ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 12/15 ojú ìwé 4-7
  • Máa Ṣàánú Fáwọn Ẹlòmíì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Ṣàánú Fáwọn Ẹlòmíì
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àǹfààní Tó Wà Nínú Kéèyàn Máa Ṣàánú
  • Àánú Máa Ń Jẹ́ Ká Báwọn Ẹlòmíì Kẹ́dùn
  • Wá Síbi Tí Àánú Ti Ń Jọba
  • Ẹ Ní Ìyọ́nú Oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Máa Fàánú Hàn Bíi Ti Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2017
  • “Ojú Àánú Ọlọ́run Wa”
    Sún Mọ́ Jèhófà
  • Jèhófà Ń Fi Ìyọ́nú Ṣàkóso
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 12/15 ojú ìwé 4-7

Máa Ṣàánú Fáwọn Ẹlòmíì

ÀSÌKÒ tá a wà yí gan-an ló yẹ ká máa ṣàánú lójú méjèèjì, nítorí ìyàn, àìsàn, àìríná àìrílò, ìwà ọ̀daràn, ogun abẹ́lé àti ìjábá tó gbòde kan. Aláàánú èèyàn lẹni tó bá ń báwọn tó ń jìyà kẹ́dùn, tó sì ń fẹ́ láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Bí ìgbà téèyàn mumi tútù nínú oòrùn ọ̀sán gangan làánú táwọ́n èèyàn bá fi hàn sáwọn tó lọ́gbẹ́ ọkàn ṣe máa ń tù wọ́n lára, ó máa ń dín ìrora wọn kù, ó sì máa ń mú kára wọn yá gágá.

A lè máa ṣàánú àwọn èèyàn nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa, ká máa ràn wọ́n lọ́wọ́, ká sì máa wà nítòsí wọn nígbà tí wọ́n bá nílò ìrànlọ́wọ́ wa. Kò ní dáa ká fojú àánú wa mọ sọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí, ọ̀rẹ́ àtàwọn ojúlùmọ̀ wa. A lè máa ṣàánú fáwọn tá ò tiẹ̀ mọ̀ rí pàápàá. Nígbà tí Jésù Kristi ń wàásù lórí òkè, ó béèrè pé: “Bí ẹ bá nífẹ̀ẹ́ àwọn tí wọ́n ń nífẹ̀ẹ́ yín, èrè wo ni ẹ ní?” Jésù Kristi máa ń ṣàánú àwọn èèyàn. Ó tún sọ pé: “Nítorí náà, gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.”—Mátíù 5:46, 47; 7:12.

O lè ka àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn nínú Ìwé Mímọ́. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé inú Bíbélì la ti lè rí ìtọ́sọ́nà tó dáa jù lọ lórí bó ṣe yẹ ká máa ṣàánú. Ó sọ ọ́ lásọtúnsọ pé ó pọn dandan fún wa pé ká máa ṣèrànwọ́ fáwọn tó nílò rẹ̀ lọ́nà kan tàbí òmíràn. Kódà, a rí i nínú Bíbélì pé ọba tí àánù rẹ̀ kò lẹ́gbẹ́ ni Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá wa àti Ònṣèwé Bíbélì.

Bí àpẹẹrẹ, a kà á pé: “[Ọlọ́run] máa ń gbèjà àwọn opó àtàwọn ọmọ aláìlóbìí. Ó ń bójú tó àwọn àjèjì, ó ń fún wọn lóúnjẹ àti aṣọ.” (Diutarónómì 10:18, Bíbèlì Contemporary English Version) Ìwé Mímọ́ sọ pé Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ ẹni tí “ń mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún fún àwọn tí a lù ní jìbìtì, Ẹni tí ń fi oúnjẹ fún àwọn tí ebi ń pa.” (Sáàmù 146:7) Àṣẹ tí Jèhófà pa nípa àwọn àlejò tí nǹkan ò fi bẹ́ẹ̀ ṣenuure fún ni pé: “Kí àtìpó . . . dà bí ọmọ ìbílẹ̀ yín; kí ìwọ sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.”—Léfítíkù 19:34.

