Ẹ̀yin Èwe—Ẹ Lo Àǹfààní Ẹ̀kọ́ Yín Lọ́nà Rere
1 Báwo ni ìmọ̀lára rẹ ṣe rí nípa pípadà sí ilé ẹ̀kọ́ lẹ́yìn ìsinmi ìparí ọdún? Ìwọ ha ń fi ìháragàgà fẹ́ láti jàǹfààní láti inú ẹ̀kọ́ ọdún mìíràn bí? Ìwọ yóò ha lo àǹfààní tí ilé ẹ̀kọ́ rẹ fún ọ láti ṣàjọpín òtítọ́ pẹ̀lú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ àti àwọn olùkọ́ rẹ bí? Ó dá wa lójú pé ìwọ yóò fẹ́ sa gbogbo ipá rẹ ní ilé ẹ̀kọ́.
2 Jẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Rere: Bí o bá múra sílẹ̀ dáadáa nígbà tí o bá wà níbi ẹ̀kọ́ tí o sì fetí sílẹ̀ dáadáa, ìwọ yóò jàǹfààní tí ó wà pẹ́ títí. Jẹ́ aláápọn nínú ṣíṣe àwọn iṣẹ́ àṣetiléwá rẹ, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ rẹ ṣèdíwọ́ fún àwọn ìgbòkègbodò ti ìṣàkóso Ọlọ́run.—Fílí. 1:10.
3 Fi kíka ìwé pẹlẹbẹ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Ìmọ̀ Ẹ̀kọ́ bẹ̀rẹ̀ sáà tuntun ní ilé ẹ̀kọ́. Lẹ́yìn náà, kí ìwọ tàbí àwọn òbí rẹ fún olùkọ́ rẹ kọ̀ọ̀kan ní ẹ̀dà kan. Jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ìbéèrè èyíkéyìí tí wọ́n bá ní ni ìwọ yóò dáhùn. Èyí yóò jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ lóye àwọn ìlànà àti ìgbàgbọ́ rẹ, wọn yóò sì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ bí o ṣe ń fi àwọn ohun tí a ti kọ́ ọ sílò. Yóò tún mú un dá àwọn olùkọ́ rẹ lójú pé ìwọ àti àwọn òbí rẹ múra tán láti fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wọn bí àwọn olùkọ́ ti ń ràn ọ́ lọ́wọ́ láti jèrè ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó ṣeyebíye.
4 Jẹ́ Ẹlẹ́rìí Rere: Èé ṣe tí o kò fi wo ilé ẹ̀kọ́ gẹ́gẹ́ bí ìpínlẹ̀ tìrẹ fún jíjẹ́rìí lọ́nà tí kì í ṣe bí àṣà? Ní sáà ilé ẹ̀kọ́ tí ń bọ̀, ìwọ yóò ní àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ láti jẹ́rìí. O ní àgbàyanu ìmọ̀ tẹ̀mí tí ó jẹ́ pé, nígbà tí o bá ṣàjọpín rẹ̀, o lè “gba ara rẹ àti àwọn tí ń fetí sí ọ là.” (1 Tím. 4:16) Nípa níní ìwà àwòfiṣàpẹẹrẹ Kristẹni àti nípa jíjẹ́rìí nígbàkigbà tí ó bá bójú mu láti ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò ṣe ara rẹ àti àwọn ẹlòmíràn láǹfààní.
5 Arákùnrin ọ̀dọ́ kan jẹ́rìí fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀. Lára àwọn tí ó dáhùn padà lọ́nà rere ni onísìn Kátólíìkì kan, aláìgbọlọ́rungbọ́ kan tí ó ti máa ń fi àwọn tí ó gba Ọlọ́run gbọ́ ṣe yẹ̀yẹ́ tẹ́lẹ̀, àti èwe kan tí ó jẹ́ amusìgá tí ń fìkan ràn kan àti ọ̀mùtí paraku kan. Lápapọ̀, arákùnrin ọ̀dọ́ yìí ran 15 nínú àwọn ojúgbà rẹ̀ lọ́wọ́ láti ya ara wọn sí mímọ́, kí wọ́n sì ṣe batisí!
6 Nítorí náà, ẹ̀yin èwe, ẹ gbájú mọ́ kíkẹ́kọ̀ọ́, kí ẹ sì gbájú mọ́ ṣíṣiṣẹ́ nínú ìpínlẹ̀ aláìlẹ́gbẹ́ tí ẹ ní fún jíjẹ́rìí. Nígbà náà, ẹ óò gbádùn àǹfààní tí ó ga jù lọ láti inú lílọ sí ilé ẹ̀kọ́.