Ìmúgbòòrò Tí Ń Bá A Nìṣó Ń Mú Àìní fún Àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba Pọ̀ Sí I
1 Tipẹ́tipẹ́ ni wòlíì Jèhófà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé “àwọn ohun fífani-lọ́kànmọ́ra tí ń bẹ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè yóò wọlé wá.” (Hág. 2:7, NW) A ń rí ògìdìgbó nísinsìnyí tí wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tí wọ́n sì ń di olùjọsìn Jèhófà. Ẹ wo bí ó ti múni láyọ̀ tó láti rí 11,624 tí a batisí ní ọ̀wọ́ àwọn àpéjọpọ̀ àgbègbè ti 1996 ní Nàìjíríà nìkan! Láti máa bá a nìṣó ní ríran gbogbo àwọn ẹni tuntun wọ̀nyí lọ́wọ́, a ní láti ‘fi ọkàn àyà wa sí àwọn ọ̀nà wa’ láti ri dájú pé a ń ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ Ọlọ́run lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó. (Hág. 1:5) Ọ̀nà pàtàkì kan tí a lè gbà ṣe èyí jẹ́ nípa ṣíṣèrànwọ́ láti pèsè àwọn ilé ìjọsìn tí ó bójú mu fún ogunlọ́gọ̀ àwọn ẹni tuntun olùyin Jèhófà.
2 Owó Àkànlò Society fún Gbọ̀ngàn Ìjọba ti wà lẹ́nu iṣẹ́ fún ọdún méje báyìí, ó sì ti mú kí ó ṣeé ṣe fún ìjọ 105 láti ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun tàbí èyí tí a tún ṣe. Ìdáhùnpadà àwọn akéde sí fífi owó ṣètìlẹ́yìn fún owó àkànlò yí ti tẹ́ni lọ́rùn ní tòótọ́. Owó tí a yá àwọn ìjọ ni a ń san pa dà tí ó fi jẹ́ pé gbogbo owó tí a dá ni a ń lò lọ, lọ́dọọdún, láti kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun.
3 Ìrànwọ́ Àwọn Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn: Àwọn Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn 25 ní Nàìjíríà ń ṣèrànwọ́ fún àwọn alàgbà tí ń lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Wọ́n ń ṣèrànwọ́ láti pinnu àìní fún Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun tàbí láti tún gbọ̀ngàn tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ ṣe, wọ́n sì ń pèsè ìrànwọ́ láti ìta bí a bá ti nílò rẹ̀ tó ṣáájú kí a tó ra ilẹ̀ títí di ìgbà tí a bá parí Gbọ̀ngàn Ìjọba náà. Ìjọ kọ̀ọ̀kan ni a yàn sábẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìgbìmọ̀ wọ̀nyí.
4 Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn òṣìṣẹ́ olùmúratán ti yọ̀ǹda ara wọn láti nípìn-ín nínú iṣẹ́ títún àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe àti kíkọ́ tuntun. Àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni wọ̀nyí, tí ó ní ọ̀pọ̀ àwọn amọṣẹ́dunjú àti oníṣòwò nínú, ti yọ̀ǹda àkókò àti ìsapá wọn fàlàlà nínú irú àwọn ọ̀ràn bíi ríra ilẹ̀, yíyàwòrán ilé, àti ṣíṣe àkọsílẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ àwọn ohun èlò ìkọ́lé tí a óò rà. Wọ́n tún ń ṣèrànwọ́ ní ríra ojúlówó ohun èlò ìkọ́lé ní owó pọ́ọ́kú, wọ́n ń parí iṣẹ́ àkọ́kọ́ lórí ilẹ̀ náà, wọ́n sì ń bójú tó iṣẹ́ ìkọ́lé náà gan-an. Irú fífúnni ní ohun àmúṣọrọ̀ wọn tí a yà sí mímọ́ lọ́nà ọlọ́làwọ́ bẹ́ẹ̀ nítorí ire Ìjọba yẹ fún ìyìn gidigidi, ó sì ń mú ìbùkún jìngbìnnì wá láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.—Òwe 11:25.
