Jàǹfààní Dídára Jù Lọ ní Ilé Ẹ̀kọ́
1 Àkókò náà nìyí nínú ọdún tí ọ̀pọ̀ nínú àwọn èwe máa ń béèrè pé: “Ó ha yẹ kí n ti pa dà sí ilé ẹ̀kọ́ bí?” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìpèníjà àti àníyàn mélòó kan ń bẹ tí ó so pọ̀ mọ́ pípadà sí ilé ẹ̀kọ́, àǹfààní púpọ̀ ní ń bẹ pẹ̀lú tí àwọn ọ̀dọ́ tí ń sakun láti jàǹfààní dídára jù lọ nínú ẹ̀kọ́ wọn yóò jèrè.
2 Níní ìwọ̀n ẹ̀kọ́ ṣíṣe kókó lè fi kún ìtẹ̀síwájú ẹni nípa tẹ̀mí. Ohun tí ẹnì kan bá ṣe ní ìgbà èwe rẹ̀ yóò nípa lórí ohun tí yóò lè ṣàṣeparí nígbà tí ó bá di àgbà. Àní nínú ọ̀ràn ilé ẹ̀kọ́ pàápàá, “ohun yòó wù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni òun yóò ká pẹ̀lú.” (Gál. 6:7) Àwọn èwe tí wọ́n fi taápọntaápọn kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ wọn ní ilé ẹ̀kọ́ lè jèrè òye tí yóò mú kí wọ́n túbọ̀ wúlò fún Jèhófà.
3 Ìrònú àfẹ̀sọ̀ṣe tẹ́lẹ̀ ni a béèrè bí ẹnì kan yóò bá yan àwọn ẹ̀kọ́ tí ó tọ́ ní ilé ẹ̀kọ́. Kí àwọn òbí ran ọmọ wọn lọ́wọ́ láti yan èyí tí ó fúnni ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí ó gbéṣẹ́ jù lọ, kí ọwọ́ wọn baà lè tẹ àwọn góńgó tẹ̀mí nínú ìgbésí ayé. Nípa mímú òye wọn pọ̀ sí i, àwọn èwe yóò ní àǹfààní láti lè gbọ́ bùkátà ara wọn nínú iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà. Ìwọ̀n ẹ̀kọ́ ṣíṣe kókó tí wọ́n bá ní yẹ kí ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fi ìyìn fún Jèhófà níbi yòó wù tí wọ́n bá ti ń sìn.
4 Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ gbìyànjú láti jàǹfààní dídára jù lọ nínú àwọn ọdún tí ẹ óò lò ní ilé ẹ̀kọ́. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ẹ pọkàn pọ̀ sórí gbígbé ìgbésí ayé onítẹ̀ẹ́lọ́rùn tí ó sì nítumọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀, dípò pípọkànpọ̀ sórí ìlépa iṣẹ́ ayé. Sakun láti lo ìgbésí ayé rẹ̀ ní ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà. Nípa báyìí, ìwọ yóò mú ọ̀nà rẹ yọrí sí rere, sí ìyìn Jèhófà.—Orin Dá. 1:3.