Ẹ̀KỌ́ 69
Áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì Lọ Sọ́dọ̀ Màríà
Èlísábẹ́tì ní mọ̀lẹ́bí kan tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Màríà, tó ń gbé nílùú Násárẹ́tì nílẹ̀ Gálílì. Màríà àti Jósẹ́fù ń fẹ́ ara wọn sọ́nà, iṣẹ́ káfíńtà ni Jósẹ́fù ń ṣe. Nígbà tí oyún Èlísábẹ́tì pé oṣù mẹ́fà, áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì lọ sọ́dọ̀ Màríà. Ó sọ pé: ‘Ṣé dáadáa ni, Màríà? Jèhófà ti fi ojú rere hàn sí ẹ.’ Ohun tí áńgẹ́lì náà ń sọ kò yé Màríà. Gébúrẹ́lì wá sọ fún un pé: ‘O máa lóyún, wàá bí ọmọkùnrin kan, wàá sì pe orúkọ ẹ̀ ní Jésù. Ó máa ṣàkóso bí Ọba. Ìjọba ẹ̀ ò sì ní lópin.’
Màríà wá sọ fún un pé: ‘Báwo ni mo ṣe máa bímọ, torí pé mi ò tíì ní ìbálòpọ̀ rí.’ Gébúrẹ́lì sọ pé: ‘Kò sóhun tí Jèhófà ò lè ṣe. Ẹ̀mí mímọ́ máa bà lé ẹ, wàá sì bí ọmọkùnrin kan. Èlísábẹ́tì mọ̀lẹ́bí rẹ náà ti lóyún.’ Lẹ́yìn náà Màríà sọ pé: ‘Ẹrúbìnrin Jèhófà ni mo jẹ́. Kó ṣẹlẹ̀ sí mi bí o ṣe sọ.’
Màríà wá rìnrìn àjò lọ sọ́dọ̀ Èlísábẹ́tì. Nígbà tí Màríà kí i, Èlísábẹ́tì mọ̀ ọ́n lára pé ọmọ inú òun mira. Ẹ̀mí mímọ́ sì mú kí Èlísábẹ́tì sọ pé: ‘Màríà, Jèhófà ti bù kún ọ. Ojú rere ńlá ló jẹ́ fún mi pé ìyá Olúwa mi wá sílé mi.’ Màríà sì sọ pé: ‘Mo fi gbogbo ọkàn mi yin Jèhófà.’ Màríà dúró sọ́dọ̀ Èlísábẹ́tì fún oṣù mẹ́tà, lẹ́yìn náà, ó pa dà sílé ẹ̀ ní Násárẹ́tì.
Nígbà tí Jósẹ́fù gbọ́ pé Màríà ti lóyún, ó fẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Àmọ́, áńgẹ́lì kan yọ sí i lójú àlá, ó sì sọ fún un pé: ‘Má bẹ̀rù láti gbé Màríà níyàwó. Kò ṣe ohun kankan tó burú.’ Torí náà, Jósẹ́fù gbé Màríà níyàwó, ó sì mú un wá sílé ẹ̀.
“Jèhófà ń ṣe gbogbo ohun tó bá fẹ́ ní ọ̀run àti ní ayé.”—Sáàmù 135:6