Máa Fi “Ìyọ́nú Oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́” Hàn
1. Kí làwọn èèyàn nílò gan-an lóde òní?
1 Ọ̀pọ̀ èèyàn nílò ẹni táá máa fi ìyọ́nú hàn sí wọn gan-an lásìkò yìí ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Bí ipò ayé ṣe ń burú sí i, ìbànújẹ́, ìsoríkọ́ àti àìnírètí ti bá ọ̀pọ̀ èèyàn. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló nílò ìrànlọ́wọ́, àwa tá a sì jẹ́ Kristẹni la wà ní ipò láti fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn aládùúgbò wa jẹ wá lógún gan-an. (Mát. 22:39; Gál. 6:10) Báwo la ṣe lè fi hàn pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ wá lógún?
2. Ọ̀nà wo ló dára jù lọ fún wa láti fi ìyọ́nú hàn sáwọn èèyàn?
2 Iṣẹ́ Tó Fi Hàn Pé A Jẹ́ Oníyọ̀ọ́nú: Ọlọ́run nìkan ló lè pèsè ìtùnú tó wà pẹ́ títí tó sì jẹ́ ojúlówó. (2 Kọ́r. 1:3, 4) Jèhófà rọ̀ wá pé ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ òun nípa jíjẹ́ ẹni tó ní “ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ,” ó sì ti gbé iṣẹ́ lé wa lọ́wọ́ pé ká sọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn aládùúgbò wa. (1 Pét. 3:8) Ìtara kópa nínú iṣẹ́ yìí ni ọ̀nà tó dára jù lọ fún wa láti tu “àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn” nínú, torí pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló máa yanjú ìṣòro ìràn èèyàn. (Aísá. 61:1) Láìpẹ́, ìyọ̀nú tí Jèhófà ní fún àwọn èèyàn rẹ̀ máa mú kó mú ìwà ibi kúrò láyé, táá sì mú ayé tuntun òdodo wá.—2 Pét. 3:13.
3. Báwo la ṣe lè ní irú èrò tí Jésù ní nípa àwọn èèyàn?
3 Ní Irú Èrò Tí Jésù Ní Nípa Àwọn Èèyàn: Nígbà tí Jésù ń wàásù fún ọ̀pọ̀ èrò, ó tún ń ronú nípa ẹnì kọ̀ọ̀kan tó wà níbẹ̀. Ó ń wo ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn bí ẹni tó jẹ́ aláìní nípa tẹ̀mí. Ńṣe ni wọ́n dà bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn tó máa darí wọn. Ohun tí Jésù rí wọ̀ ọ́ lọ́kàn, ó sì mú kó máa fi sùúrù kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. (Máàkù 6:34) Tí àwa náà bá ní irú èrò tí Jésù ní nípa àwọn èèyàn, ó máa jẹ́ ká lè fi ojúlówó ìyọ́nú hàn sí wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Èyí sì máa hàn nínú ọ̀nà tá à ń gbà sọ̀rọ̀ àti ìrísí ojú wa. Ìwàásù á sì di ohun tá a máa fi sípò àkọ́kọ́, a ó sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa bá ohun tó ń jẹ ẹnì kọ̀ọ̀kan lọ́kàn mu.—1 Kọ́r. 9:19-23.
4. Kí nìdí tó fi yẹ ká fi ìyọ́nú wọ ara wa láṣọ?
4 Ogunlọ́gọ̀ ńlá èèyàn láti gbogbo orílẹ̀-èdè ń fetí sí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ara sì ń tù wọ́n bá a ṣe ń fi ìfẹ́ hàn sí wọn. Bá a ṣe ń bá a nìṣó láti máa fi ìyọ́nú wọ ara wa láṣọ, ńṣe là ń tipa bẹ́ẹ̀ bu ọlá fún Jèhófà Ọlọ́run wa tó jẹ́ oníyọ̀ọ́nú, a sì ń mú inú rẹ̀ dùn.—Kól. 3:12.