ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwyp àpilẹ̀kọ 7
  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Ò Bá Wù Mí Láti Lọ sí Iléèwé?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Ò Bá Wù Mí Láti Lọ sí Iléèwé?
  • Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Kí N Fi Iléèwé Sílẹ̀?
    Jí!—2011
  • Ǹjẹ́ Mi Ò Ní Pa Ilé Ìwé Tì Báyìí?
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kìíní
  • Jàǹfààní Dídára Jù Lọ ní Ilé Ẹ̀kọ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Ẹ̀yin Èwe—Ẹ Lo Àǹfààní Ẹ̀kọ́ Yín Lọ́nà Rere
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
Àwọn Míì
Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
ijwyp àpilẹ̀kọ 7
Ọmọkùnrin kan tí inú ẹ̀ ò dùn dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ ibi tí wọ́n ń kó nǹkan pa mọ́ sí ní iléèwé.

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Ò Bá Wù Mí Láti Lọ sí Iléèwé?

Ṣé àwọn olùkọ́ ẹ le koko mọ́ ẹ níléèwé, àbí àwọn ojúgbà ẹ máa ń halẹ̀ mọ́ ẹ? Ṣé iṣẹ́ àṣetiléwá máa ń pọ̀ fún ẹ láti ṣe, tí ìdánwò sì máa ń dẹ́rù bà ẹ́? Àwọn nǹkan yìí tó ohun tó lè mú kó má wù ẹ́ láti lọ síléèwé.a Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Rachelb sọ pé:

“Ní tèmi, ó sàn kí n lọ gbafẹ́ létíkun tàbí kí n wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi. Kódà, ó sàn kí n máa bá àwọn òbí mi dáná tàbí túnlé ṣe ju kí n lọ síléèwé.”

Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi ti Rachel, lílọ sílé ìwé lè dà bí ìgbà tí wọ́n rán ẹ lọ sẹ́wọ̀n, tó o wá ń fara dà á dìgbà tí wọ́n máa tú ẹ sílẹ̀. Kí lo lè ṣe tí iléèwé ò fi ní sú ẹ?

Ǹjẹ́ o mọ̀? Tó o bá ní èrò tó tọ́ nípa ilé ìwé, kò ní sú ẹ, o ò sì ní máa wo iléèwé bí ibi tí wọ́n ń fipá rán ẹ lọ. Èyí máa jẹ́ kó o gbà pé iléèwé jẹ́ ibi tí wàá ti kọ́ àwọn nǹkan tó o máa nílò tó o bá dàgbà.

Tó o bá fẹ́ ní èrò tó tọ́ nípa ilé ìwé, máa ronú nípa àwọn nǹkan yìí:

Ìwé àti pẹ́ńsù.

Ẹ̀kọ́ rẹ. Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i ni wàá túbọ̀ mọ bí wàá ṣe yanjú ìṣòro tó bá yọjú lọ́jọ́ iwájú, bóyá níbi tó o ti ń ṣiṣẹ́ tàbí nídìí àwọn nǹkan míì tó o bá ń ṣe. O ò ní máa retí pé káwọn míì bá ẹ yanjú ìṣòro ẹ. Bi ara ẹ pé, ‘Táwọn nǹkan kan bá tiẹ̀ wà tí mi ò fẹ́ràn nílé ìwé, àwọn ẹ̀kọ́ wo ni mò ń kọ́ níbẹ̀ tó máa wúlò fún mi?’

Ìlànà Bíbélì: “Má ṣe jẹ́ kí ọgbọ́n tó gbéṣẹ́ àti làákàyè bọ́ mọ́ ọ lọ́wọ́.”​—Òwe 3:21.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, ka àpilẹ̀kọ náà, “Kí Nìdí Tí Mo Fi Ń Gba Òdo Nílé Ìwé?”

Àkójọ ohun téèyàn fẹ́ ṣe.

Ìwà rẹ. Àwọn nǹkan tẹ́ ẹ̀ ń ṣe nílé ìwé máa jẹ́ kó o mọ bó ṣe lè máa fọgbọ́n lo àkókò ẹ, bó o ṣe lè máa kó ara ẹ níjàánu, kó o sì jẹ́ ẹni tó ń ṣiṣẹ́ kára. Àwọn ìwà yìí máa ṣe ẹ́ láǹfààní tó o bá dàgbà. Bi ara ẹ pé: ‘Báwo làwọn nǹkan tá à ń ṣe nílé ìwé ṣe ń jẹ́ kí n máa kó ara mi níjàánu, kí n sì máa ṣiṣẹ́ kára? Kí ni mo lè ṣe táá jẹ́ kí n sunwọ̀n sí i láwọn apá yìí?’

Ìlànà Bíbélì: “Gbogbo iṣẹ́ àṣekára ló ní èrè.”​—Òwe 14:23.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, ka àpilẹ̀kọ náà, “Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Ṣọ́ Àkókò Lò?”