Bó ti wù kó rí, kò rọrùn láti máa ṣàánú. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn Kristẹni tó wà ní Kólósè pè: “Ẹ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀, ẹ sì fi àkópọ̀ ìwà tuntun wọ ara yín láṣọ, èyí tí a ń sọ di tuntun nípasẹ̀ ìmọ̀ pípéye ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán Ẹni tí ó dá a . . . Gẹ́gẹ́ bí àyànfẹ́ Ọlọ́run, mímọ́ àti olùfẹ́, ẹ fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú . . . wọ ara yín láṣọ.”—Kólósè 3:9, 10, 12.

Ìyẹn fi hàn pé, a gbọ́dọ̀ sapá ká lè máa ṣàánú. Ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú tàbí àánú yìí wà lára àwọn “àkópọ̀ ìwà tuntun” táwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ ní. Pọ́ọ̀lù ti gbé láàárín àwọn oníwà ìkà rí nílùú Róòmù àtijọ́. Ìdí nìyẹn tó fi rọ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ pé kí wọ́n yára ṣe ìyípadà tó bá yẹ, kí wọ́n lè túbọ̀ máa bá àwọn ẹlòmíì kẹ́dùn, kí wọ́n sì lè máa ṣàánú.

Àǹfààní Tó Wà Nínú Kéèyàn Máa Ṣàánú

Òmùgọ̀ tàbí ẹni tó dùn ún rẹ́ jẹ làwọn kan máa ń pe ẹni tó bá ń ṣàánú. Ṣé èrò wọn tọ̀nà?

Rárá o! Ojúlówó ìfẹ́ ni olórí ohun tó ń mú kéèyàn máa ṣàánú látọkànwá. Ìfẹ́ yìí wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run torí pé òun gan-an ni ìfẹ́. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:16) Nítorí náà, ó bá a mu wẹ́kú ká pe Jèhófà ní “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.” (2 Kọ́ríńtì 1:3) Ọ̀rọ̀ tá a lò fún “àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́” túmọ̀ sí “kéèyàn máa káàánú àwọn tí nǹkan kù díẹ̀ fún, kéèyàn sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́.” Ó ṣe tán, Jèhófà “jẹ́ onínúrere sí àwọn aláìlọ́pẹ́ àti àwọn ẹni burúkú”!—Lúùkù 6:35.

Ẹlẹ́dàá wa ń fẹ́ káwa pẹ̀lú jẹ́ aláàánú nípa ṣiṣoore fáwọn ẹlòmíì. Bíbélì sọ nínú ìwé Míkà 6:8 pé: “Ó ti sọ fún ọ, ìwọ ará ayé, ohun tí ó dára. Kí sì ni ohun tí Jèhófà ń béèrè láti ọ̀dọ̀ rẹ bí kò ṣe pé kí o ṣe ìdájọ́ òdodo, kí o sì nífẹ̀ẹ́ inú rere?” Nínú Òwe 19:22, a tún lè rí i kà pé: “Ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra nínú ará ayé ni inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́.” Nítorí pé Jésù Kristi, Ọmọkùnrin Ọlọ́run fìwà jọ Bàbá rẹ dáadáa, òun náà tún rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ máa bá a lọ ní dídi aláàánú, gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba yín ti jẹ́ aláàánú.” (Lúùkù 6:36) Nígbà tí Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀ máa sọ ọ́, ó ní: “Ẹ jẹ́ aláánú gẹ́gẹ́ bí Bàbá yín ti jẹ́ aláánú.”

Ìdí pàtàkì tá a fi gbọ́dọ̀ jẹ́ aláàánú ni pé, ó tún ń ṣe wá láǹfààní tó pọ̀. A máa ń rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ inú Òwe 11:17 tó sọ pé: “Ènìyàn tí ó ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ń bá ọkàn ara rẹ̀ lò lọ́nà tí ń mú èrè wá.” Bá a bá ṣàánú fẹ́nì kan tó jẹ́ aláìní, Ọlọ́run la ṣe é fún. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run kì í fi í kùnà láti san èrè fún àánù yòówù táwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ bá fi hàn. Òun ló mí sí Ọba Sólómọ́nì láti sọ pé: “Ẹni tí ń fi ojú rere hàn sí ẹni rírẹlẹ̀, Jèhófà ni ó ń wín, Òun yóò sì san ìlòsíni rẹ̀ padà fún un.” (Òwe 19:17) Pọ́ọ̀lù náà tún sọ pé: “Ẹ mọ̀ pé, ohun rere yòówù tí olúkúlùkù ì báà ṣe, yóò gba èyí padà láti ọ̀dọ̀ Jèhófà.”—Éfésù 6:8.

