ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/97 ojú ìwé 5
  • Jọ̀wọ́ Fi Fún Alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jọ̀wọ́ Fi Fún Alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
km 8/97 ojú ìwé 5

Jọ̀wọ́ Fi Fún Alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́

Àtúnyẹ̀wò pípa ìwé dé lórí àkópọ̀ ẹ̀kọ́ tí a kárí nínú àwọn iṣẹ́ àyànfúnni Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọrun fún àwọn ọ̀sẹ̀ January 6 sí April 21, 1997. Lo abala tákàdá ọ̀tọ̀ láti fi kọ ìdáhùn sí púpọ̀ nínú àwọn ìbéèrè náà, bí ó bá ti lè ṣeé ṣe fún ọ tó, ní ìwọ̀n àkókò tí a yàn.

[Àkíyèsí: Lákòókò àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀, Bibeli nìkan ni a lè lò láti dáhùn ìbéèrè èyíkéyìí. Àwọn ìtọ́kasí tí ó tẹ̀ lé àwọn ìbéèrè wà fún ìwádìí fúnra rẹ. Nọ́ḿbà ojú ìwé àti ìpínrọ̀ lè má fara hàn nínú gbogbo àwọn ìtọ́ka tí a ṣe sí Ilé Ìṣọ́.]

Dáhùn Òtítọ́ tàbí Èké sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tí ó tẹ̀ lé e yìí:

1. Ìyọ́nú tí Jésù ní, tí a ṣàpèjúwe ní Máàkù 1:41, pèsè àpèjúwe tí ń ru ìmọ̀lára sókè nípa àníyàn tí Jèhófà ní fún àwọn ènìyàn. [3, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w96-YR 3/1 ojú ìwé 5.]

2. Ìṣípayá 7:16 fi hàn pé ayé kì yóò ṣenúnibíni sí àwọn mẹ́ńbà ogunlọ́gọ̀ ńlá náà. [5, uw-YR ojú ìwé 108 ìpínrọ̀ 11]

3. Ìbéèrè Jòhánù Olùbatisí tí ó wà ní Lúùkù 7:19 fi hàn pé òun kò ní ìgbàgbọ́. [14, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w87-YR 1/1 ojú ìwé 14.]

4. Nígbà Àjọ Ìrékọjá tí Jésù ṣe kẹ́yìn pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, Pétérù nìkan ni ó sọ fún un pé: “Dájúdájú èmi kì yóò sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ.” [1, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀]

5. Kò sí ẹ̀rí tí ó bá Bíbélì mu tí ń fi hàn pé àpọ́sítélì Pétérù gbéyàwó. [13, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀]

6. A rí àwọn ohun tí yóò máa ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ ìkẹyìn kìkì nínú Mátíù 24, Máàkù 13, àti Lúùkù 21. [12, kl-YR ojú ìwé 102 àpótí]

7. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé àwọn Júù ni Máàkù kọ Ìhìn Rere rẹ̀ fún ní pàtàkì. [3, w89-YR 10/15 ojú ìwé 30]

8. Nígbà tí Jésù sọ fún àwọn Farisí pé Ìjọba Ọlọ́run wà láàárín wọn, ó ń tọ́ka sí ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba lọ́la. (Lúùkù 17:21) [6, kl-YR ojú ìwé 91 ìpínrọ̀ 6]

9. Kò sí àlàyé tí ó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ nípa ìdí tí ìwé Lúùkù fi ní àkànlò èdè tí ó ní onírúurú ọ̀rọ̀ ju bí àpapọ̀ Ìhìn Rere mẹ́ta yòó kù ti ní in lọ. [11, w89-YR 11/15 ojú ìwé 24]

10. Kò sí àwọn ìtọ́kasí nínú Bíbélì nípa àwọn ànímọ́ tí ogunlọ́gọ̀ ńlá gbọ́dọ̀ fi hàn kí wọ́n baà lè la Amágẹ́dọ́nì já. [1, uw-YR ojú ìwé 105 ìpínrọ̀ 5]

Dáhùn àwọn ìbéèrè tí ó tẹ̀ lé e yìí:

11. Lábẹ́ òfin àwọn Júù, kí ni ó ṣàìtọ́ nínú ìgbéyàwó Hẹ́rọ́dù Áńtípà àti Hẹrodíà? (Máàkù 6:18) [5, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀]