Àwọn méjì jọ ń sọ̀rọ̀.

Àjọṣe ẹ pẹ̀lú àwọn míì. Bó o ṣe ń ṣe sáwọn ọmọ kíláàsì ẹ níléèwé máa jẹ́ kó o túbọ̀ máa gba tàwọn míì rò, kó o sì máa kà wọ́n sí. Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Joshua sọ pé: “Bí ẹ̀kọ́ ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àtàwọn ẹ̀kọ́ míì ṣe ṣe pàtàkì, náà ló ṣe pàtàkì kéèyàn kọ́ bí á ṣe máa báwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Ó ṣe tán, jálẹ̀ ayé wa làá máa báwọn èèyàn sọ̀rọ̀.” Bi ara ẹ pé, ‘Kí ni mo ti kọ́ níléèwé nípa bí mo ṣe lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn èèyàn, títí kan àwọn tí àṣà ìbílẹ̀ àti ẹ̀sìn wọn yàtọ̀ sí tèmi?’

Ìlànà Bíbélì: “Ẹ máa lépa àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo èèyàn.”​—Hébérù 12:14.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, ka àpilẹ̀kọ náà, “Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Ò Bá Rọrùn fún Mi Láti Máa Bá Àwọn Èèyàn Sọ̀rọ̀?”

Ẹni tó ń rìn lójú ọ̀nà.

Ọjọ́ ọ̀la rẹ. Àwọn ohun tẹ́ ẹ̀ ń kọ́ níléèwé lè jẹ́ kó o mọ ẹ̀bùn tó o ní tàbí ohun tó o mọ̀ ọ́n ṣe, kó o sì fìyẹn pinnu ohun tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Brooke sọ pé: “O lè gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ lórí iṣẹ́ kan pàtó; ohun témi ṣe nìyẹn. Tó o bá wá jáde, wàá lè fi ohun tó o kọ́ yẹn ríṣẹ́.” Bi ara ẹ pé: ‘Iṣẹ́ wo ni mo fẹ́ máa fi gbọ́ bùkátà ara mi tí mo bá jáde iléèwé? Kí ni mo lè ṣe tí màá fi kọ́ ohun tó máa wúlò fún mi lẹ́nu iṣẹ́ yẹn?’

Ìlànà Bíbélì: “Kíyèsí ìrìn ẹsẹ̀ rẹ.”​—Òwe 4:26, Yoruba Bible.

a Ọ̀pọ̀ àwọn àbá tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí máa wúlò fún àwọn ọmọ tó jẹ́ pé òbí wọn ló ń kọ́ wọn níwèé nílé.

b A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

Ohun táwọn ojúgbà ẹ sọ

  • Madison.

    “Tí wọ́n bá yan àwa mélòó kan pé ká jọ ṣe àwọn iṣẹ́ kan pa pọ̀ níléèwé, oríṣiríṣi èèyàn ni mo máa ń bá ṣiṣẹ́. Àṣà ìbílẹ̀ wa máa ń yàtọ̀, bí wọ́n sì ṣe ń ṣe nǹkan máa ń yàtọ̀ sí tèmi. Ìyẹn jẹ́ kí n mọ béèyàn ṣe ń gba tàwọn míì rò. Àwọn ọmọ kíláàsì mi fẹ́ràn mi, wọ́n sì máa ń bọ̀wọ̀ fún mi torí wọ́n mọ̀ pé mo máa ń ṣe dáadáa sáwọn, mi kì í sì í ṣàríwísí wọn.”​—Madison.

  • Ryan.

    “Mo kọ́ bí mo ṣe lè máa fojú tó tọ́ wo àwọn ọmọ kíláàsì mi. Ọ̀pọ̀ wọn ló máa ń wù láti ṣe ohun tó dáa. Torí náà, mo máa ń wá bí mo ṣe lè bá wọn sọ̀rọ̀ Bíbélì tó máa gbé wọn ró.”​—Ryan.

  • Brooke.

    “Iléèwé máa kọ́ ẹ bó o ṣe lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn èèyàn. Ọ̀pọ̀ àkókò lo fi ń wà pẹ̀lú àwọn ọmọ kíláàsì ẹ, torí náà wàá kọ́ ohun tó yẹ kó o sọ àtohun tí ò yẹ kó o sọ. Wàá tún kọ́ bó o ṣe lè ní sùúrù àti bó o ṣe lè pín ohun tó o bá ní pẹ̀lú àwọn míì. Tẹ́ ẹ bá ń ṣe ẹ̀kọ́ nípa eré ìdárayá, o máa kọ́ bí ìwọ àtàwọn míì ṣe lè jọ ṣe nǹkan pa pọ̀. Kò sí bó o ṣe lè dá kọ́ àwọn nǹkan yẹn láìṣe é pẹ̀lú àwọn míì.”​—Brooke.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́