A San Èrè-Ẹ̀san fún Wọn fún Rírìn Láìlẹ́bi
JEHOFA ń bùkún ó sì ń san èrè-ẹ̀san fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olùṣòtítọ́. Ó lè jẹ́ pé wọ́n níláti dúró fún àkókò díẹ̀ láti rí ìṣiṣẹ́yọrí àwọn ète Ọlọrun, ṣùgbọ́n irú ìdùnnú wo ní o máa ń jẹ́ nígbà tí wọ́n bá ní ìrírí yìí!
Èyí ni a ṣàpèjúwe rẹ̀ dáradára ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn nínú ọ̀ràn Sakariah tí ó jẹ́ àlùfáà àwọn Ju àti aya rẹ̀, Elisabeti, tí àwọn méjèèjì wá láti ìlà ìdílé Aaroni. Ọlọrun ti ṣèlérí láti fi irú-ọmọ bùkún àwọn ọmọ Israeli bí wọ́n bá sìn-ín tọkàntọkàn. Ó sọ pé àwọn ọmọ jẹ́ èrè. (Lefitiku 26:9; Orin Dafidi 127:3) Síbẹ̀síbẹ̀, Sakariah àti Elisabeti wà láìlọ́mọ wọ́n sì ti darúgbó.—Luku 1:1-7.
Ìwé Mímọ́ sọ pé Sakariah ati Elisabeti “ṣe olódodo níwájú Ọlọrun, wọ́n ń rìn ní gbogbo òfin òun ìlànà Oluwa ní àìlẹ́gàn.” (Luku 1:6) Wọ́n fẹ́ràn Ọlọrun gan-an débi pé kò ni wọ́n lára láti lépa ọ̀nà òdodo àti láti pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́.—1 Johannu 5:3.
Àwọn Ìbùkún Àìròtẹ́lẹ̀
Jẹ́ kí a padà sí apá ìparí ìgbà ìrúwé tàbí ní ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà ẹ̀rùn ti ọdún 3 B.C.E. Herodu Ńlá náà ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba ní Judea. Ní ọjọ́ kan, àlùfáà náà Sakariah wọ Ibi Mímọ́ nínú tẹ́ḿpìlì ní Jerusalemu. Bí àwọn ènìyàn ti péjọ láti gbàdúrà níta ibi mímọ́ náà, ó ń fín tùràrí lórí pẹpẹ oníwúrà náà. Èyí ni ó ṣeéṣe kí a kà sí ohun tí ó lọ́lá jù nínú iṣẹ́-ìsìn ojoojúmọ́, èyí ni a ń ṣe lẹ́yìn rírú ẹbọ. Àlùfáà kan lè ní irú àǹfààní yìí lẹ́ẹ̀kan péré ní ìgbésí-ayé rẹ̀.
Ohun tí Sakariah rí ṣe é ní kàyéfì. Èéṣe, angẹli Jehofa dúró ní apá ọ̀tún pẹpẹ tùràrí! Àlùfáà arúgbó náà bẹ̀rẹ̀ síí dààmú ó sì bẹ̀rù. Ṣùgbọ́n angẹli náà sọ pé: “Má bẹ̀rù, Sakariah: nítorí tí àdúrà rẹ gbà, Elisabeti aya rẹ yóò sì bí ọmọkùnrin kan fún ọ, ìwọ óò sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Johannu.” Bẹ́ẹ̀ni, Jehofa ti gbọ́ àwọn àdúrà onítara Elisabeti àti Sakariah.—Luku 1:8-13.
Angẹli náà fikún un pé: “Ìwọ óò sì ní ayọ̀ àti inúdídùn: ènìyàn púpọ̀ yóò sì yọ̀ sí ìbí rẹ̀. Nítorí òun ó pọ̀ níwájú Oluwa, kì yóò sì mu ọtí-wáìnì, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sì mu ọtí-líle; yóò sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àní láti inú ìyá rẹ̀ wá.” Johannu yóò jẹ́ Nasiri títí ìgbà ìwàláàyè rẹ̀ tí ó kún fún ẹ̀mí mímọ́ Ọlọrun. Angẹli náà tẹ̀síwájú: “Òun ó si pa púpọ̀ dà nínú àwọn ọmọ Israeli sí Oluwa Ọlọrun wọn. Ẹ̀mí àti agbára Elijah ni òun óò sì fi ṣáájú rẹ̀ lọ, láti pa ọkàn àwọn baba dà sí ti àwọn ọmọ, àti ti àwọn aláìgbọràn sí ọgbọ́n àwọn olóòótọ́; kí ó lè pèsè ènìyàn tí a múrasílẹ̀ de Oluwa.”—Luku 1:14-17.
Sakariah béèrè pé: “Àmì wo ni èmi ó fi mọ èyí? Èmi ṣáà di àgbà, àti Elisabeti aya mi sì di arúgbó.” Angẹli náà dáhùn pé: “Èmi ni Gabrieli, tí máa dúró níwájú Ọlọrun; èmi ni a rán wá láti sọ fún ọ, àti láti mú ìhìn ayọ̀ wọ̀nyí fún ọ wá. Sì kíyèsí i, ìwọ óò yadi, ìwọ kì yóò sì lè fọhùn, títí ọjọ́ náà tí nǹkan wọ̀nyí yóò fi ṣẹ, nítorí ìwọ kò gba ọ̀rọ̀ mi gbọ́ tí yóò ṣẹ ní àkókò wọn.” Nígbà tí Sakariah jáde wá láti ibi mímọ́, kò lè sọ̀rọ̀, àwọn ènìyàn sì wòye pé ó ti rí ìran kan tí ó jú ti ẹ̀dá ènìyàn lọ. Gbogbo ohun tí ó lè ṣe ni kí ó ṣe àmì, ní lílo ìfaraṣàpèjúwe láti fi gbé èrò rẹ̀ kalẹ̀. Nígbà tí iṣẹ́-ìsìn rẹ̀ parí, ó padà sí ilé.—Luku 1:18-23.