Àánú máa ń jẹ́ kí àjọṣe wa túbọ̀ dán mọ́rán sí i, ó sì má a ń jẹ́ kí àáwọ̀ tètè parí. Ó máa ń jẹ́ kí àìgbọ́ra-ẹni-yé tètè yanjú, ó sì máa ń jẹ́ káwọn èèyàn tètè máa dárí ji ara wọn. Bí a kì í bá ṣàlàyé ohun tó wà lọ́kàn wa dáadáa tàbí táwọn èèyàn bá ṣì wá lóye, àfàìmọ̀ kí èdè àìyédè máà wáyé. Ibi tí àánú sì ti wúlò gan-an nìyí, tórí pé ó máa jẹ́ kọ́ràn tètè yanjú. Ó máa ń rọrùn láti tètè dárí ji ẹni tó bá jẹ́ aláàánú. Bá a bá jẹ́ aláàánú, kò ní ṣòro fún wa láti fi ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fáwọn Kristẹni sílò pé: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn.”—Kólósè 3:13.

Àánú Máa Ń Jẹ́ Ká Báwọn Ẹlòmíì Kẹ́dùn

Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àánú lágbára láti dín ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn kù. Gẹ́gẹ́ bá a ti sọ ṣáájú, ó ń jẹ́ ká báwọn tó ní ìrora ọkàn kẹ́dùn, ó sì tún ń jẹ́ ká máa fọ̀rọ̀ àwọn tí ìyà ń jẹ ro ara wa wò. Bá a bá jẹ́ aláàánú, a ò ní máa fàwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ ṣẹlẹ́yà, kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe la ó máa wá ọ̀nà tá a lè gbà ràn wọ́n lọ́wọ́.

Àwọn Kristẹni ń fara wé Jésù nípa bíbá àwọn ẹlòmíì kẹ́dùn. Kò jẹ́ kí ọwọ́ òun dí jù láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́. Ó pèsè àwọn ohun tí wọ́n nílò fún wọn, títí kan ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n sún mọ́ Ọlọ́run. Bó o bá rí i pé àwọn ẹlòmíì nílò ìrànwọ́, àánú máa ń jẹ́ kó wá bó ṣe máa ràn wọ́n lọ́wọ́.

Ṣàkíyèsí ohun tó ṣe nígbà tó rí àwọn èrò rẹpẹtẹ tébi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń pa: “Nígbà tí ó rí àwọn ogunlọ́gọ̀, àánú wọn ṣe é, nítorí a bó wọn láwọ, a sì fọ́n wọn ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.” (Mátíù 9:36) Ọ̀mọ̀wé kan tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì ṣàlàyé pé ọ̀rọ̀ tí wọ́n tú sí ‘àánú ṣe é’ nínú ẹsẹ yẹn túmọ̀ sí “bí nńkan ṣe máa ń rí lára èèyàn bọ́rọ̀ bá dunni dọ́kàn.” Kódà, àwọn kan tiẹ̀ sọ pé ọ̀rọ̀ yẹn lọ̀rọ̀ tó bá a mu jù lọ tí wọ́n ń lò fún ojú àánú lédè Gíríìkì.

Bẹ́ẹ̀ náà làwọn Kristẹni tó bá lójú àánú ṣe tètè máa ń ṣèrànwọ́ fáwọn aláìní nípa pípèsè àwọn ohun tí wọ́n nílò fún wọn títí kan àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Gbogbo yín ẹ jẹ́ onínú kan náà, kí ẹ máa fi ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì hàn, kí ẹ máa ní ìfẹ́ni ará, kí ẹ máa fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn.” (1 Pétérù 3:8) Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ìdílé Kristẹni kan tí ò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ kó lọ sí àdúgbò míì nítorí àìlera, àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ níbẹ̀ fún wọn nílé lọ́fẹ̀ẹ́ fún odindi oṣù mẹ́fà. Olórí ìdílé yẹn sọ pé: “Ojoojúmọ́ ni wọ́n máa ń wá wò bára wa ṣe le sí. Wọ́n tún máa ń fún wa níṣìírí, àwọn ọ̀rọ̀ wọn sì máa ń tù wá lára.”

