ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lfb ẹ̀kọ́ 68 ojú ìwé 162-ojú ìwé 163 ìpínrọ̀ 1
  • Èlísábẹ́tì Bí Ọmọ Kan

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Èlísábẹ́tì Bí Ọmọ Kan
  • Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wọ́n Bí Ẹni Tó Máa Ṣètò Ọ̀nà Sílẹ̀
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • A San Èrè-Ẹ̀san fún Wọn fún Rírìn Láìlẹ́bi
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìkéde Méjì Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • A Bí Atọ́nàṣe Naa
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
Àwọn Míì
Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
lfb ẹ̀kọ́ 68 ojú ìwé 162-ojú ìwé 163 ìpínrọ̀ 1
Sekaráyà sọ fáwọn ọ̀rẹ́ àti mọ̀lẹ́bí ẹ̀ pé Jòhánù lorúkọ ọmọkùnrin òun máa jẹ́

Ẹ̀KỌ́ 68

Èlísábẹ́tì Bí Ọmọ Kan

Lẹ́yìn ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ọdún tí wọ́n tún ògiri Jerúsálẹ́mù kọ́, àlùfáà kan tó ń jẹ́ Sekaráyà àti Èlísábẹ́tì ìyàwó ẹ̀ ń gbé nítòsí ìlú Jerúsálẹ́mù. Ó ti pẹ́ tí wọ́n ti ṣègbéyàwó, àmọ́ wọn ò tíì bímọ kankan. Lọ́jọ́ kan, bí Sekaráyà ṣe ń sun tùràrí nínú tẹ́ńpìlì, áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì yọ sí i. Ẹ̀rù ba Sekaráyà gan-an, ṣùgbọ́n Gébúrẹ́lì sọ fún un pé: ‘Má bẹ̀rù. Ìròyìn ayọ̀ ni mo mú wá fún ẹ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà. Èlísábẹ́tì ìyàwó ẹ máa bí ọmọkùnrin kan, orúkọ ẹ̀ sì máa jẹ́ Jòhánù. Jèhófà ti yan Jòhánù fún iṣẹ́ pàtàkì kan.’ Sekaráyà béèrè pé: ‘Báwo ni màá ṣe gbà ẹ́ gbọ́? Èmi àti ìyàwó mi ti darúgbó, a ò sì lè bímọ mọ́.’ Gébúrẹ́lì wá sọ pé: ‘Ọlọ́run ló rán mi láti wá sọ̀rọ̀ yìí fún ẹ. Ṣùgbọ́n nítorí pé o ò gbà mí gbọ́, o ò ní lè sọ̀rọ̀ títí ìyàwó ẹ á fi bí ọmọ náà.’

Sekaráyà pẹ́ nínú tẹ́ńpìlì lọ́jọ́ yìí ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Nígbà tó fi máa jáde, àwọn tó dúró níta fẹ́ mọ ohun tó ṣẹlẹ̀. Àmọ́, Sekaráyà ò lè sọ̀rọ̀. Ńṣe ló kàn ń fọwọ́ ṣàpèjúwe. Ìgbà yẹn làwọn èèyàn tó mọ̀ pé Sekaráyà tí gbọ́ ìròyìn kan látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.

Kò pẹ́, Èlísábẹ́tì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan bí áńgẹ́lì náà ṣe sọ. Àwọn ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ wá wo ọmọ náà. Wọ́n sì ń bá Èlísábẹ́tì yọ̀. Èlísábẹ́tì wá sọ pé: ‘Jòhánù lorúkọ ẹ̀ máa jẹ́.’ Àwọn èèyàn náà dá a lóhùn pé: ‘Kò sẹ́nì kankan tó ń jẹ́ Jòhánù nínú ilé yín. Jẹ́ ká máa pè é ní Sekaráyà, bíi bàbá ẹ̀.’ Àmọ́, Sekaráyà kọ ọ́ sílẹ̀ pé: ‘Jòhánù lorúkọ ẹ̀.’ Lójú ẹsẹ̀, Sekaráyà bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ pa dà! Gbogbo Jùdíà ni wọ́n ti gbọ́ ìròyìn ọmọ náà, àwọn èèyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: ‘Kí lọmọ yìí máa dà tó bá dàgbà?’

Ẹ̀mí mímọ́ wá bà lé Sekaráyà. Ó sì sọ tẹ́lẹ̀ pé: ‘Ẹ yin Jèhófà. Ó ṣèlérí fún Ábúráhámù pé òun máa rán olùgbàlà kan wá, ìyẹn Mèsáyà, láti gbà wá là. Jòhánù máa di wòlíì, á sì pa ọ̀nà mọ́ fún Mèsáyà.’

Ohun pàtàkì kan tún ṣẹlẹ̀ sí mọ̀lẹ́bí Èlísábẹ́tì kan tó ń jẹ́ Màríà. A máa mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ ní orí tó kàn.

“Lójú èèyàn, èyí kò ṣeé ṣe, àmọ́ ohun gbogbo ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.”​—Mátíù 19:26

Ìbéèrè: Kí ni Gébúrẹ́lì sọ fún Sekaráyà? Iṣẹ́ pàtàkì wo ni Jòhánù máa ṣe?

Mátíù 11:7-14; Lúùkù 1:5-25, 57-79; Àìsáyà 40:3; Málákì 3:1

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́