ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • jy orí 3 ojú ìwé 14-ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 2
  • Wọ́n Bí Ẹni Tó Máa Ṣètò Ọ̀nà Sílẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wọ́n Bí Ẹni Tó Máa Ṣètò Ọ̀nà Sílẹ̀
  • Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Bí Atọ́nàṣe Naa
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Èlísábẹ́tì Bí Ọmọ Kan
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • A San Èrè-Ẹ̀san fún Wọn fún Rírìn Láìlẹ́bi
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Àwọn Míì
Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
jy orí 3 ojú ìwé 14-ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 2
Èlísábẹ́tì ń fi ọmọ ẹ̀ han àwọn èèyàn

ORÍ 3

Wọ́n Bí Ẹni Tó Máa Ṣètò Ọ̀nà Sílẹ̀

LÚÙKÙ 1:57-79

  • WỌ́N BÍ JÒHÁNÙ ARINIBỌMI, WỌ́N SÌ SỌ Ọ́ LÓRÚKỌ

  • SEKARÁYÀ SỌ TẸ́LẸ̀ NÍPA IṢẸ́ TÍ JÒHÁNÙ MÁA ṢE

Èlísábẹ́tì ò ní pẹ́ bímọ. Ó ti tó oṣù mẹ́ta báyìí tí Màríà mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ti wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Màríà ti wá fẹ́ máa lọ, ó máa rìnrìn àjò ọ̀nà jíjìn pa dà sí ilé rẹ̀ ní Násárẹ́tì. Tó bá fi máa tó oṣù mẹ́fà sí i, òun náà máa bímọ.

Kò pẹ́ tí Màríà lọ ni Èlísábẹ́tì bímọ. Ẹ wo bí inú àwọn èèyàn ṣe máa dùn tó pé wẹ́rẹ́ ló bí ọmọ náà, wọ́n gbóhùn ìyá, wọ́n gbọ́ tọmọ! Nígbà tí Èlísábẹ́tì gbé ọmọ náà han àwọn aládùúgbò àtàwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀, wọ́n bá a yọ̀.

Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni pé, tí wọ́n bá bí ọmọkùnrin, kí wọ́n dádọ̀dọ́ fún un ní ọjọ́ kẹjọ, ìgbà yẹn náà ni wọ́n sì sábà máa ń sọ ọmọ náà lórúkọ. (Léfítíkù 12:2, 3) Àwọn kan ronú pé Sekaráyà tó jẹ́ orúkọ bàbá ẹ̀ ló yẹ kí wọ́n sọ ọ́. Àmọ́ Èlísábẹ́tì sọ fún wọn pé: “Rárá o! Jòhánù la máa pè é.” (Lúùkù 1:60) Ẹ má gbàgbé pé áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì ti sọ pé Jòhánù ni wọ́n gbọ́dọ̀ sọ ọmọ náà.

Làwọn aládùúgbò àtàwọn mọ̀lẹ́bí bá yarí, wọ́n sọ pé: “Kò sí mọ̀lẹ́bí rẹ kankan tó ń jẹ́ orúkọ yìí.” (Lúùkù 1:61) Wọ́n wá fara ṣàpèjúwe fún Sekaráyà láti béèrè orúkọ tó fẹ́ sọ ọmọ rẹ̀. Sekaráyà ní kí wọ́n fún òun ní wàláà òkúta kan, ohun tó sì kọ síbẹ̀ ni: “Jòhánù ni orúkọ rẹ̀.”—Lúùkù 1:63.

Sekaráyà ń kọ̀wé sórí òkúta; Sekaráyà ti ń pa dà sọ̀rọ̀, ó sì ń sọ tẹ́lẹ̀

Iṣẹ́ ìyanu kan ṣẹlẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ṣe ni Sekaráyà bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ pa dà. Ṣé ẹ rántí pé ó yadi lẹ́yìn tí áńgẹ́lì náà sọ fún un pé ìyàwó rẹ̀ máa bímọ tí kò sì gbà gbọ́? Torí náà, nígbà tí Sekaráyà bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀, ó ya àwọn aládùúgbò lẹ́nu, wọ́n sì ń bi ara wọn pé: “Kí ni ọmọ kékeré yìí máa dà?” (Lúùkù 1:66) Ìdí ni pé wọ́n rí ọwọ́ Ọlọ́run nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí.

Sekaráyà kún fún ẹ̀mí mímọ́, ó sì kéde pé: “Ẹ yin Jèhófà, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, torí ó ti yíjú sí àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì ti gbà wọ́n sílẹ̀. Ó ti gbé ìwo ìgbàlà kan dìde fún wa ní ilé Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀.” (Lúùkù 1:68, 69) Jésù Olúwa tí wọn ò tíì bí ló ń tọ́ka sí nígbà tó sọ pé “ìwo ìgbàlà.” Sekaráyà sọ pé “lẹ́yìn tí a bá ti gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa,” Ọlọ́run máa tipasẹ̀ Ẹni yẹn “fún wa ní àǹfààní láti máa ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún un láìbẹ̀rù, pẹ̀lú ìdúróṣinṣin àti òdodo níwájú rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ wa.”—Lúùkù 1:74, 75.

Sekaráyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa ọmọ rẹ̀ pé: “Ní tìrẹ, ọmọ kékeré, wòlíì Ẹni Gíga Jù Lọ la ó máa pè ọ́, torí o máa lọ níwájú Jèhófà láti múra àwọn ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀, láti fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní ìmọ̀ ìgbàlà nípa dídárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, torí ojú àánú Ọlọ́run wa. Pẹ̀lú àánú yìí, ojúmọ́ kan máa mọ́ wa láti ibi gíga, láti fún àwọn tó jókòó nínú òkùnkùn àti òjìji ikú ní ìmọ́lẹ̀, kó sì darí ẹsẹ̀ wa ní ọ̀nà àlàáfíà.” (Lúùkù 1:76-79) Ẹ ò rí i pé àsọtẹ́lẹ̀ yẹn fini lọ́kàn balẹ̀ gan-an!

Ní gbogbo àkókò yìí, Màríà ti dé ilé rẹ̀ ní Násárẹ́tì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tíì ṣègbéyàwó, ó ti lóyún. Torí náà, kí ló máa ṣẹlẹ̀ táwọn èèyàn bá rí i pé ó lóyún?

  • Oṣù mélòó ni Jòhánù fi ju Jésù lọ?

  • Kí ló ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kẹjọ tí wọ́n bí Jòhánù?

  • Iṣẹ́ wo ni Ọlọ́run máa gbé fún Jòhánù?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́