5 Àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ kàn sí Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn tí ó wà ní àgbègbè wọn nígbà tí ìjọ wọn bá kọ́kọ́ ronú nípa títún Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ó ti wà tẹ́lẹ̀ ṣe tàbí bí wọ́n bá fẹ́ kọ́ tuntun. Èé ṣe? Àwọn ìgbìmọ̀ ẹlẹ́kùnjẹkùn ní àwọn ìlànà atọ́nisọ́nà tí ó lè ran àwọn ìjọ lọ́wọ́ nínú àgbéyẹ̀wò wọn àkọ́kọ́. Yíyan ibi tí a óò kọ́ ilé sí ń mú ọ̀pọ̀ kókó abájọ lọ́wọ́ ní àfikún sí iye tí a óò ra ilẹ̀ náà. Àwọn nǹkan mìíràn lè mú kí iye tí a óò fi kọ́ ilé náà gan-an pọ̀ sí i gidigidi, irú bíi ṣíṣe iṣẹ́ púpọ̀ lórí ibi tí a óò kọ́ ilé sí, kíkó àwọn nǹkan eléwu tàbí nǹkan olóró kúrò, tàbí àwọn ọ̀ràn òfin tí ó lè kóni sí yọ́ọ́yọ́ọ́. Bí ìjọ kan bá nílò ìrànlọ́wọ́ owó láti ọ̀dọ̀ Society, àwọn ìgbìmọ̀ ẹlẹ́kùnjẹkùn ní àwọn ẹ̀dà fọ́ọ̀mù Kingdom Hall Loan Survey lọ́wọ́, wọ́n sì lè ran àwọn alàgbà ìjọ lọ́wọ́ láti kọ ọ̀rọ̀ kún wọn.
6 Society ti fún àwọn Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn ní àwọn àwòrán ilẹ̀ ilé tí a dámọ̀ràn fún àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba. Kí ẹ to yan àwòrán ilé kan, àwọn alàgbà ìjọ ní láti kàn sí ìgbìmọ̀ ẹlẹ́kùnjẹkùn, kí wọ́n sì jíròrò gbogbo ìgbékalẹ̀ ilé náà látòkèdélẹ̀, ní lílo àwọn àwòrán ilé tí Society pèsè gẹ́gẹ́ bí ìtọ́sọ́nà. Kì í ṣe kìkì pé èyí yóò dín owó ìkọ́lé kù nìkan ni, ṣùgbọ́n yóò tún ran ìjọ lọ́wọ́ láti yan ilé kan tí ó jẹ́ alábọ́ọ́dé síbẹ̀ tí yóò wúlò tí yóò sì ṣe wẹ́kú fún ọ̀nà ìgbàkọ́lé kíákíá.
7 Àkọsílẹ̀ ìnáwó tí ó péye tí ó sì ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ ni a gbọ́dọ̀ pa mọ́. Àwọn arákùnrin tí wọ́n ní ìmọ̀ ti yọ̀ǹda ara wọn láti bá àwọn igbìmọ̀ ẹlẹ́kùnjẹkùn ṣiṣẹ́ kí wọ́n lè ran àwọn ìjọ lọ́wọ́ láti gbé ètò àkáǹtì tí wọ́n nílò kalẹ̀ àti pípa á mọ́. Èyí ń ṣèrànwọ́ gidigidi, níwọ̀n bí àwọn alàgbà àdúgbò kì í ti í sábà ń ṣiṣẹ́ lórí irú àwọn àkọsílẹ̀ ìnáwó fún kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba bí èyí nígbà gbogbo bí àwọn arákùnrin onírìírí tí a sì ti dá lẹ́kọ̀ọ́ dáradára wọ̀nyí ti ń ṣe. Nígbà tí iṣẹ́ náà bá parí, ìgbìmọ̀ ẹlẹ́kùnjẹkùn gbọ́dọ̀ gba ẹ̀dà gbogbo àkọsílẹ̀ àkáǹtì fún iṣẹ́ náà.
