Ṣé Àwọn Kristẹni Lè Máa Ṣayẹyẹ Ìbọ̀rìṣà Láìmọ̀?
ÀRÍYÀNJIYÀN kan tó gbàfiyèsí wáyé nígbà ayẹyẹ Kérésìmesì lórílẹ̀-èdè Ítálì lọ́dún 2004. Àwọn kan lára àwọn olùkọ́ àtàwọn ọ̀mọ̀wé tó ń bójú tó ọ̀ràn ẹ̀kọ́ gbà pé ó yẹ káwọn dín àwọn ọjọ́ táwọn yà sọ́tọ̀ fáwọn àṣà Kérésìmesì kù tàbí káwọn má tiẹ̀ tẹ̀ lé àṣà náà mọ́. Ìdí tí wọ́n fi fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé iye àwọn ọmọ ilé ìwé tí kì í ṣọdún kérésìmesì, ìyẹn àwọn tí kì í ṣe Kátólíìkì tàbí Pùròtẹ́sítáǹtì, ti ń pọ̀ sí i. Bó ti wù kó rí, a ṣì rí àwọn olùkọ́ àtàwọn ọ̀mọ̀wé míì bíi tiwọn tí wọ́n fàáké kọ́rí pé kò yẹ káwọn fagi lé àṣà Kérésìmesì.
Àmọ́, ká tiẹ̀ pa àríyànjiyàn tiwọn tì, ibo gan-an làṣà Kérésìmesì ti bẹ̀rẹ̀? Nígbà tí iná àríyànjiyàn náà jó dórí kókó, ìwé ìròyìn àwọn aláṣẹ ìjọ Kátólíìkì tí wọ́n ń pè ní L’Osservatore Romano ṣe àwọn àkíyèsí tó wọni lọ́kàn.
Nígbà tí ìwé ìròyìn náà ń sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ tí wọ́n ń ṣọdún Kérésìmesì, ó sọ pé: “Tá a bá ní ká fojú ohun tí ìtàn sọ wò ó, kò sẹ́ni tó mọ ọjọ́ tí wọ́n bí Jésù torí pé ìtàn ìlú Róòmù, títí kan ètò ìkànìyàn tó wáyé nígbà yẹn àtàwọn ìwádìí tí wọ́n fi ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣe kò sọ ní pàtó pé ọjọ́ báyìí ni wọ́n bí i. . . . Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀jọ [1,600] ọdún sẹ́yìn ni Ṣọ́ọ̀ṣì Róòmù mú December 25 tí gbogbo èèyàn wá mọ̀ sì ọjọ́ Kérésì. Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, ọjọ́ yìí gan-an ni wọ́n ń bọ oòrùn nílùú Róòmù . . . Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nítorí àṣẹ tí Kọnsitatáìnì pa ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán [1,700] ọdún sẹ́yìn ọ̀pọ̀ ló wá mọ ìsìn Kristẹni dunjú nílùú Róòmù, síbẹ̀ ìtàn àròsọ nípa . . . babalóòṣà àwọn tó ń kúnlẹ̀ bọ oòrùn ṣì gbilẹ̀, àgàgà láàárín àwọn ọmọ ogun wọn. Inú àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tó wọ́pọ̀ nígbà yẹn ni wọ́n ti rí àwọn ayẹyẹ ìbọ̀rìṣà tí wọ́n ń ṣe ní December 25. Èyí ló mú kí Ṣọ́ọ̀ṣì Róòmù mú ọjọ́ yẹn láti máa ṣayẹyẹ tí wọ́n gbà pó ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ìsìn Kristẹni, ni wọ́n bá fi Jésù Kristi, tó jẹ́ Oòrùn Ẹ̀san, dípò oòrùn táwọn èèyàn ń bọ̀, tí wọ́n sì sọ pé ọjọ́ tí wọ́n ń bọ oòrùn làwọ́n á máa ṣayẹyẹ ìbí Jésù.”
Báwo wá ni ti igi Kérésìmesì ti wọ́n mú wọnú àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ Kátólíìkì ṣe jẹ́?
Àpilẹ̀kọ tó fara hàn nínú ìwé ìròyìn Kátólíìkì yẹn sọ pé láyé ọjọ́un àwọn èèyàn gbà gbọ́ pé àwọn èròjà tó lè wo onírúurú àrùn wà nínú àwọn igi tó máa ń tutù yọ̀yọ̀ kádún, irú bí “igi holly, igi ọ̀pẹ, igi lọ̀rẹ́ẹ̀lì àti ẹ̀ka igi ahóyaya.” Àpilẹ̀kọ yẹn ń bá a lọ pé: “Alẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú Kérésìmesì, ìyẹn December 24, ni wọ́n máa ń fi ìtàn olókìkí nípa Igi tó wà nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé ṣèrántí Ádámù àti Éfà . . . Wọ́n á gbé igi ahóyaya tí wọ́n fi rọ́pò igi ápù sórí pèpéle, torí ápù ò ṣe é lò nígbà òtútù, wọ́n á wá so àwọn èso ápù rọ̀ sára ẹ̀ka Igi ahóyaya ọ̀hún. Nígbà míì sì rèé, wọ́n máa ń ṣàpẹẹrẹ ìtúsílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ nípa ṣíṣe súìtì àti ẹ̀bùn fáwọn ọmọdé, wọ́n sì tún máa ń ṣe bisikíìtì tó ní bátànì àrà ọ̀tọ̀ tó dúró fún ara Jésù.” Tí wọ́n bá ṣèyẹn tán ńkọ́?
Nígbà tí ìwé ìròyìn L’Osservatore Romano ń ṣàlàyé bí àṣà lílo igi Kérésìmesì ṣe bẹ̀rẹ̀ nílùú Jámánì ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún márùn-ún sẹ́yìn, ó sọ pé: “Orílẹ̀-èdè Ítálì wà lára àwọn orílẹ̀ èdè tí kò tètè gba àṣà lílo igi Kérésìmesì bóyá nítorí ọ̀rọ̀ tí wọ́n hu gbọ́ pé àṣà àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì ni lílo igi Kérésìmesì jẹ́, wọ́n wá pinnu pé àwòrán ìbí Jésù níbùjẹ ẹran làwọn á máa lò.” Póòpù Paul Kẹfà “lẹni tó kọ́kọ́ dáṣà gbígbé igi Kérésìmesì ràgàjì kan kalẹ̀ [ní Gbàgede Pétérù Mímọ́ nílùú Róòmù]” lẹ́bàá àwòrán nípa ìbí Jésù ní ibùjẹ ẹran.
Ṣé o rò pé kò sóhun tó burú nínú kí olórí ìsìn kan sọ pé àmì àtàwọn ayẹyẹ ìbọ̀rìṣà àtayébáyé kan ní nǹkan ṣe pẹ̀lú ètò ẹ̀sìn Kristẹni? Bíbélì gba àwọn Kristẹni tòótọ́ níyànjú nípa ọ̀nà tó tọ́, nígbà tó sọ pé: “Àjọṣe wo ni òdodo àti ìwà àìlófin ní? Tàbí àjọpín wo ni ìmọ́lẹ̀ ní pẹ̀lú òkùnkùn?”—2 Kọ́ríńtì 6:14-17.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Igi Kérésìmesì (ojú ìwé kejì) àti Àwòrán ìbí Jésù níbùjẹ ẹran ní ibùjókòó Ìjọba Póòpù
[Credit Line]
© 2003 BiblePlaces.com
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Oòrùn àkúnlẹ̀bọ
[Credit Line]
Ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí nílùú Wiesbaden