Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Ṣé Kí N Fi Iléèwé Sílẹ̀?
Ibo lo rò pé ó yẹ kó o kàwé dé?
․․․․․
Ibo làwọn òbí rẹ fẹ́ kó o kàwé dé?
․․․․․
ǸJẸ́ ìdáhùn rẹ sí ìbéèrè méjèèjì yìí bára mu? Ká tiẹ̀ gbà pé ìdáhùn rẹ bára mu tó sì jẹ́ pé o ṣì ń lọ sí iléèwé, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o fi iléèwé sílẹ̀ nígbà míì. Ǹjẹ́ ó máa ń ṣe ẹ́ bíi tàwọn tó sọ ọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé e yìí?
● “Àwọn ìgbà míì wà tó máa ń rẹ̀ mí débi pé mi kì í fẹ́ dìde lórí bẹ́ẹ̀dì láàárọ̀. Mo máa ń ronú pé, ‘Kí nìdí tí mo ṣe fẹ́ lọ síléèwé láti lọ kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tí kò ní ṣe mí láǹfààní kankan?’”—Rachel.
● “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ọ̀rọ̀ iléèwé máa ń sú mi, ó máa ń ṣe mí bíi pé kí n fi iléèwé silẹ̀ kí n sì lọ wá iṣẹ́ kan ṣe. Mo ronú pé iléèwé kò ṣe mí láǹfààní kankan, ó tẹ́ mi lọ́rùn kí n máa fi àkókò mi ṣe nǹkan táá máa mówó wọlé fún mi.”—John.
● “Ó máa ń tó wákàtí mẹ́rin tí mo fi máa ń ṣe iṣẹ́ àṣetiléwá ní alaalẹ́! Iṣẹ́ àṣetiléwá àtàwọn iṣẹ́ míì máa ń wọ̀ mí lọ́rùn bí nǹkan míì, àwọn iṣẹ́ ọ̀hún kì í sì í tán, mi ò rò pé agbára mi gbé e mọ́, ó ń ṣe mí bíi pé kí n fi iléèwé sílẹ̀.”—Cindy.
● “Nígbà kan, àwọn kan halẹ̀ mọ́ wa pé àwọn máa ju bọ́ǹbù síléèwé wa, àwọn mẹ́ta gbìyànjú láti gbẹ̀mí ara wọn, ẹnì kan pàpà gbẹ̀mí ara rẹ̀, àwọn ọmọ ìta ò sì yéé hùwà ipá. Wàhálà yẹn pọ̀ débi pé, ó máa ń ṣe mí bíi pé kí n fi iléèwé sílẹ̀!”—Rose.
Ǹjẹ́ ó máa ń ṣe ẹ́ bíi tàwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn yìí? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn nǹkan wo ló ṣẹlẹ̀ tó fẹ́ mú kó o fi iléèwé sílẹ̀?
․․․․․
Ó tiẹ̀ lè ti máa wù ẹ́ gan-an báyìí pé kó o fi iléèwé sílẹ̀. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo lo ṣe lè mọ̀ bóyá ó ti tó àkókò tó yẹ kó o fi iléèwé sílẹ̀, àbí torí pé iléèwé kàn sú ẹ lo ṣe fẹ́ fi iléèwé sílẹ̀? Ká tó dáhùn ìbéèrè yìí, á dáa ká mọ ohun tó túmọ̀ sí pé kéèyàn fi iléèwé sílẹ̀.
Ṣé O Ti Kàwé Débi Tó Wù Ẹ́ Ni àbí O Kàn Fẹ́ Fi Iléèwé Sílẹ̀?
Ṣé o lè sọ ìyàtọ̀ tó wà nínú kéèyàn kàwé débi tó wù ú àti kéèyàn kàn fi iléèwé sílẹ̀?
․․․․․
Ǹjẹ́ o mọ̀ pé láwọn orílẹ̀-èdè kan, ó kéré tán àwọn ọ̀dọ́ gbọ́dọ̀ lo ọdún márùn-ún sí mẹ́jọ níléèwé? Láwọn orílẹ̀-èdè míì sì rèé, ó kéré tán, àwọn ọmọléèwé gbọ́dọ̀ lo ọdún mẹ́wàá sí méjìlá níléèwé. Torí náà, ọjọ́ orí téèyàn gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ iléèwé àti ibi tó yẹ kéèyàn kàwé dé kò bára mu níbi gbogbo.