Àwọn Kristẹni tòótọ́ pẹ̀lú kì í fọ̀rọ̀ àwọn àlejò ṣeré rárá. Inú wọn máa ń dùn láti wáyè gbọ́ tàwọn ẹlòmíì, wọ́n sì máa ń náwó nára láti ṣèrànwọ́ fáwọn tí wọn ò tiẹ̀ mọ̀ rí pàápàá. Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti ran àwọn tí wọn ò mọ̀ rí lọ́wọ́ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí.

Ìyẹn fi hàn pé, àwọn tó jẹ́ aláàánú tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú ló kún inú ìjọ Kristẹni. Ìfẹ́ máa ń jẹ́ kó wu àwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́. Àwọn ọmọ aláìlóbìí àtàwọn opó tó wà nínú ìjọ lè fẹ́ kó o ran àwọn lọ́wọ́ nítorí ọ̀kan-ò-jọ̀kan àwọn ìṣòro tí wọ́n ní. Ṣé o lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro àìríná àìrílò, àìrí ìtọ́jú tó bó ṣe yẹ, àìrílégbé tàbí àwọn ìṣòro míì tó kàn wọ́n gbọ̀ngbọ̀n?

Gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí tọkọtaya kan nílùú Gíríìsì. Àrùn rọpá-rọsẹ̀ ń ṣe ọkọ, ìyẹn ló sì sọ òun àti ìyàwó ẹ̀ dèrò ọsibítù kan tó jìnnà sílé wọn. Ọsàn tí wọ́n bá ká látinú ọgbà wọ́n ni wọ́n máa ń tà tí wọ́n fi ń rówó díẹ̀díẹ̀ ná. Ta ló máa máa bá wọn ká ọsàn náà báyìí? Àwọn ará tó wà nínú ìjọ́ ló ràn wọ́n lọ́wọ́. Wọ́n bá wọn ká àwọn ọsàn náà, wọ́n sì tà á. Ìyẹn jẹ́ kí tọkọtaya náà lówó díẹ̀ lọ́wọ́, ọkàn wọn sì balẹ̀.

Oríṣiríṣi ọ̀nà la lè gbà ṣàánú fáwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn Kristẹni tó jẹ́ aláàánú ti wá rí i pé ohun táwọn tí ìyà ń jẹ fẹ́ lọ́pọ̀ ìgbà ni pé ká wá kí wọn, ká sì tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ láti gbọ́ ohun tí wọ́n bá fẹ́ sọ, ká fọ̀rọ̀ wọn ro ara wa wò, ká sì fi Ìwé Mímọ́ tù wọ́n nínú.—Róòmù 12:15.

Wá Síbi Tí Àánú Ti Ń Jọba

Ibi ààbò tó fini lọ́kàn balẹ̀, tó tuni nínú, tójú àánú àti inú rere ti ń jọba, ni ìjọ Kristẹni tó wà káàkiri ayé. Àwọn Kristẹni tòótọ́ ti wá rí i pé ńṣe ni àánú máa ń mú káwọn èèyàn sún mọ́ni ti ìwà òǹrorò sì máa ń léni sá. Nítorí náà, wọ́n ń fara wé Baba wọn ọ̀run bí wọ́n ṣe ń sapá láti máa ‘ṣàánú fáwọn ẹlòmíì.’

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fọ̀yàyà pè ọ́ pé kó o wá sọ́dọ̀ wọn, níbi tí àánú àti ìfẹ́ ti ń jọba, tí wọ́n sì ti máa ń kóni mọ́ra dáadáa. Ó dá wọn lójú pé ọkàn rẹ á balẹ̀, ara á sì tù ọ́ láàárín wọn.—Róòmù 15:7.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni tó wà ní Kólósè níyànjú pé kí wọ́n fi ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ ti ìyọ́nú wọ ara wọn láṣọ

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Bí Jésù bá ti rí i pé ẹnì kan nílò ìrànwọ́, ó máa ń wá ọ̀nà láti ràn án lọ́wọ́ tàánútàánú

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́