Ṣó o Ní Agbaninímọ̀ràn Tó Bá Dọ̀rọ̀ Ìjọsìn Ọlọ́run?
ỌMỌ ọdún mẹ́rìndínlógún péré ni Ùsáyà nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba. Ó sì lé ní àádọ́ta ọdún tó fi ṣàkóso lórí ìjọba gúúsù ti ẹ̀yà Júdà. Láti kékeré ni Ùsáyà ti “ń bá a nìṣó ní ṣíṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà.” Kí ló ràn án lọ́wọ́ láti rìn lọ́nà títọ́? Ìtàn náà sọ pé: “[Ùsáyà] sì ń bá a lọ ní títẹ̀ sí wíwá Ọlọ́run ní àwọn ọjọ́ Sekaráyà, olùkọ́ni ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́; àti pé, ní àwọn ọjọ́ tí ó wá Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ mú kí ó láásìkí.”—2 Kíróníkà 26:1, 4, 5.
A ò mọ púpọ̀ nípa Sekaráyà tó jẹ́ bọ́bajíròrò yìí ju ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ nípa rẹ̀ lọ. Síbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí “olùkọ́ni ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́,” Sekaráyà kópa tó kàmàmà lórí bí ọba Ùsáyà ṣe yan ohun tó tọ́ láàyò nígbà tó ṣì kéré. Bíbélì The Expositor’s Bible sọ pé Sekaráyà jẹ́ “ọkùnrin tó kún fún ìmọ̀ nípa Ìwé Mímọ́, tòye ẹ̀ jinlẹ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ẹ̀sìn, tó sì mọ bó ṣe lè fi ìmọ̀ tó ní kọ́ àwọn ẹlòmíì lẹ́kọ̀ọ́.” Nígbà tí ọ̀mọ̀wé kan tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa sọ irú ẹni tí Sekaráyà jẹ́, ó ní: “Ó lóye àsọtẹ́lẹ̀ dáadáa . . . onílàákàyè, olùfọkànsìn àti adúróṣánṣán èèyàn ni pẹ̀lú; ó sì tún jọ pé ó kópa tó jọjú lórí Ùsáyà.”
Rírìn tí Ùsáyà rìn lọ́nà tó tọ́ yọrí sí ìbùkún jìngbìnnì, ó sì “fi okun hàn dé ìwọ̀n àrà ọ̀tọ̀” nítorí pé ‘Ọlọ́run tòótọ́ ń bá a lọ láti ràn án lọ́wọ́.’ Bẹ́ẹ̀ ni, ohun tó mú kí Ùsáyà ṣàṣeyọrí nígbà tó ń ṣàkóso ni pé ó ń bá a lọ láti máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run “ní àwọn ọjọ́ Sekaráyà.” (2 Kíróníkà 26:5-8) Àmọ́, bí nǹkan ṣe bẹ̀rẹ̀ sí i dùn fún Ùsáyà, ló bá dẹni tó ń kọtí ikún sáwọn ìmọ̀ràn tí Sekaráyà agbaninímọ̀ràn rẹ̀ ti fún un. “Ọkàn-àyà [Ùsáyà] di onírera àní títí dé àyè tí ń fa ìparun, tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣe àìṣòótọ́ sí Jèhófà.” Nítorí ìwà àfojúdi tó hù ni Jèhófà ṣe fi ẹ̀tẹ̀ kọlù ú tó sì wá di aláìlera débi pé kò lè ṣe gbogbo ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba mọ́.—2 Kíróníkà 26:16-21.
Ṣó o lẹ́ni tó o lè pè ní agbaninímọ̀ràn tàbí atọ́nisọ́nà tó ti nípa lórí bó o ṣe ń bá a lọ ní “wíwá Ọlọ́run”? Bóyá ọ̀dọ́mọdé ni ẹ́ àbí o ti kúrò léwe, ọkùnrin ni ẹ́ àbí obìnrin, ó ṣeé ṣe kó o ní irú agbaninímọ̀ràn kan bẹ́ẹ̀. Ó yẹ kó o mọyì ẹ̀ torí pé ìmọ̀ràn rẹ̀ lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa bá a nìṣó ní ṣíṣe ohun tó tọ́ lójú Jèhófà. Máa fetí sílẹ̀ sí Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀ yìí, kó o sì máa fi ìmọ̀ràn rẹ̀ sọ́kàn. Ó máa dáa gan-an tó o bá ń tẹ́tí sí àwọn ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n tó ń tẹnu irú “olùkọ́ni ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́” bẹ́ẹ̀ jáde.—Òwe 1:5; 12:15; 19:20.