Bákan náà, láwọn orílẹ̀-èdè kan, òfin gba àwọn ọmọ láyè láti máa gbélé kàwé, wọ́n lè ka àwọn ẹ̀ka ẹ̀kọ́ kan tàbí gbogbo ẹ̀ka ẹ̀kọ́ nílé, láìjẹ́ pé wọ́n ń lọ síléèwé. Bí àwọn òbí ọmọ kan bá fọwọ́ sí i pé kó bẹ̀rẹ̀ sí í gbélé kàwé, ìyẹn kò túmọ̀ sí pé ó ti fi iléèwé sílẹ̀.
Yálà ìwọ ń lọ síléèwé tàbí ò ń gbélé kàwé, bó o bá ń ronú láti fòpin sí ẹ̀kọ́ iléèwé rẹ ṣáájú ìgbà tó yẹ kó o gba ìwé ẹ̀rí, ó yẹ kó o gbé àwọn ìbéèrè yìí yẹ̀ wò:
Kí ni òfin béèrè? Bá a ti sọ ṣáájú, òfin nípa ibi tó yẹ kéèyàn kàwé dé kò dọ́gba láti orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn. Ní orílẹ̀-èdè tó o wà, ibo ni òfin sọ pé, ó kéré tán, ó yẹ kéèyàn kàwé dé? Ṣé o ti kàwé débẹ̀? Tó o bá kọ̀ láti ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé kí á “wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga,” tó o sì kọ̀ láti kàwé dé ibi tí òfin béèrè, ńṣe lo fi iléèwé sílẹ̀.—Róòmù 13:1.
Ṣé mo ti kàwé débi tí mo fẹ́ kà á dé? Kí làwọn nǹkan tó wù ẹ́ pé kó o ṣe lẹ́yìn tó o bá parí iléèwé rẹ? Bí o kò bá tí ì mọ ohun tó o fẹ́ ṣe, ńṣe lọ̀rọ̀ rẹ máa dà bíi ti ẹni tó wọ ọkọ̀ àmọ́ tí kò mọ ibi tó ń lọ. Torí náà, ṣe ni kí ìwọ àti àwọn òbí rẹ jọ kọ ọ̀rọ̀ kún àwọn àlàfo tó wà ní ojú ìwé 28 tó ní àkòrí náà, “Àwọn Ohun Tí Mo Fẹ́ Ṣe Tí Mo Bá Kàwé Tán.” Ìyẹn ò ní jẹ́ kó o máa ronú láti fi iléèwé sílẹ̀ ṣáájú ìgbà tó yẹ, èyí á sì jẹ́ kí ìwọ àtàwọn òbí rẹ jọ pinnu ibi tó o máa kàwé dé.—Òwe 21:5.
Ó dájú pé àwọn olùkọ́ rẹ àtàwọn ẹlòmíì máa gbà ẹ́ nímọ̀ràn nípa ibi tó o lè kàwé dé. Àmọ́, àwọn òbí rẹ ló máa pinnu ohun tí wàá ṣe. (Òwe 1:8; Kólósè 3:20) Bí o kò bá kàwé dé ibi tí ìwọ àtàwọn òbí rẹ jọ sọ, á jẹ́ pé o fi iléèwé sílẹ̀ nìyẹn.
Kí nìdí ti mo fi fẹ́ fi iléèwé sílẹ̀? Má ṣe tan ara rẹ jẹ. (Jeremáyà 17:9) Nígbà tí àwa èèyàn bá fẹ́ ṣe ohun tó wù wá, oríṣiríṣi àwáwí la máa ń ṣe.—Jákọ́bù 1:22.
Ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìdí tó o rò pé ó bọ́gbọ́n mu tó lè mú kó o fi iléèwé sílẹ̀ láìjẹ́ pé o kàwé débi tó o fẹ́.
․․․․․
Ṣàkọsílẹ̀ àwọn àwáwí tó o lè ṣe tó bá jẹ́ pé ńṣe ló kàn wù ẹ́ láti fi iléèwé sílẹ̀.
