ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 7/15 ojú ìwé 31
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì Lọ Sọ́dọ̀ Màríà
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Wọ́n Pọ́n Jésù Lé Kí Wọ́n Tó Bí I
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • A Bọla Fun Un Ṣaaju Ìbí Rẹ̀
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Áńgẹ́lì Kan Bẹ Màríà Wò
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 7/15 ojú ìwé 31

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Maria tí ó di ìyà Jesu ha ti lóyún nígbà tí ó lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Elisabeti tí ó jẹ́ mọ̀lẹ́bí rẹ̀ bí?

Bẹ́ẹ̀ni, ó dájú pé ó ti lóyún.

Ní Luku orí 1, a kà lákọ̀ọ́kọ́ nípa oyún Elisabeti, aya àlùfáà Sekariah, tí ó bí Johannu (Oníbatisí). Nígbà tí Elisabeti wà ‘ní oṣù kẹfà rẹ̀ áńgẹ́lì Gabrieli’ bẹ Maria wò láti sọ fún un pé òun yóò lóyún yóò sì bí “Ọmọkùnrin Ẹni Gíga Jùlọ.” (Luku 1:26, 30-33) Ṣùgbọ́n nígbà wo ni Maria lóyún?

Àkọsílẹ̀ Luku ń bá a lọ ní sísọ pé Maria lẹ́yìn náà rin ìrìn-àjò lọ sí Juda láti ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Elisabeti mọ̀lẹ́bí rẹ̀ tí ó ti lóyún. Nígbà tí àwọn obìnrin méjèèjì náà pàdé, ìkókó tí ń bẹ nínú ọlẹ̀ Elisabeti (Johannu) sọ kúlú. Elisabeti tọ́ka sí ‘èso ilé ọlẹ̀ Maria,’ ó sì pe Maria ni ‘ìyá Oluwa òun.’ (Luku 1:39-44) Ìparí èrò tí ó bọ́gbọ́n mu tí a lè dé nígbà náà ni pé Maria ti fẹ́ra kù tẹ́lẹ̀, pé ó ti lóyún nígbà tí ó lọ láti rí Elisabeti.

Luku 1:56 kà pé: “Lẹ́yìn naa Maria wà pẹlu rẹ̀ fún nǹkan bí oṣù mẹ́ta, ó sì padà sí ilé tirẹ̀.” Ẹsẹ̀ yìí kò ṣe pàtó nípa ọjọ́ náà gan-an lórí kàlẹ́ńdà. Ó sọ pé “nǹkan bí oṣù mẹ́ta,” èyí tí yóò fi hàn pé oyun Elisabeti ti di oyun oṣù mẹ́sàn-án.

Lẹ́yìn tí ó ti ran Elisabeti lọ́wọ́ lákòókò tí ó kẹ́yìn ìlóyún rẹ̀, Maria gba ilé rẹ̀ ní Nasareti lọ. Ó lè jẹ́ pé Maria ti mọ̀ pé gbàrà tí Elisabeti bá ti bímọ (Johannu), àwọn àlejò púpọ̀ lè máa wá, ó ṣeé ṣe kí àwọn kan lára wọn jẹ́ mọ̀lẹ́bí. Ìyẹn lè jẹ́ ohun kan tí ń mára tini tàbí tí ó lè kó ìtìjú bá ọ̀dọ́mọbìnrin kan tí kò tí ì lọ́kọ tí òun fúnra rẹ̀ sì ti lóyún. Oyún Maria ti tó oyún oṣù mélòó nígbà tí ó padà sí Nasareti? Níwọ̀n bí ó ti wà pẹ̀lú Elisabeti fún “nǹkan bí oṣù mẹ́ta,” ó ṣeé ṣe kí oyún Maria ti wà ní ìparí oṣù kẹta tàbí ìbẹ̀rẹ̀ oṣù kẹrin nígbà tí ó padà sí Nasareti.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́