12. Kí ni ó ń dí àwọn kan lọ́wọ́ láti gba ìmọ̀ràn? [15, uw-YR ojú ìwé 127 ìpínrọ̀ 4]

13. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo nínú Orin Dáfídì àti Hébérù ni ó fi hàn pé Jésù kò bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso lọ́gán lẹ́yìn tí ó gòkè re ọ̀run? [9, kl-YR ojú ìwé 96 ìpínrọ̀ 15]

14. Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tí ó sọ pé: “Ẹ ní iyọ̀ nínú ara yín, kí ẹ sì pa àlàáfíà mọ́ láàárín ara yín lẹ́nì kíní kejì”? (Máàkù 9:50) [7, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w85-YR 11/15 ojú ìwé 24 ìpínrọ̀ 12.]

15. Ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n tí ó níye lórí wo ni a lè rí kọ́ láti inú bí Jésù ṣe hùwà pa dà sí ìtọrẹ tí opó náà ṣe? (Máàkù 12:42-44) [8, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w87-YR 12/1 ojú ìwé 29 ìpínrọ̀ 7 sí ojú ìwé 30 ìpínrọ̀ 1.]

16. Báwo ni ó ṣe ṣeé ṣe fún Máàkù láti rí kúlẹ̀kúlẹ̀ ìsọfúnni fún àkọsílẹ̀ Ìhìn Rere rẹ̀? [3, w89-YR 10/15 ojú ìwé 30]

17. Nígbà tí a bá ṣe ìfiwéra Mátíù 6:9, 10 àti Lúùkù 11:2-4, èé ṣe tí a fi lè dé ìparí èrò pé kì í ṣe pé kí a máa sọ àwọn ọ̀rọ̀ àdúrà náà bí wọ́n ṣe rí gan-an? [16, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w90-YR 5/15 ojú ìwé 16 ìpínrọ̀ 6.]

18. Lọ́nà wo ni a gbà fún ìgbọ́kànlé wa nínú ìṣeégbáralé Bíbélì lókun nígbà tí a ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi Lúùkù 3:1, 2? [12, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀]

19. Ní ìbámu pẹ̀lú Ìṣípayá 7:14, kí ni ìyọrísí fífọ aṣọ ìgúnwà ẹni nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà? [4, uw-YR ojú ìwé 106 ìpínrọ̀ 6, 7]

20. Níwọ̀n bí a ti mọ̀ pé Jésù kò fìgbà kan rí ṣàìní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, èé ṣe tí òun fi kígbe pé: “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èé ṣe tí ìwọ fi ṣá mi tì?” (Máàkù 15:34) [10, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w87-YR 6/15 ojú ìwé 31.]

Pèsè ọ̀rọ̀ tàbí àpólà ọ̀rọ̀ tí a nílò láti parí ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn gbólóhùn tí ó tẹ̀ lé e yìí:

21. Búrẹ́dì àti wáìnì tí a ń lò ní Ìṣe Ìrántí jẹ́ --------------------- lásán, tí búrẹ́dì náà dúró fún ---------------------, tí wáìnì náà sì dúró fún ---------------------. [8, uw-YR ojú ìwé 115 ìpínrọ̀ 13]

22. Nígbà tí a bá gbé ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ ní ti gidi yẹ̀ wò, ó dà bí ẹni pé ó hàn gbangba pé ní gbogbogbòò ìpè ti ọ̀run ni a ti parí ní nǹkan bí ọdún ---------------------, nígbà tí a lóye ní kedere nípa ìrètí orí ilẹ̀ ayé tí ogunlọ́gọ̀ ńlá ní. [6, uw-YR ojú ìwé 111 ìpínrọ̀ 6]

23. Nígbà tí Jòhánù Olùbatisí bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù, --------------------- ni gómìnà Jùdíà, --------------------- sì ni olùṣàkóso àgbègbè Gálílì. [12, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; Wo Lúùkù 3:1.]