․․․․․
Àwọn ìdí tó bọ́gbọ́n mu wo lo kọ sílẹ̀? Ó lè jẹ́ torí kó o lè ṣèrànwọ́ lórí ọ̀rọ̀ gbígbọ́ bùkátà ìdílé rẹ tàbí kó o lè yọ̀ǹda ara rẹ láti máa kọ́ àwọn èèyàn ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àwọn ìdí tí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ lè jẹ́ torí pé o fẹ́ sá fún ìdánwò iléèwé tàbí torí o fẹ́ sá fún àwọn iṣẹ́ àṣetiléwá. Ó yẹ kó o ronú jinlẹ̀ kó o lè mọ ìdí pàtàkì tó mú kó o fẹ́ láti fi iléèwé sílẹ̀, ṣé ìdí tó bọ́gbọ́n mu ni àbí ìdí tí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀?
Tún ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tó o kọ sílẹ̀, kó o wá kọ nọ́ńbà 1 sí 5, sí ẹ̀gbẹ́ wọn látorí èyí tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì dórí èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ. Tó bá jẹ́ torí pé o fẹ́ sá fún àwọn ìṣòro lo ṣe fẹ́ fi iléèwé sílẹ̀, àfàìmọ̀ kó má jẹ́ pé ìbànújẹ́ lọ̀rọ̀ náà máa yọrí sí.
Kí Ló Burú Nínú Kéèyàn fi Iléèwé Sílẹ̀?
Tó o bá fi iléèwé sílẹ̀ nígbà tí kò tíì tó àkókò, ṣe ló dà bí ìgbà tó o bẹ́ sílẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú irin kó o tó dé ibi tó ò ń lọ. Òótọ́ ni pé ara lè má tù ẹ́ bó o ṣe wà nínú ọkọ̀ náà, àwọn tẹ́ ẹ jọ wọkọ̀ sì lè máa kanra. Àmọ́, tó o bá bẹ́ jáde nínú ọkọ̀ náà, o ò ní lè dé ibi tó ò ń lọ, o sì lè tipa bẹ́ẹ̀ ṣe ara rẹ léṣe. Bákan náà, tó o bá fi iléèwé sílẹ̀, o ò ní lè ṣe àwọn nǹkan tó o fẹ́ fi ẹ̀kọ́ rẹ ṣe, o sì lè tipa bẹ́ẹ̀ fa àwọn ìṣòro kan fún ara rẹ lójú ẹsẹ̀ àti lọ́jọ́ iwájú. Lára irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ rèé:
Àwọn ìṣòro tó lè jẹ yọ lójú ẹsẹ̀ Ó lè ṣòro fún ẹ láti rí iṣẹ́, tó o bá sì rí iṣẹ́, owó oṣù tí wọ́n á máa san fún ẹ lè máà tó èyí tí wàá máa gbà ká ní o kàwé débi tó yẹ. Kó o tó lè gbọ́ bùkátà ara rẹ, á wá di pé kó o máa fi ọ̀pọ̀ àkókò ṣiṣẹ́ ní àyíká ibi tó tiẹ̀ tún burú ju ti iléèwé rẹ lọ.
Àwọn ìṣòro tó lè jẹ yọ lọ́jọ́ iwájú Ìwádìí fi hàn pé ó ṣeé ṣe kí àwọn tó fi iléèwé sílẹ̀ ní àwọn àìlera kan, ó ṣeé ṣe kí wọ́n bímọ nígbà tí ọjọ́ orí wọn ṣì kéré, ó ṣeé ṣe kí wọ́n ṣẹ̀wọ̀n, wọ́n sì lè dẹni tó ń gbára lé ètò ìrànwọ́ tó wà fáwọn mẹ̀kúnnù kí wọ́n tó lè máa jẹun.
Òótọ́ ni pé, tó o bá dúró parí iléèwé rẹ, ìyẹn kò fún ẹ ní ìdánilójú pé o ò lè kojú àwọn ìṣòro tá a mẹ́nu bà yìí. Àmọ́ kò ní bọ́gbọ́n mu tó o bá dìídì ṣàkóbá fún ara rẹ nípa fífi iléèwé sílẹ̀.
