ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 7/11 ojú ìwé 2
  • Ǹjẹ́ Àwọn Ọmọ Rẹ Ti Múra Sílẹ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Àwọn Ọmọ Rẹ Ti Múra Sílẹ̀?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ran Àwọn Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Láti Kojú Àwọn Ìṣòro Tó Ń Bá Wọn Fínra
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Ṣẹ́ Ẹ Ti Múra Sílẹ̀ fún Iléèwé?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Báwo Ni Ìdílé Rẹ Ṣe Lè Jẹ́ Aláyọ̀?—Apá Kejì
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Kí Wọ́n Lè Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
km 7/11 ojú ìwé 2

Ǹjẹ́ Àwọn Ọmọ Rẹ Ti Múra Sílẹ̀?

1. Kí nìdí tó fi yẹ kí àwọn ọmọ tó ṣì wà níléèwé múra sílẹ̀?

1 Ó ti ń tó àkókò fún àwọn ọmọ iléèwé láti wọlé fún sáà ẹ̀kọ́ mìíràn. Kò sí àní-àní pé àwọn ọmọ yín máa kojú àwọn ìṣòro kan àti ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ńṣe. Wọ́n á sì tún láǹfààní láti “jẹ́rìí sí òtítọ́.” (Jòh. 18:37) Ṣé wọ́n ti múra sílẹ̀?

2. Kí àwọn ọmọ yín múra sílẹ̀, kí ló yẹ kí wọ́n mọ̀?

2 Ǹjẹ́ ìdí tí àwọn èèyàn fi máa ń ṣe ayẹyẹ tó ní ín ṣe pẹ̀lú ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni tàbí àwọn ayẹyẹ míì tó jẹ́ ti àwọn abọ̀rìṣà yé àwọn ọmọ yín dáadáa, ṣé wọ́n sì mọ ìdí tí kò fi yẹ kí wọ́n lọ́wọ́ nínú rẹ̀? Ṣé wọ́n ti mọ ohun tí wọ́n máa sọ nígbà tí wọ́n bá ń fúngun mọ́ wọn pé kí wọ́n gbájú mọ́ lílépa ìmọ̀ ẹ̀kọ́ níléèwé gíga, pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ ẹnì kan, kí wọ́n máa mutí tàbí kí wọ́n máa lo oògùn olóró? Ṣé ohun tí wọ́n kàn máa sọ ni pé, ẹ̀sìn àwọn kò fàyè gbà á, àbí wọ́n á lè ṣàlàyé ohun tí wọ́n gbà gbọ́?—1 Pét. 3:15.

3. Báwo ni àwọn òbí ṣe lè lo àkókò Ìjọsìn Ìdílé láti kọ́ àwọn ọmọ wọn bí wọ́n á ṣe gbèjà ìgbàgbọ́ wọn?

3 Ẹ Lo Àkókò Ìjọsìn Ìdílé: Òótọ́ ni pé títí àwọn ọmọ yín á fi jáde ilé ìwé ni ẹ ó jọ máa sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro tí wọ́n ní níléèwé. Tẹ́ ẹ bá sapá láti jíròrò àwọn ìṣòro tí wọ́n lè kojú ní ilé ìwé ṣáájú kí wọ́n tó wọlé, ó máa jẹ́ kí wọ́n ní ìgboyà. Ẹ ò ṣe lo àkókò Ìjọsìn Ìdílé kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ láti fi jíròrò rẹ̀? Ẹ lè ní kí àwọn ọmọ yín sọ ohun tó ń já wọn láyà bí ọjọ́ tí wọ́n máa wọlé iléèwé ṣe ń sún mọ́lé. Ẹ tún lè ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ọ̀ràn kan tẹ́ ẹ ti jíròrò pẹ̀lú àwọn ọmọ yín ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn nígbà tí wọ́n ṣì kérè, ní báyìí tí wọ́n ti dàgbà tí òye wọn sì ti pọ̀ sí i. (Sm. 119:95) Ẹ lè ṣe ìdánrawò, kí ẹ̀yin òbí ṣe bí olùkọ́, agbaninímọ̀ràn tàbí akẹ́kọ̀ọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn. Ẹ kọ́ àwọn ọmọ yín bí wọ́n ṣe lè fi Bíbélì dáhùn ìbéèrè àti bí wọ́n á ṣe máa lo àwọn ìtẹ̀jáde bí ìwé Reasoning àti ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé. Òbí kan lo àkókò ìdánrawò láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ bí wọ́n á ṣe jẹ́ kí àwọn olùkọ́ tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dé iléèwé wọn mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni àwọn, nígbà tí sáà ilé ẹ̀kọ́ bá bẹ̀rẹ̀ lọ́dọọdún.—Wo Ilé Ìṣọ́ December 15, 2010, ojú ìwé 3 sí 5.

4. Kí ni àwọn òbí tó gbọ́n máa ṣe?

4 Ńṣe ni àwọn ìṣòro tí àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n jẹ́ Kristẹni ń kojú ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí túbọ̀ ń “nira láti bá lò.” (2 Tím. 3:1) Àwọ́n òbí tó jẹ́ ọlọ́gbọ́n á sapá láti ronú nípa àwọn ìṣòro tó ṣeé ṣe kí àwọn ọmọ wọn bá pàdé nílé ẹ̀kọ́. (Òwe 22:3) Kí sáà ilé ẹ̀kọ́ tuntun tó bẹ̀rẹ̀, ẹ ṣe gbogbo ohun tẹ́ ẹ bá lè ṣe láti mú kí àwọn ọmọ yín múra sílẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́