24. --------------------- ni ẹ̀mí tí ń bá ipá ìsúnniṣe èrò inú àti ọkàn àyà àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọkùnrin Ọlọ́run ní tòótọ́ jẹ́rìí. [7, uw-YR ojú ìwé 113 ìpínrọ̀ 9]

25. Gẹ́gẹ́ bí a ti fi hàn ní Lúùkù 10:16, nígbà tí a bá fi ìmọrírì tẹ́wọ́ gba àwọn ìpèsè tẹ̀mí tí ó ń wá nípasẹ̀ --------------------- àti Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso, a ń bọ̀wọ̀ fún ---------------------. [14, uw-YR ojú ìwé 123 ìpínrọ̀ 13]

Mú ìdáhùn tí ó tọ̀nà nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn gbólóhùn tí ó tẹ̀ lé e yìí:

26. Àwọn ẹni mímọ́ tí a tọ́ka sí ní Mátíù 27:52 jẹ́ (àwọn tí a jí dìde fún ìgbà díẹ̀ nínú ẹran ara; àwọn ara òkú aláìlẹ́mìí ní ti gidi tí ìsẹ̀lẹ̀ sọ síta láti inú ibojì wọn; àwọn tí a gbé dìde sí ìyè ti ọ̀run ṣáájú kí a tó gbé Jésù dìde). [2, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w90-YR 9/1 ojú ìwé 7.]

27. Ìjọba tí Jésù wàásù nípa rẹ̀ jẹ́ (igbá kejì, olórí) fún ipò ọba aláṣẹ àgbáyé ti Ọlọ́run. [5, kl-YR ojú ìwé 91 ìpínrọ̀ 4]

28. Ẹ̀mí mímọ́ fìdí ìyànsípò “olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n inú ẹrú” múlẹ̀ ní ọdún (33 Sànmánì Tiwa; 1918; 1919). (Mát. 24:45) [12, uw-YR ojú ìwé 119 ìpínrọ̀ 6]

29. Ìlànà kan tí ó yẹ kí gbogbo Kristẹni, pàápàá àwọn tí ń bẹ ní ipò àbójútó nínú ètò àjọ Ọlọ́run tẹ̀ lé ni: “Ẹni tí ó bá mú ara rẹ̀ hùwà bí (onígbèéraga; ẹni pàtàkì; ẹni tí ó kéré jù) láàárín gbogbo yín ni ẹni ńlá.” (Lúùkù 9:48) [13, uw-YR ojú ìwé 122 ìpínrọ̀ 12]

30. Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ ní (Mátíù 10; Mátíù 24; Lúùkù 21), Jésù fún àwọn tí ó rán jáde láti lọ wàásù ní ìtọ́ni pàtó lórí iṣẹ́ ìsìn. [2, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀]

So àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí ó tẹ̀ lé e yìí mọ́ àwọn gbólóhùn tí a tò lẹ́sẹẹsẹ sí ìsàlẹ̀ yìí:

Òwe 4:13; Dán. 7:9, 10, 13, 14; Máàk. 7:20-23; 13:10; Lúùk. 8:31

31. A gbọ́dọ̀ wà lójúfò láti mọ agbára ìdarí èyíkéyìí tí ó jẹ́ ti aláìwà-bí-Ọlọ́run tàbí tí ń sọni dìbàjẹ́ tí ó lè wá sínú èrò inú wa àti ọkàn àyà wa, kí a sì mú un kúrò kí ó tó ta gbòǹgbò. [Máàk. 7:20-23] [6, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w89-YR 11/1 ojú ìwé 14 ìpínrọ̀ 16.]

32. Àwọn ẹ̀mí èṣù yóò dara pọ̀ mọ́ Sátánì nínú ipò àìlètapútú nígbà “ẹgbẹ̀rún ọdún náà.” (Ìṣí 20:3) [Lúùk. 8:31] [15, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀]

33. A nílò ẹ̀mí ìjẹ́kánjúkánjú kí a baà lè ṣàṣeparí iṣẹ́ ìjẹ́rìí kárí ayé náà láàárín àkókò tí ó láàlà. [Máàk. 13:10] [9, Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀; wo w95-YR 10/1 ojú ìwé 27.]

34. Títẹ́wọ́gba ìmọ̀ràn lè dáàbò boni kúrò nínú sísọ àti ṣíṣe àwọn ohun tí ó lè fa àbámọ̀. [Òwe 4:13] [16, uw-YR ojú ìwé 128 ìpínrọ̀ 6]

35. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò lè rí àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí, Ọ̀rọ̀ Jèhófà fún wa ní ìwòfìrí nípa ètò àjọ rẹ̀ ti ọ̀run tí a kò lè fojú rí àti díẹ̀ nínú àwọn ìgbòkègbodò ètò àjọ náà tí ń nípa lórí àwọn olùjọsìn rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. [Dán. 7:9, 10, 13, 14] [9, uw-YR ojú ìwé 117 ìpínrọ̀ 1]

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́