̀ tó wà nínú Bíbélì.—Mát. 13:44.
2. Báwo la ṣe lè lo ìwé Ìròyìn Ayọ̀ nígbà tá a bá kọ́kọ́ wàásù fún ẹnì kan?
2 Nígbà Tá A Bá Kọ́kọ́ Wàásù fún Ẹnì Kan: O lè sọ pé: “Ibi tọ́rọ̀ ayé yìí ń lọ ti tojú sú àwọn èèyàn. Ǹjẹ́ o rò pé nǹkan ṣì lè dáa? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìròyìn ayọ̀ tó lè fún wa ní ìrètí wà nínú Bíbélì. Wo díẹ̀ lára àwọn ìbéèrè tí Bíbélì dáhùn lójú ìwé yìí.” Fún onílé ní ìwé náà, kó o sì ní kó yan èyí tó bá wù ú nínú àwọn ìbéèrè tó wà ní ẹ̀yìn ìwé náà. Lẹ́yìn náà, fi bá a ṣe máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn án nípa lílo ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ nínú ẹ̀kọ́ tó yàn. Ọ̀nà míì tó o lè gbà lo ìwé yìí ni pé kó o bi onílé ní ìbéèrè kan táá fẹ́ mọ ìdáhùn rẹ̀ nínú ẹ̀kọ́ tó o yàn, kó o wá fi bó ṣe lè rí ìdáhùn Bíbélì sí ìbéèrè náà hàn án nínú ìwé pẹlẹbẹ náà. Àwọn akéde kan máa ń fi fídíò kan tí wọ́n wà jáde lórí ìkànnì jw.org/yo, tó bá ẹ̀kọ́ tí wọ́n ń jíròrò mu han ẹni tí wọ́n bá bá sọ̀rọ̀.
3. Sọ bá a ṣe lè fi ìwé Ìròyìn Ayọ̀ ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
3 Bá A Ṣe Lè Fi Ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (1) Ka ìbéèrè tá a kọ nọ́ńbà sí, tá a fi lẹ́tà tó dúdú yàtọ̀ kọ, èyí táá jẹ́ kí onílé rí kókó pàtàkì inú ẹ̀kọ́ náà. (2) Ka ìpínrọ̀ tó wà nísàlẹ̀ ìbéèrè náà. (3) Ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a fi lẹ́tà wínníwínní kọ, kó o sì fi ọgbọ́n béèrè àwọn ìbéèrè tó máa jẹ́ kí onílé rí bí Ìwé Mímọ́ ṣe dáhùn ìbéèrè tá a kọ nọ́ńbà sí náà. (4) O lè tẹ̀ lé ìtọ́ni tó wà ní kókó 2 àti 3 tí ìbéèrè náà bá ní ìpínrọ̀ míì. Tí fídíò kan bá wà tó bá ìbéèrè tí ò ń bá onítọ̀hùn jíròrò mu, àmọ́ tí o kò tíì fi hàn án tẹ́lẹ̀, o lè fi han ẹni náà láàárín kan nínú ìjíròrò yín. (5) Lákòótán, sọ pé kí onílé dáhùn ìbéèrè tá a kọ nọ́ńbà sí kó o lè mọ̀ bóyá ó ti lóye ohun tẹ́ ẹ kọ́.
4. Kí ló máa jẹ́ ká mọ ìwé Ìròyìn Ayọ̀ lò lọ́nà tó já fáfá?
4 Sapá láti mọ ìwé pẹlẹbẹ yìí lò dáadáa. Máa lò ó nígbàkigbà tó o bá rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀. Kó o tó lọ kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́, ronú nípa onítọ̀hún àti ọ̀nà tó dáa jù lọ tó o lè gbà bá a fèrò wérò lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nínú ẹ̀kọ́ náà. (Òwe 15:28; Ìṣe 17:2, 3) Bó o ṣe ń já fáfá sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́, wàá máa rí i pé ìwé pẹlẹbẹ yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìwé tó o fẹ́ràn jù lọ tó o lè lò láti máa fi kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́!