Àwọn Àǹfààní Tó Wà Nínú Kó O Dúró Parí Iléèwé Rẹ
Tí èsì ìdánwò kan tó o ṣe kò bá dáa tàbí tó o kojú ìṣòro kan níléèwé, ìyẹn lè jẹ́ kí iléèwé sú ẹ, àwọn ìṣòro tó lè jẹ yọ lọ́jọ́ iwájú tiẹ̀ lè máà tó nǹkan kan lójú rẹ tó o bá fi wéra pẹ̀lú àwọn ohun tó ò ń kojú rẹ̀ báyìí. Àmọ́ kó o tó ṣe ohun tó dà bíi pé ó rọ̀ ẹ́ lọ́rùn yìí, gbé ohun tí àwọn ọmọ iléèwé tá a fa ọ̀rọ̀ wọn yọ lẹ́ẹ̀kan sọ nípa àwọn àǹfààní tó wà nínú kéèyàn dúró parí iléèwé rẹ̀.
● “Mo ti kọ́ béèyàn ṣe lè máa ní ìforítì, kó sì tún já fáfá. Mo tún ti kẹ́kọ̀ọ́ pé téèyàn bá fẹ́ gbádùn ohun kan, àfi kéèyàn nífẹ̀ẹ́ àtọkànwá sí nǹkan ọ̀hún. Mo ti túbọ̀ mọ iṣẹ́ àwòrán yíyà tí mo lọ kọ́ níléèwé, èyí sì máa ṣe mí làǹfààní tó pọ̀ gan-an lẹ́yìn tí n bá gboyè jáde.”—Rachel.
● Mo mọ̀ pé tí n bá ṣiṣẹ́ kára, ọwọ́ mi á lè tẹ àwọn àfojúsùn mi. Iṣẹ́ tí mò ń kọ́ níléèwé báyìí máa jẹ́ kí n lè kúnjú ìwọ̀n fún iṣẹ́ tí mo fẹ́ máa ṣe, ìyẹn iṣẹ́ títún èrọ ìtẹ̀wé ṣe.”—John.
● “Iléèwé tí mo lọ ti jẹ́ kí n mọ béèyàn ṣe lè yanjú ìṣòro, yálà níléèwé tàbí níbòmíì. Torí pé mo ti mọ bí mo ṣe lè yanjú àwọn ìṣòro tó jẹ mọ́ ẹ̀kọ́ iléèwé, àjọṣe mi pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì àtàwọn ìpèníjà míì, èyí ti jẹ́ kí n túbọ̀ dàgbà dénú.”—Cindy.
● “Ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ níléèwé ti jẹ́ kí n mọ ohun tí mo lè ṣe tí n bá ní ìṣòro lẹ́nu iṣẹ́ mi. Bákan náà, àwọn nǹkan kan máa ń ṣẹlẹ̀ láwọn ìgbà míì tó máa ń mú kó pọn dandan fún mi láti máa ṣàyẹ̀wò ìdí tí mo fi ń sin Ọlọ́run, torí náà, lílọ sí iléèwé ti jẹ́ kí ìgbàgbọ́ mi túbọ̀ lágbára.”—Rose.
Ọlọ́gbọ́n Ọba Sólómọ́nì kọ̀wé pé: “Òpin ọ̀ràn kan ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ sàn ju ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ rẹ̀ lọ. Onísùúrù sàn ju onírera ní ẹ̀mí.” (Oníwàásù 7:8) Torí náà, dípò tí wàá kàn fi kúrò níléèwé, ńṣe ni kó o fi sùúrù ronú nípa bó o ṣe lè kojú àwọn ìṣòro tó bá jẹ yọ. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá rí i pé ìgbẹ̀yìn rẹ̀ á dára gan-an ni.
O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype
OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ
● Tó o bá ní àwọn àfojúsùn tí ọwọ́ rẹ lè tètè tẹ̀ nípa ẹ̀kọ́ rẹ, báwo nìyẹn ṣe lè mú kó o lo àkókò tó o fi wà níléèwé lọ́nà tó dáa?
● Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o mọ nǹkan kan nípa iṣẹ́ tó o fẹ́ ṣe nígbà tó o bá kàwé tán?
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ Ẹ SỌ
“Iléèwé ló jẹ́ kí n fẹ́ràn ìwé kíka. Ohun tó dáa gan-an ni pé kéèyàn mọ̀wéé kà, ó lè jẹ́ kéèyàn mọ èrò ọkàn ẹlòmíì àti bọ́rọ̀ ṣe rí lára onítọ̀hún.”