8 Ní àwọn orílẹ̀-èdè míràn, àwọn ará ti mú ọ̀nà ìgbàkọ́lé kíákíá jáde láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun tán láàárín ọjọ́ díẹ̀ péré. Nàìjíríà ńkọ́? Ó hàn gbangba pé Gbọ̀ngàn Ìjọba tí a ń kọ́ kò tó rárá fún iye àwọn ìjọ tí ń pọ̀ sí i ṣáá ní Nàìjíríà. Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ni a sábà máa ń wò bí iṣẹ́ tí kò lópin. Ní àárín 1996, Society bẹ̀rẹ̀ ìwéwèé láti bẹ̀rẹ̀ sí í lo ọ̀nà ìgbàkọ́lé kíákíá. Lákọ̀ọ́kọ́, ọ̀pọ̀ ń ṣiyè méjì nípa bóyá yóò ṣeé ṣe ní àdúgbò wa níwọ̀n bí àwọn ohun èlò ìkọ́lé tí ó wà kò ti jẹ́ bákan náà pẹ̀lú èyí tí a ń rí ní òkè òkun. Ṣùgbọ́n, pẹ̀lú ìgbọ́kànlé kíkún nínú Jèhófà, iṣẹ́ náà tẹ̀ síwájú. Gbọ̀ngàn Ìjọba àkọ́kọ́ tí a kọ́ lọ́nà yí ní Nàìjíríà ni a parí ní abúlé Ewossa, kìlómítà 51 sí Bẹ́tẹ́lì ní Igieduma. Gbọ̀ngàn Ìjọba náà ní àyè fún àga tí 150 ènìyàn lè jókòó sí.
9 Báwo ni ó ṣe ṣẹlẹ̀? Àwọn arákùnrin onírìírí ni a lò láti yàwòrán ilé náà, láti ṣírò iye tí yóò náni, àti láti ra àwọn ohun èlò ìkọ́lé tí a nílò. A ṣètò àwọn òṣìṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú iṣẹ́ ọwọ́ tí wọ́n mọ̀. Ìjọ náà ni a sọ fún nípa àwọn ohun èlò tí wọ́n nílò àti iṣẹ́ tí ó pọn dandan pé kí wọ́n ṣe ṣáájú ọjọ́ iṣẹ́ ìkọ́lé náà gan-an. Irú iṣẹ́ tí a kọ́kọ́ ṣe sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ gba nǹkan bí oṣù mẹ́fà. Iṣẹ́ ìkọ́lé kíákíá náà gan-an gba ọjọ́ 15. Àwọn ohun èlò ìkọ́lé tí a ń rí ní àdúgbò ni a lò, èyí tí ó ní nínú bíríkì ìkọ́lé tí a sun, ọ̀dà fún ògiri inú, páànù ìbolé, àti àwọn igi ìrólé fún òrùlé.
10 Láàárín ọjọ́ mẹ́ta, gbogbo ògiri Gbọ̀ngàn Ìjọba náà àti ti ṣáláńgá ni a parí. Ní ọjọ́ mẹ́ta tí ó tẹ̀ lé e, rírẹ́ ògiri inú àwọn ilé méjèèjì ni a parí. ẹ́ ògiri ìta tàbí kí a fi ọ̀dà kùn ún níwọ̀n bí ó ti jẹ́ bíríkì pupa.) Kíkan òrùlé gba ọjọ́ kan péré. Bíbo àjà ilé, ṣíṣàgbékalẹ̀ àwọn ohun tí ń lo iná mànàmáná, gbígbin òdòdó, kíkun ògiri lọ́dà, síso àwọn ilẹ̀kùn àti fèrèsé, àti títo àwọn àga ni a parí ní ọjọ́ 15. Gbọ̀ngàn Ìjọba náà ni a yà sí mímọ́ ní January 25, 1997.
