ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/97 ojú ìwé 8
  • Gbára Lé Jèhófà Láti Mú Kí Àwọn Nǹkan Dàgbà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Gbára Lé Jèhófà Láti Mú Kí Àwọn Nǹkan Dàgbà
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bá A Ṣe Lè Lo Ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Fara Wé Jèhófà Nípa Fífi Tinútinú Ṣàníyàn Nípa Àwọn Ẹlòmíràn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Àwọn Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Tí A Dábàá fún Lílò Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Pápá
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2002
  • Fífi Ìwé Pẹlẹbẹ Béèrè Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
km 8/97 ojú ìwé 8

Gbára Lé Jèhófà Láti Mú Kí Àwọn Nǹkan Dàgbà

1 “Fún ìgbà àkọ́kọ́ mo nírìírí ìdùnnú aláìlẹ́gbẹ́ ti ṣíṣèrànwọ́ láti dá ìjọ tuntun kan sílẹ̀. Èyí gbà ju ọdún méjì tí ó kún fún iṣẹ́ aláápọn, àdúrà ìgbà gbogbo àti gbígbára lé Jèhófà ẹni ‘tí ń mú kí nǹkan dàgbà.’” Bí aṣáájú ọ̀nà afitọkàntọkàn ṣiṣẹ́ kan ṣe kọ̀wé nìyí, ẹni tí ó kọ́ nípa ìdí tí ó fi yẹ kí a gbára lé Jèhófà fún ìmúdàgbà. (1 Kọ́r. 3:5-9) Bí a ṣe ń wá àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ìtẹ̀sí ọkàn sí nǹkan tẹ̀mí kiri, àwa pẹ̀lú nílò ìtìlẹ́yìn Ọlọ́run bí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa yóò bá mú èso jáde.—Òwe 3:5, 6.

2 Ìdàgbà Ń Béèrè Ìtọ́jú: Hóró òtítọ́ ni a ní láti tọ́jú bí yóò bá dàgbà. Pípadà ṣe ìkésíni láàárín ọjọ́ kan tàbí méjì lẹ́yìn ìbẹ̀wò àkọ́kọ́ sábà máa ń mú èso rere jáde. Jẹ́ ọlọ́yàyà kí o sì yá mọ́ni. Jẹ́ kí ara tu ẹni náà. Má ṣe nìkan sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà. Jẹ́ kí ó mọ irú ẹni tí o jẹ́, kí o sì fi hàn pé o lọ́kàn ìfẹ́ nínú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan.

3 Ní July àti títí dé August, a óò pọkàn pọ̀ sórí fífi onírúurú àwọn ìwé pẹlẹbẹ lọ àwọn ènìyàn tí a bá bá pàdé. Ṣùgbọ́n, a tún ní láti pa dà ṣiṣẹ́ lórí ìfẹ́ ọkàn tí a bá rí àti lórí àwọn ìwé tí a bá fi sóde. A ń ṣe èyí nípa ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò àti fífi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọni. (Mát. 28:19, 20) Fún ète yìí, a lè lo ìwé pẹlẹbẹ Béèrè láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́. Àwọn àbá mẹ́rin tí ó tẹ̀ lé e yìí lè ràn ọ́ lọ́wọ́.

4 Bí o bá ti bá ẹnì kan tí ó ń ṣàníyàn nípa ibi tí ayé yìí ń forí lé sọ̀rọ̀, o lè tún bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ náà nípa sísọ pé:

◼ “Mo gbà gbọ́ pé ìwọ ń ṣàníyàn bí èmi náà nípa ìwólulẹ̀ ìwà rere láwùjọ. A ń gbọ́ àwọn ìròyìn tí ń mú ìrora ọkàn báni nípa ìwà ipá abẹ́lé, tí ó ń yọrí sí ìfìyàjẹ àwọn ọmọdé, òbí àti alábàáṣègbéyàwó. Ó sì dà bí ẹni pé ọ̀pọ̀ ènìyàn kò ronú pé ó burú láti purọ́ tàbí jalè kí wọ́n lè tẹ́ ìfẹ́ ara wọn lọ́rùn. O ha rò pé Ọlọ́run bìkítà nípa bí àwọn ènìyàn ṣe ń gbé ìgbésí ayé wọn bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ọlọ́run gbé ọ̀pá ìdiwọ̀n pàtó kalẹ̀ fún ènìyàn láti máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀, ní tòótọ́, wọn kì í sì í ṣe ẹrù ìnira fún wa.” Ka Jòhánù Kíní 5:3. Lẹ́yìn náà, fún un ní ìwé pẹlẹbẹ Béèrè, kí o sì ṣí i sí ẹ̀kọ́ 10. Ka ìpínrọ̀ àkọ́kọ́. Tọ́ka sí àwọn ọ̀rọ̀ àti gbólóhùn tí a kọ wínníwínní ní ìbẹ̀rẹ̀ ìpínrọ̀ 2 sí 6, kí o sì béèrè lọ́wọ́ onílé nípa àwọn àṣà tí òun rò pé ó ń ṣe ìpalára jù lọ fún àwùjọ. Ka ìpínrọ̀ tí ó tan mọ́ ọn kí o sì ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tàbí méjì bí àyè bá ti wà tó. Parí rẹ̀ nípa kíka ìpínrọ̀ 7, lẹ́yìn náà kí o sì ṣètò láti pa dà wá fún ìjíròrò síwájú sí i.

