Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ July 18
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JULY 18
Orin 98 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 6 ìpínrọ̀ 17 sí 24, àti àpótí tó wà lójú ìwé 48 (25 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Sáàmù 74-78 (10 min.)
No. 1: Sáàmù 77:1-20 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Àwọn Ọ̀nà Tá A Lè Gbà Kọ Ojú Ìjà sí Èṣù—Ják. 4:7 (5 min.)
No. 3: Ṣé Ọjọ́ Oníwákàtí Mẹ́rìnlélógún Ni Ọjọ́ Kọ̀ọ̀kan Ìṣẹ̀dá?—td 29B (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀.
15 min: Kí La Rí Kọ́? Ìjíròrò. Ẹ ka Jòhánù 4:3-24, kẹ́ ẹ sì jíròrò rẹ̀. Ẹ jíròrò bá a ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Lẹ́yìn náà, ṣe àṣefihàn bí àkéde kan ṣe ń jẹ́rìí lọ́nà àìjẹ́bí-àṣà. Kí àṣefihàn náà jẹ́ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ gan-an.
15 min: “Ǹjẹ́ Àwọn Ọmọ Rẹ Ti Múra Sílẹ̀?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ní kí àwọn òbí àtàwọn ọ̀dọ́ sọ ìṣòro tí àwọn Kristẹni ń kojú níléèwé. Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá ti jíròrò ìpínrọ̀ 3, ṣe àṣefihàn kan, kí bàbá ṣe bí olùkọ́, kí ọmọ sì ṣàlàyé ìdí tí kò fi fẹ́ lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ kan tí wọ́n ṣe ní kíláàsì, tàbí nǹkan míì, tó ta ko ìlànà Bíbélì.
Orin 91 àti Àdúrà