ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/09 ojú ìwé 2
  • Ṣẹ́ Ẹ Ti Múra Sílẹ̀ fún Iléèwé?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣẹ́ Ẹ Ti Múra Sílẹ̀ fún Iléèwé?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ǹjẹ́ Àwọn Ọmọ Rẹ Ti Múra Sílẹ̀?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Ẹ̀yin Èwe—Ẹ Lo Àǹfààní Ẹ̀kọ́ Yín Lọ́nà Rere
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Ṣé Kí N Fi Iléèwé Sílẹ̀?
    Jí!—2011
  • Má Ṣe Fà Sẹ́yìn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
km 8/09 ojú ìwé 2

Ṣẹ́ Ẹ Ti Múra Sílẹ̀ fún Iléèwé?

1. Àwọn àǹfààní wo ló máa ṣí sílẹ̀ fún ẹ̀yin ọ̀dọ́ nígbà tí sáà ẹ̀kọ́ mìíràn bá bẹ̀rẹ̀?

1 Yálà ẹ̀yin Kristẹni tẹ́ ẹ jẹ́ ọ̀dọ́ ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ wọ ilé ìwé ni o, tàbí ẹ fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sáà ẹ̀kọ́ mìíràn, ẹ máa dojú kọ àwọn ìṣòro tẹ́ ò tíì rírú ẹ̀ rí. Àmọ́, ẹ tún máa láǹfààní láti “jẹ́rìí sí òtítọ́.” (Jòh. 18:37) Ṣó o ti múra sílẹ̀ dáadáa láti wàásù?

2. Kí ló máa fi hàn pé ẹ ti múra sílẹ̀ fún iléèwé?

2 Kẹ́ ẹ lè ṣàṣeyọrí nínú ohunkóhun tẹ́ ẹ bá dáwọ́ lé, ẹ ti gba ọ̀pọ̀ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ látọ̀dọ̀ Jèhófà, látọ̀dọ̀ àwọn òbí yín àti nípasẹ̀ ẹrú olóòótọ́ àti olóye. (Òwe 1:8; 6:20; 23:23-25; Éfé. 6:1-4; 2 Tím. 3:16, 17) Ní báyìí, ó dájú pé ẹ ti mọ àwọn ìṣòro tó ṣeé ṣe kẹ́ ẹ dojú kọ níléèwé. Pẹ̀lú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tẹ́ ẹ ti gbà nípa ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ àti ohun tẹ́ ẹ ti mọ̀ nípa àwọn nǹkan tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ níléèwé yín, ńṣe ni kẹ́ ẹ múra sílẹ̀ láti wàásù. (Òwe 22:3) Ẹ fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn ìtọ́ni àtàwọn àbá tó lè ṣèrànwọ́ tó dá lórí Ìwé Mímọ́, èyí tó wà nínú apá kìíní àti apá kejì ìwé “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé,” tó fi mọ́ àwọn àpilẹ̀kọ tó tan mọ́ ọn tó máa ń jáde déédéé nínú ìwé ìròyìn Jí!

3. Àwọn ọ̀nà wo lẹ lè gbà jẹ́rìí níléèwé?

3 Ẹ máa láǹfààní láti jẹ́rìí lónírúurú ọ̀nà níléèwé tó jẹ́ ìpínlẹ̀ ìwàásù àrà ọ̀tọ̀ fún yín. Báwọn míì bá kíyè sí bẹ́ ẹ ṣe ń múra lọ́nà tó dáa, tí wọ́n ń kíyè sí ọ̀rọ̀ àti ìṣe yín, tí wọ́n ń rí bẹ́ ẹ ṣe máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn olùkọ́, àti bẹ́ ẹ ṣe ń ṣe dáadáa sí nínú ẹ̀kọ́ yín, tó sì wá hàn sí wọn pé ẹ mọ ohun tẹ́ ẹ fẹ́ fìgbésí ayé yín ṣe, àwọn kan lára wọn lè béèrè pé: “Kí ló dé ti tiyín fi yàtọ̀?” (Mál. 3:18; Jòh. 15:19) Èyí lè fún yín láǹfààní láti wàásù, kẹ́ ẹ sì ṣàlàyé ohun tẹ́ ẹ gbà gbọ́. (1 Tím. 2:9, 10) Jálẹ̀ ọdún, ó ṣeé ṣe kẹ́ ẹ dojú kọ àwọn ìṣòro kan, irú bí ìgbà tí wọ́n bá ń ṣọdún tàbí àwọn ayẹyẹ orílẹ̀-èdè. Tí wọ́n bá bi ẹ́ pé kí ló dé tó ò fi bá wọn ṣe é, ṣé wàá kàn sọ pé “A kì í ṣe é nínú ẹ̀sìn tèmi; Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí,” àbí wàá lo àǹfààní yẹn láti jẹ́rìí nípa Baba rẹ onífẹ̀ẹ́, Jèhófà? Bí ẹ̀yin ọ̀dọ́ bá múra sílẹ̀ dáadáa, tẹ́ ẹ sì tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà, ẹ máa ṣe tán láti jẹ́rìí fáwọn ọmọléèwé yín, àwọn olùkọ́, àtàwọn míì.—1 Pét. 3:15.

4. Kí nìdí tó fi lè dá ẹ̀yin ọ̀dọ́ lójú pé ẹ máa ṣàṣeyọrí níléèwé?

4 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rù lè máa bà yín láti lọ síléèwé, ẹ mọ̀ dájú pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa tì yín lẹ́yìn kẹ́ ẹ lè ṣàṣeyọrí. Síwájú sí i, a báa yín yọ̀ fún àǹfààní tẹ́ ẹ máa ní láti jẹ́rìí níléèwé tó jẹ́ ìpínlẹ̀ ìwàásù àrà ọ̀tọ̀ fún yín. Torí náà, ẹ jẹ́ onígboyà kẹ́ ẹ sì múra sílẹ̀ fún iléèwé!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́