5 Fún àwọn tí o ti bá pàdé tí ọ̀ràn ìdílé jẹ lọ́kàn, o lè sọ ohun kan bí èyí:

◼ “O ha rò pé ó bọ́gbọ́n mu láti retí pé Ẹlẹ́dàá yóò fún wa ní àwọn irinṣẹ́ tí a nílò láti gbé ìgbésí ayé ìdílé aláṣeyọrí sí rere ró bí?” Jẹ́ kí ó fèsì. Mú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè jáde, ṣí i sí ẹ̀kọ́ 8, kí o sì ṣàlàyé pé ó ní àwọn ìlànà Bíbélì nínú fún gbogbo mẹ́ńbà ìdílé. Fi àṣefihàn bí a ṣe lè lo ìwé pẹlẹbẹ náà pẹ̀lú Bíbélì láti jàǹfààní tí ó pọ̀ jù lọ láti inú rẹ̀ lọ̀ ọ́. Tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tí ó wà ní ojú ewé 2 ìwé pẹlẹbẹ náà. Ṣètò láti pa dà ṣe ìkésíni láti máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ lórí ẹ̀kọ́ náà lọ, tàbí bí o bá parí rẹ̀, láti kọ́ ẹ̀kọ́ mìíràn tí onílé bá yàn nínú ìwé pẹlẹbẹ náà.

6 Ọ̀nà ìgbàyọsíni tààràtà kan nìyí tí o lè lò láti fi ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa lọni. Fi ìwé pẹlẹbẹ “Béèrè” hàn án, kí o sì sọ pé:

◼ “Ìwé pẹlẹbẹ yìí ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ ẹ̀kọ́ tí ó kún rẹ́rẹ́, tí ó kárí àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì inú Bíbélì nínú. Ní ojú ewé kọ̀ọ̀kan, ìwọ yóò rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tí ó ti da àwọn ènìyàn láàmú fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún. Fún àpẹẹrẹ, Kí ni ète Ọlọ́run fún ilẹ̀ ayé?” Ṣí i sí ẹ̀kọ́ 5, kí o sì ka àwọn ìbéèrè tí ó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ náà. Béèrè lọ́wọ́ onílé nípa èyí tí òun lọ́kàn ìfẹ́ sí jù lọ, lẹ́yìn náà kí o sì ka ìpínrọ̀ tí ó bá tan mọ́ ọn, kí o sì wo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó bá a mu. Ṣàlàyé pé àwọn ìdáhùn tí ó tẹ́ni lọ́rùn sí àwọn ìbéèrè yòó kù ni a lè rí lọ́nà rírọrùn bí èyí. Dábàá pé ìwọ yóò tún pa dà wá láti jíròrò ìbéèrè àti ìdáhùn míràn.

7 Tàbí ìwọ lè fẹ́ láti gbìyànjú ọ̀nà ìyọsíni tí a mú rọrùn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nípa sísọ pé:

◼ “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé nípa wíwulẹ̀ lo ìṣẹ́jú díẹ̀, ìwọ lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè pàtàkì kan nínú Bíbélì? Fún àpẹẹrẹ, . . .” Lẹ́yìn náà ka ìbéèrè kan tí ó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀kọ́ inú ìwé pẹlẹbẹ náà, ọ̀kan tí o ronú pé yóò fa ẹni náà mọ́ra. Kí o lè lóye díẹ̀ nínú àwọn ìbéèrè tí o lè lò, wo ìpínrọ̀ 15 àti 16 nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti March 1997, tí a fún lákọlé náà: “Máyà Le Láti Ṣe Ìpadàbẹ̀wò.”

8 Fífi ìdùnnú tẹ́wọ́ gba ìpèníjà náà láti ṣe ìpadàbẹ̀wò kí a sì darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jẹ́ apá kan jíjẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀” pẹ̀lú Ọlọ́run. (1 Kọ́r. 3:9) Bí a ti ń ṣiṣẹ́ kára láti mú ọkàn ìfẹ́ tí a bá rí dàgbà, tí a sì wá gbára lé Jèhófà láti mú kí àwọn nǹkan dàgbà, àwa yóò nírìírí ojúlówó ìtẹ́lọ́rùn tí iṣẹ́ mìíràn kò lè mú wá.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́