Àwọn Ìfilọ̀
◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní August: A lè lo èyíkéyìí nínú àwọn ìwé pẹlẹbẹ olójú ewé 32 tí ó tẹ̀ lé e yìí fún ₦15: Akoso Naa Ti Yoo Mu Paradise Wá, Gbádùn Iwalaaye lori Ilẹ Ayé Titilae!, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, Ki Ni Ète Igbesi-Aye? Bawo Ni Iwọ Ṣe Le Rí I?, Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú, àti Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi? September: Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. October: Àsansílẹ̀ owó fún yálà Jí! tàbí Ilé Ìṣọ́ tàbí fún ìwé ìròyìn méjèèjì. Bẹ̀rẹ̀ láti apá ìparí oṣù náà, a óò pín ìwé àṣàrò kúkúrú náà, Ìròyìn Ìjọba No. 35 káàkiri. November: Pípín ìwé àṣàrò kúkúrú náà Ìròyìn Ìjọba No. 35 káàkiri yóò máa bá a nìṣó. Àwọn ìjọ tí ó bá ti kárí ìpínlẹ̀ wọn nípa mímú ìwé àṣàrò kúkúrú náà Ìròyìn Ìjọba No. 35 dé ọ̀dọ̀ àwọn onílé ní ilé tàbí ibùgbé kọ̀ọ̀kan lè fi ìwé Ìmọ̀ lọni. ÀKÍYÈSÍ: Kí àwọn ìjọ tí yóò bá nílò àwọn ìwé ìgbétásì tí a mẹ́nu kàn lókè yí, yàtọ̀ sí Ìròyìn Ìjọba No. 35 tí a óò kó ránṣẹ́ sí gbogbo ìjọ, béèrè fún wọn lórí Literature Order Form (S-14) olóṣooṣù wọn ti oṣù tí ń bọ̀.
◼ Àwọn fọ́ọ̀mù S-1, S-14, àti S-20 tí ó pọ̀ tó ni a ń fi ránṣẹ́ sí ìjọ kọ̀ọ̀kan fún lílò ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 1998. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi òye lo àwọn fọ́ọ̀mù wọ̀nyí. A gbọ́dọ̀ lò wọ́n fún kìkì ète tí a ṣe wọ́n fún.
◼ Ìjọ kọ̀ọ̀kan yóò gba fọ́ọ̀mù Literature Inventory (S-18) mẹ́ta. Kí akọ̀wé ìjọ rí ìránṣẹ́ tí ń bójú tó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ní ìbẹ̀rẹ̀ August, kí wọ́n sì dá ọjọ́ tí wọn yóò ṣe ìṣírò ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó wà nínú ìjọ ní ìparí oṣù náà. Wọ́n gbọ́dọ̀ ka iye àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó wà lọ́wọ́ ní ti gidi, kí wọ́n sì kọ àròpọ̀ rẹ̀ sórí fọ́ọ̀mù Literature Inventory. Àròpọ̀ iye ìwé ìròyìn tí ó wà lọ́wọ́ ni a lè mọ̀ láti ọ̀dọ̀ ìránṣẹ́ tí ń bójú tó ìwé ìròyìn. Ẹ jọ̀wọ́, ẹ fi ẹ̀dà tí ó jẹ́ ojúlówó ránṣẹ́ sí Society, ó pẹ́ tán ní September 6. Ẹ tọ́jú ẹ̀dà kejì sínú fáìlì yín. Ẹ lè lo ẹ̀dà kẹta gẹ́gẹ́ bí èyí tí ẹ óò kọ́kọ́ kọ nǹkan sí. Kí akọ̀wé bójú tó ìṣírò náà, kí alábòójútó olùṣalága sì ṣàyẹ̀wò fọ́ọ̀mù tí a ti kọ ọ̀rọ̀ kún náà. Akọ̀wé àti alábòójútó olùṣalága yóò fọwọ́ sí fọ́ọ̀mù náà.
◼ A ń fi ẹ̀dà fọ́ọ̀mù Congregation Analysis Report S-10 méjì ránṣẹ́ sí ìjọ kọ̀ọ̀kan. Kí ẹ fara balẹ̀ dáradára láti kọ ọ̀rọ̀ kún fọ́ọ̀mù yí, kí ẹ sì fi ẹ̀dà tí ó jẹ́ ojúlówó ránṣẹ́ sí Society, ó pẹ́ tán September 6, 1997, pẹ̀lú ìròyìn August. Kí ẹ fi ẹ̀dà kejì sínú fáìlì yín.
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti August 21 sí 30, 1997, Society yóò máa ṣe ìṣírò ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó wà lọ́wọ́ ní Igieduma. Nítorí ìṣírò tí a fẹ́ ṣe yìí, a kò ní ṣiṣẹ́ lórí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ìjọ béèrè pé kí a fi ránṣẹ́ tàbí tí wọ́n fẹ́ wá kó ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyẹn.
◼ A ti ṣe àwọn àtúnṣe tí ó tẹ̀ lé e yìí sí “Àwọn Ọ̀gangan Ibi Àpéjọpọ̀ Àgbègbè ti 1997” tí ó wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti May 1997. Kí alábòójútó olùṣalága ìjọ èyíkéyìí tí a ti yí déètì tàbí ọ̀gangan ibi àpéjọpọ̀ wọn pa dà jọ̀wọ́ ṣètò pé kí a ṣe ìfilọ̀ ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tí ó tẹ̀ lé e lẹ́yìn tí a bá ti gba Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí.
November 7-9, 1997
IGWURUTA ALI 1 (Khana) RV-4B
December 5-7, 1997
Ọ̀TÀ 7 (Gẹ̀ẹ́sì, Èdè Àwọn Adití) WE-18 àwọn ìjọ láti A sí D
January 9-11, 1998
Ọ̀TÀ 9 (Gẹ̀ẹ́sì) WE-18 àwọn ìjọ láti E sí Z
January 16-18, 1998
IGWURUTA ALI 8 (Gòkánà) RV-4A