“Ó máa ń ṣòro fún mi láti mọ ohun àkọ́múṣe. Ká wá ní mi ò kàwé rárá ni, ì bá tún burú jù báyìí lọ! Ẹ̀kọ́ Iléèwé ti jẹ́ kí n mọ béèyàn ṣe ń ṣètò nǹkan, ó ti jẹ́ kí n lè máa tẹ̀ lé ètò tí mo bá ṣe, kí n sì lè ṣe àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù lọ.”
[Àwọn àwòrán]
Esme
Christopher
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 28]
ÀWỌN OHUN TÍ MO FẸ́ ṢE TÍ MO BÁ KÀWÉ TÁN
Ọ̀kan lára ìdí pàtàkì téèyàn fi ń lọ síléèwé ni pé kó lè rí iṣẹ́ tó máa fi gbọ́ bùkátà ara rẹ̀, tó bá sì ní ìdílé lọ́jọ́ iwájú, kó lè gbọ́ bùkátà wọn. (2 Tẹsalóníkà 3:10, 12) Ǹjẹ́ o ti pinnu irú iṣẹ́ tó o fẹ́ ṣe tó o bá kàwé tán, ṣé o sì ti mọ bó o ṣe lè fi àkókò tó o ṣì wà níléèwé múra sílẹ̀ fún iṣẹ́ náà? Kó o lè mọ̀ bóyá ẹ̀kọ́ tí ò ń kọ́ níléèwé báyìí á jẹ́ kó o lè ṣe iṣẹ́ náà, dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí:
Àwọn ẹ̀bùn wo ni mo ní? (Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ ara rẹ yọ̀ mọ́ àwọn èèyàn, tó o sì mọ bí wọ́n ṣe ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ dáadáa? Ṣé o gbádùn kó o máa fọwọ́ ara rẹ ṣe àwọn nǹkan tàbí kó o máa tún àwọn nǹkan tó bà jẹ́ ṣe? Ṣé o mọ béèyàn ṣe lè ronú jinlẹ̀ lórí ìṣòro kó sì yanjú rẹ̀?)
․․․․․
Àwọn iṣẹ́ wo ni mo lè ṣe tó máa jẹ́ kí n lè lo àwọn ẹ̀bùn tí mo ní?
․․․․․
Irú àwọn iṣẹ́ wo ló wà tí mo lè ṣe ní àgbègbè ibi tí mò ń gbé?
․․․․․
Àwọn ẹ̀kọ́ wo ni mò ń kọ́ báyìí tó máa jẹ́ kí n lè rí iṣẹ́?
․․․․․
Àwọn ẹ̀kọ́ wo ni mò ń kọ́ níléèwé báyìí tó máa jẹ́ kó rọrùn fún mi láti lé àwọn àfojúsùn mi bá?
․․․․․
Má gbàgbé pé ìdí tó o fi ń lọ sí iléèwé ni pé kó o lè kẹ́kọ̀ọ́ yege nípa ohun tó máa ṣe ẹ́ láǹfààní lọ́jọ́ iwájú. Torí náà, má ṣe ki àṣejù bọ̀ ọ́ nípa jíjókòó pa sí kíláàsì kan, torí pé ó fẹ́ sá fún àwọn ojúṣe tó o máa ní lẹ́yìn tó o bá kàwé tán. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀ ńṣe lo máa dà bí ẹni tó wọ ọkọ̀, àmọ́ tó kọ̀ láti sọ̀ kalẹ̀.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 29]
Ọ̀RỌ̀ RÈÉ O, Ẹ̀YIN ÒBÍ
“Ọ̀rọ̀ àwọn olùkọ́ mi ti sú mi!” “Iṣẹ́ àṣetiléwá tí wọ́n máa ń fún mi ti pọ̀ jù!” “Kì í rọrùn rárá láti gba máàkì gidi, mo kàn ń da ara mi láàmù lásán ni? Irú àwọn wàhálà yìí ló mú kí ọ̀rọ̀ iléèwé sú àwọn ọ̀dọ́ kan, wọ́n sì ń fẹ́ láti fi iléèwé sílẹ̀, láìtíì kọ́ àwọn ẹ̀kọ́ tó máa jẹ́ kí wọ́n lè gbọ́ bùkátà ara wọn. Bí ọmọ rẹ bá sọ pé òun fẹ́ fi iléèwé sílẹ̀, kí lo lè ṣe?