Ìdí fún Ayọ̀
Gan-an bí a ti ṣèlérí, láìpẹ́ Elisabeti ní ìdí láti yọ̀. Ó lóyún, ó sì mú ẹ̀gàn ti jíjẹ́ àgàn kúrò. Ìbátan rẹ̀ Maria pẹ̀lúpẹ̀lù kún fún ayọ̀, níti pé angẹli kan náà, Gabrieli, sọ fún un pé: “Sáà sì kíyèsí i, ìwọ óò lóyún nínú rẹ, ìwọ yóò sì bí ọmọkùnrin kan, ìwọ ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jesu. Òun ó pọ̀, Ọmọ Ọ̀gá-ògo jùlọ ni a óò sì máa pè é: Oluwa Ọlọrun yóò sí fi ìtẹ́ Dafidi baba rẹ̀ fún un.” Maria múratán láti kó ipa “ọmọ-ọ̀dọ̀ Oluwa.”—Luku 1:24-38.
Maria yára lọ sí ilé Sakariah àti Elisabeti ní ìlú olókè ti Judea. Bí ohùn ìkíni Maria ti jáde, ọlẹ̀ inú Elisabeti sọ sókè. Lábẹ́ ìdarí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọrun, Elisabeti ké ní ohùn rara pé: “Alábùkúnfún ni ìwọ nínú àwọn obìnrin, alábùkúnfún sì ni fún ọmọ inú rẹ. Níbo sì ni èyí ti wá bá mi, tí ìyá Oluwa mi ìbá fi tọ̀ mí wá? Sáwò ó, bí ohùn kíkí rẹ ti bọ́ sí mi ní etí, ọlẹ̀ sọ nínú mi fún ayọ̀, alábùkúnfún sì ni ẹni tí ó gbàgbọ́: nítorí nǹkan wọ̀nyí tí a ti sọ fún un láti ọ̀dọ̀ Oluwa wá yóò ṣẹ.” Maria dáhùn pẹ̀lú ìdùnnú ńlá. Ó dúró ti Elisabeti fún nǹkan bí oṣù mẹ́ta.—Luku 1:39-56.
A Bí Johannu
Láìpẹ́ Elisabeti àti Sakariah arúgbó bí ọmọkùnrin kan. Ní ọjọ́ kẹjọ, ọmọdé jòjòló náà ni a kọnílà. Àwọn ìbátan fẹ́ pe ọmọkùnrin náà ní Sakariah, ṣùgbọ́n Elisabeti sọ pé: “Bẹ́ẹ̀kọ́; bíkòṣe Johannu ni a óò pè é.” Ǹjẹ́ ọkọ rẹ̀ tí ó sì yadi síbẹ̀ gbà bí? Ní orí wàláà ó kọ pé: “Johannu ni orúkọ rẹ̀.” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ahọ́n Sakariah sì tú, ó sì bẹ̀rẹ̀ síí sọ̀rọ̀, ó ń yin Jehofa.—Luku 1:57-66.
Bí ó ti kún fún ẹ̀mí mímọ́, àlùfáà náà tí ayọ̀ kún inú rẹ̀ sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀. Ó sọ̀rọ̀ bíi pé Olùdáǹdè tí a ṣèlérí náà—‘ìwo ìgbàlà ilé Dafidi’—ni a ti gbé dìde ní ìbámu pẹ̀lú májẹ̀mú Abrahamu nípa Irú-Ọmọ ìbùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè. (Genesisi 22:15-18) Gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a rán ṣíwájú Messia náà, ọmọ Sakariah fúnraarẹ̀ tí a bí ní ọ̀nà ìyanu yóò ‘ṣáájú Oluwa láti fi ìmọ̀ ìgbàlà fún àwọn ènìyàn rẹ̀ fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀ wọn.’ Bí ọdún ti ń gorí ọdún, Johannu ń dàgbà ó sì ń lágbára síi ní ẹ̀mí.—Luku 1:67-80.
A San Èrè-Ẹ̀san Fún Wọn Lọ́pọ̀lọpọ̀
Sakariah àti Elisabeti jẹ́ àpẹẹrẹ rere ti ìgbàgbọ́ àti sùúrù. Wọ́n ń bá a lọ láti máa sin Jehofa pẹ̀lú ìṣòtítọ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n níláti dúró de Ọlọrun, ìbùkún wọn tí ó ga jùlọ sì wá kìkì nígbà tí wọ́n ti darúgbó.
Síbẹ̀, wo irú ìbùkún tí Elisabeti àti Sakariah gbádùn! Lábẹ́ ìdarí ẹ̀mí Ọlọrun, àwọn méjèèjì sọ àsọtẹ́lẹ̀. Wọ́n ní àǹfààní láti di òbí àti olùkọ́ni fún Johannu Arinibọmi, ẹni tí a rán ṣíwájú Messia náà. Ní àfikún, Ọlọrun kà wọ́n sí olódodo. Bákan náà, àwọn tí ó ń lépa ọ̀nà ìfọkànsìn Ọlọrun lónìí lè ní ìdúró òdodo pẹ̀lú Ọlọrun wọn yóò sì gba èrè-ẹ̀san lọ́pọ̀lọpọ̀ fún rírìn láìlẹ́bi nínú àṣẹ Jehofa.