11 Orí Àwọn Òǹwòran Wú: Bí ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ṣe ń ṣiṣẹ́ lọ́nà híhàn gbangba lórí àwọn ará tí ń ṣiṣẹ́ lórí àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba ti jẹ́ ẹ̀rí fún àwọn ẹlòmíràn. Ní Ewossa, ọ̀dọ́kùnrin kan tí ó wá ṣèbẹ̀wò sí abúlé náà rí àwọn ará tí wọ́n ń ṣe iṣẹ́ àṣesílẹ̀ fún ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé e. Nígbà tí ó pa dà wá ní ọ̀sẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e, àwọn ìbátan rẹ̀ sọ pé: “Àwọn ènìyàn Jèhófà ti parí ilé wọn.” Nígbà tí ó ń lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ ìbátan rẹ̀ kan, ó gba òpópónà tí Gbọ̀ngàn Ìjọba náà wà. Ó dúró, ó sì sọ pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tí ó wà láàárín àwọn ènìyàn Jèhófà wọ̀nyí púpọ̀. Ì bá wù mí ká ní mo lè dara pọ̀ mọ́ wọn nínú iṣẹ́ náà.”
12 Onojie (baálẹ̀) abúlé náà sọ pé: “Ohun ìyangàn nìyí fún abúlé wa. Mo nífẹ̀ẹ́ ohun tí ẹ̀yin ènìyàn wọ̀nyí ń fi ìṣọ̀kan yín ṣe. Ẹ máa bá a lọ bẹ́ẹ̀. Láti ìsinsìnyí lọ èmi yóò máa sọ fún àwọn ènìyàn tí ó nífẹ̀ẹ́ ohun rere láti lọ wo ohun tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe.”
13 Tọmọdétàgbà ni wọ́n kópa nínú iṣẹ́ náà. Ọkùnrin arúgbó ẹni 70 ọdún kan tí ó wà níbẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ tí a fi ṣe iṣẹ́ náà ni àwọn ìbátan rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ alátakò fún nímọ̀ràn pé kí ó dẹ́kun wíwá sí ibi iṣẹ́ ìkọ́lé náà. Wọ́n sọ pé: “Bí o kò bá dẹ́kun lílọ, ohun búburú kan yóò ṣẹlẹ̀ sí ọ.” Ọkùnrin náà fèsì pé: “Láti ìgbà tí mo ti ń lọ sí ìpàdé wọn, ohun búburú kankan kò ṣẹlẹ̀ sí mi. Ohun tí a ń ṣe àṣeparí rẹ̀ nísinsìnyí ń mú mi láyọ̀ pẹ̀lú bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò lè ṣe púpọ̀.” Nígbà tí àwọn ìbátan náà fúnra wọn ṣèbẹ̀wò sí ibi ìkọ́lé náà tí wọ́n sì rí i pé ilé náà ni a ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kọ́ tán, wọn kò dààmú rẹ̀ mọ́.
14 Ìdàníyàn wa ni pé kí a lo irú ọ̀nà ìgbàkọ́lé yìí ní gbogbo apá orílẹ̀-èdè yí. A lo iṣẹ́ ìkọ́lé ti Ewossa láti kọ́ àwọn Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn mẹ́ta àti àwọn òṣìṣẹ́ wọn tí ó lóye iṣẹ́ lẹ́kọ̀ọ́. A ti mú wọn gbára dì nísinsìnyí láti ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ láìsí pé yóò pọn dandan kí Society lọ́wọ́ nínú rẹ̀. Pẹ̀lú ìwéwèé tí ó dára, irú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ ni a óò mú nasẹ̀ dé ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn tí ó ba yọ̀ǹda ara wọn. Àwọn ìjọ tí ó ba ń ronú nípa kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn, tàbí títún un ṣe lọ́jọ́ iwájú, tí wọ́n sì fẹ́ lo irú ọ̀nà ìgbàkọ́lé yìí lè sọ fún Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn tí ó wà ní àgbègbè wọn. Ìsọfúnni nípa ohun tí a béèrè fún ni a ti fún wọn. Ẹ tún gbọ́dọ̀ fi ìwé ìbéèrè ránṣẹ́ sí Society bí ẹ bá fẹ́ lo ọ̀nà ìgbàkọ́lé kíákíá, níwọ̀n bí kì í ti í ṣe gbogbo Gbọ̀ngàn Ìjọba ni a ń kọ́ lọ́nà ìgbàkọ́lé kíákíá.