Irú ojú wo ni ìwọ òbí fi ń wo ẹ̀kọ́ ìwé? Nígbà tó o wà ní ọ̀dọ́, ṣé fífi àkókò ṣòfò lásán lo ka iléèwé sí, àbí ńṣe lò ń wò ó bí ìgbà tó o wà nínú àhámọ́, tó fi jẹ́ pé ńṣe lo kàn rọ́jú títí dìgbà tó o fi lè ṣe àwọn nǹkan míì tó wù ẹ́? Bọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, irú ojú tó o fi ń wo ẹ̀kọ́ ìwé yìí lè nípa lórí àwọn ọmọ rẹ. Bí àwọn ọmọ rẹ bá kàwé yanjú, wọ́n á ní “ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ àti agbára láti ronú, èyí sì ṣe pàtàkì bí wọ́n bá máa di àgbàlagbà tó ṣàṣeyọrí.—Òwe 3:21.
Fún wọn ní ohun tí wọ́n nílò. Àwọn ọmọ kan wà tó jẹ́ pé torí pé wọn ò mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n máa kẹ́kọ̀ọ́ ni kò jẹ́ kí wọ́n ṣe dáadáa níléèwé, tàbí kó jẹ́ pé wọn ò ríbi tó dáa tí wọ́n ti lè máa kàwé. Lára àwọn ohun tó lè wà níbi tí ọmọ rẹ á ti máa kàwé ni tábìlì tí ẹrù kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ lórí rẹ̀, tí ìmọ́lẹ̀ sì wà dáadáa àtàwọn ohun tí ọmọ náà lè fi ṣe ìwádìí. O lè ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti túbọ̀ máa ṣe dáadáa yálà nínú ẹ̀kọ́ ìwé rẹ̀ tàbí nínú àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run, tó o bá ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ tó o sì ṣètò ibi tó dáa tó ti lè máa ro àròjinlẹ̀ lórí àwọn nǹkan tuntun.—1 Tímótì 4:15.
Máa mọ bí nǹkan ṣe ń lọ sí. Gbà pé ìwọ àtàwọn olùkọ́ tó ń gba ọmọ rẹ nímọ̀ràn jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ ni, má ṣe máa wò wọ́n bí ọ̀tá. Rí i pé o mọ̀ wọ́n, kó o sì mọ orúkọ wọn. Máa bá wọn sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí ọmọ rẹ fẹ́ ṣe lẹ́yìn tó bá parí iléèwé àtàwọn ìṣòro tí ọmọ náà ní. Bí ọmọ rẹ kò bá ṣe dáadáa nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀, gbìyànjú láti mọ ohun tó fà á. Bí àpẹẹrẹ, ṣé kì í ṣe pé ńṣe ni ọmọ rẹ ń rò pé tí òun bá ń ṣe dáadáa jù níléèwé àwọn ojúgbà òun lè bẹ̀rẹ̀ sí í halẹ̀ mọ́ òun? Àbí ọ̀kan nínú àwọn olùkọ́ rẹ̀ ló ń dà á láàmù? Ó sì lè jẹ́ pé àwọn iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe níléèwé ló ń fún un níṣòro. Ṣe ló yẹ kí àwọn iṣẹ́ iléèwé máa ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti máa fi ìmọ̀ kún ìmọ̀, àwọn iṣẹ́ náà kò gbọ́dọ̀ mu ún lómi ju bó ṣe yẹ lọ. Ó sì tún lè jẹ́ pé àwọn ìṣòro míì ló fà á, irú bí ojú tí kò ríran dáadáa tàbí kó jẹ́ pé ọmọ rẹ ló ní ìṣòro ẹ̀kọ́ kíkọ́.
Bó o bá ṣe túbọ̀ ń mọ bí ẹ̀kọ́ ọmọ rẹ ṣe ń lọ sí, yálà ẹ̀kọ́ iléèwé ni o tàbí ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn máa nípa lórí bí ọmọ rẹ ṣe máa ṣàṣeyọrí.—Òwe 22:6.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Tó o bá fi iléèwé sílẹ̀ nígbà tí kò tíì tó àkókò, ṣe ló dà bí ìgbà tó o bẹ́ sílẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú irin kó o tó dé ibi tó ò ń lọ.