15 A Nílò Àwọn Olùyọ̀ǹda Ara Ẹni Púpọ̀ Sí I: Àwọn ìgbìmọ̀ ẹlẹ́kùnjẹkùn sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni púpọ̀ sí i ni a nílò. Èyí jẹ́ iṣẹ́ ìsìn tí ó pọn dandan ní ìtìlẹ́yìn fún ire Ìjọba. (1 Kọ́r. 15:58) A nílò àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n lóye iṣẹ́, a sì tún nílò àwọn arákùnrin tí wọ́n dàgbà dénú tí wọ́n ní ìtóótun nípa tẹ̀mí, bí wọn kò bá tilẹ̀ ní ìmọ̀ iṣẹ́ ìkọ́lé. Bí o bá tóótun, o ha lè ṣe àwọn àtúnṣebọ́sípò mélòó kan kí o baà lè wà ní ipò láti yọ̀ǹda ara rẹ bí? (Aísá. 6:8) Fún àpẹẹrẹ, ó lè ṣeé ṣe fún àwọn alàgbà tàbí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan láti ṣèrànwọ́ ní kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ní òpin ọ̀sẹ̀ kan tàbí méjì lóṣooṣù. Wọ́n lè gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní onírúurú ẹ̀ka, àní nínú àwọn ìgbòkègbodò ti kò ní í ṣe pẹ̀lú ilé kíkọ́ pàápàá. Èyí yóò jẹ́ ìrànwọ́ fún àwọn òṣìṣẹ́kára arákùnrin tí ń bójú tó iṣẹ́ wọ̀nyí.
16 Àwọn Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn àti ìgbìmọ̀ ìkọ́lé ní àdúgbò máa ń ṣètò àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tí ó fi jẹ́ pé wọ́n ń wà ní ibi ìkọ́lé náà ní kìkì ìgbà tí a bá nílò ìrànlọ́wọ́ wọn. Àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni wọ̀nyí ń pa dà sí ìjọ àdúgbò wọn àti sọ́dọ̀ ìdílé wọn ní kíákíá bí ó bá ti lè yá tó, tí wọn kì í sì í kùnà láti lọ sí àwọn ìpàdé tàbí ní lílọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn pápá láìṣe pé ó pọn dandan. Àwọn tí wọ́n ń wà ní ilẹ̀ ibi tí a ti ń kọ́lé máa ń jẹ́ (1) àwọn olùyọ̀ǹda ara ẹni tí a fọwọ́ sí, tí àwọn olórí ẹ̀ka iṣẹ́ yàn ní pàtó láti wà níbẹ̀ àti (2) àwọn tí ó wá láti àwọn ìjọ tí ó wà ní àgbègbè ibi tí a ti ń kọ́ gbọ̀ngàn náà tí wọ́n para pọ̀ jẹ́ àwùjọ òṣìṣẹ́ tí kò lóye iṣẹ́. Àwọn yòó kù ni a fún níṣìírí láti ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìsìn pápá àti ìpàdé ní ìjọ tiwọn.
17 Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn tí ń nípìn-ín nínú kíkọ́ àwọn ilé fún ìjọsìn Jèhófà ti rí i pé Orin Dáfídì 127:1 jẹ́ òtítọ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òṣìṣẹ́ olóye ń yọ̀ǹda àkókò àti ìsapá wọn fún kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tí ó dára rèǹtèrente ní kíákíá, ìbùkún Jèhófà ni ó ń mú àṣeyọrísírere dájú. A ṣì nílò Gbọ̀ngàn Ìjọba púpọ̀ sí i. Láti ìgbà tí ó ti bẹ̀rẹ̀, ó ti ṣeé ṣe fún Owó Àkànlò Society fún Gbọ̀ngàn Ìjọba láti ran ọ̀pọ̀ àwọn ìjọ lọ́wọ́ ní ṣíṣe iṣẹ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn. Ǹjẹ́ kí gbogbo wa máa bá a lọ láti yọ̀ǹda àkókò àti “ohun ìní” wa fàlàlà bí a ṣe ń fojú sọ́nà pé kí Jèhófà bù kún àwọn ìsapá wa.—Òwe 3:9.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Gbọ̀ngàn Ìjọba Tuntun náà ní Ewossa
Ọjọ́ 9 iṣẹ́ ìkọ́lé
Gbọ̀ngàn Ìjọba tí a ti parí ní ọjọ́ 15