ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • jy orí 2 ojú ìwé 12-ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 10
  • Wọ́n Pọ́n Jésù Lé Kí Wọ́n Tó Bí I

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wọ́n Pọ́n Jésù Lé Kí Wọ́n Tó Bí I
  • Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • A Bọla Fun Un Ṣaaju Ìbí Rẹ̀
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì Lọ Sọ́dọ̀ Màríà
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Áńgẹ́lì Kan Bẹ Màríà Wò
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
Àwọn Míì
Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
jy orí 2 ojú ìwé 12-ojú ìwé 13 ìpínrọ̀ 10
Màríà ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́; Èlísábẹ́tì rí i pé ọmọ inú òun sọ kúlú nígbà tí Màríà wọnú ilé rẹ̀; Màríà ń bá Èlísábẹ́tì ṣiṣẹ́ ilé

ORÍ 2

Wọ́n Pọ́n Jésù Lé Kí Wọ́n Tó Bí I

LÚÙKÙ 1:34-56

  • MÀRÍÀ LỌ KÍ ÈLÍSÁBẸ́TÌ MỌ̀LẸ́BÍ RẸ̀

Lẹ́yìn tí áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sọ fún Màríà pé ó máa bí ọmọkùnrin kan tí wọ́n máa pè ní Jésù, tó sì máa jẹ́ Ọba títí láé, Màríà béèrè pé: “Báwo ló ṣe máa ṣẹlẹ̀, nígbà tó jẹ́ pé mi ò bá ọkùnrin lò pọ̀?”—Lúùkù 1:34.

Gébúrẹ́lì dá a lóhùn pé: “Ẹ̀mí mímọ́ máa bà lé ọ, agbára Ẹni Gíga Jù Lọ sì máa ṣíji bò ọ́. Ìdí nìyẹn tí a fi máa pe ẹni tí o bí ní mímọ́, Ọmọ Ọlọ́run.”—Lúùkù 1:35.

Kí Màríà lè gba ọ̀rọ̀ yẹn gbọ́, Gébúrẹ́lì sọ fún un pé: “Wò ó! Èlísábẹ́tì mọ̀lẹ́bí rẹ náà ti lóyún ọmọkùnrin kan, ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, oyún rẹ̀ sì ti pé oṣù mẹ́fà báyìí, ẹni táwọn èèyàn ń pè ní àgàn; torí pé kò sí ìkéde kankan tí kò ní ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.”—Lúùkù 1:36, 37.

Ohun tí Màríà sọ jẹ́ ká rí i pé ó gba ohun tí Gébúrẹ́lì sọ gbọ́. Ó ní: “Wò ó! Ẹrúbìnrin Jèhófà! Kó ṣẹlẹ̀ sí mi bí o ṣe kéde rẹ̀.”—Lúùkù 1:38.

Gbàrà tí Gébúrẹ́lì kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, Màríà múra láti lọ kí Èlísábẹ́tì. Ìtòsí Jerúsálẹ́mù ní agbègbè Jùdíà ni Èlísábẹ́tì àti Sekaráyà ọkọ rẹ̀ ń gbé. Láti Násárẹ́tì tí Màríà ń gbé, ó lè gbà á tó ọjọ́ mẹ́ta sí mẹ́rin kó tó dé ibi tó ń lọ.

Nígbà tó yá, Màríà dé ilé Sekaráyà. Bó ṣe ń wọlé, ó kí Èlísábẹ́tì mọ̀lẹ́bí rẹ̀. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ kún inú Èlísábẹ́tì, ó sì sọ fún Màríà pé: “Ìbùkún ni fún ọ láàárín àwọn obìnrin, ìbùkún sì ni fún èso inú rẹ! Báwo ló ṣe jẹ́ pé èmi ni àǹfààní yìí tọ́ sí, pé kí ìyá Olúwa mi wá sọ́dọ̀ mi? Torí wò ó! bí mo ṣe gbọ́ tí o kí mi, ayọ̀ mú kí ọmọ tó wà ní inú mi sọ kúlú.”—Lúùkù 1:42-44.

Màríà wá fi ìmọrírì hàn, ó ní: “Ọkàn mi gbé Jèhófà ga, ẹ̀mí mi ò sì yéé yọ̀ gidigidi torí Ọlọ́run Olùgbàlà mi, torí pé ó ti ṣíjú wo ipò tó rẹlẹ̀ tí ẹrúbìnrin rẹ̀ wà. Torí, wò ó! láti ìsinsìnyí lọ, gbogbo ìran máa kéde pé aláyọ̀ ni mí, torí pé Ẹni tó lágbára ti ṣe àwọn ohun ńláńlá fún mi.” Ẹ kíyè sí i pé láìka àǹfààní tí Màríà ní sí, Ọlọ́run ló gbé gbogbo ògo fún. Ó sọ pé: “Mímọ́ . . . ni orúkọ rẹ̀ àti pé láti ìran dé ìran, ó ń ṣàánú àwọn tó bẹ̀rù rẹ̀.”—Lúùkù 1:46-50.

Màríà tún fi àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yin Ọlọ́run, ó ní: “Ó ti fi apá rẹ̀ ṣe ohun tó lágbára; ó ti tú àwọn tó jẹ́ agbéraga nínú èrò ọkàn wọn ká. Ó ti rẹ àwọn ọkùnrin alágbára sílẹ̀ látorí ìtẹ́, ó sì gbé àwọn tó rẹlẹ̀ ga; ó ti fi àwọn ohun rere tẹ́ àwọn tí ebi ń pa lọ́rùn dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, ó sì ti mú kí àwọn tó lọ́rọ̀ lọ lọ́wọ́ òfo. Ó ti wá ran Ísírẹ́lì ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, ó rántí àánú rẹ̀, bó ṣe sọ fún àwọn baba ńlá wa, fún Ábúráhámù àti ọmọ rẹ̀, títí láé.”—Lúùkù 1:51-55.

Màríà ń bá Èlísábẹ́tì ṣiṣẹ́ ilé

Nǹkan bí oṣù mẹ́ta ni Màríà fi wà lọ́dọ̀ Èlísábẹ́tì, ó ṣeé ṣe kó máa ran Èlísábẹ́tì lọ́wọ́ torí kò ní pẹ́ bímọ. Ọlọ́run mú káwọn méjèèjì lóyún lọ́nà ìyanu, ẹ ò rí i bó ṣe dùn tó pé àwọn obìnrin olóòótọ́ yìí wà pa pọ̀ lásìkò yẹn!

Ẹ kíyè sí i pé wọ́n pọ́n Jésù lé kí Màríà tó bí i. Èlísábẹ́tì pè é ní “Olúwa mi,” ayọ̀ sì mú kí ọmọ inú rẹ̀ “sọ kúlú” ní gbàrà tí Màríà dé ọ̀dọ̀ rẹ̀. Àmọ́, ohun táwọn míì ṣe sí Màríà àti ọmọ inú rẹ̀ yàtọ̀ pátápátá síyẹn, a ṣì máa sọ̀rọ̀ nípa kókó yìí tó bá yá.

  • Kí ni Gébúrẹ́lì sọ tó jẹ́ kí Màríà lóye ọ̀nà tó máa gbà lóyún?

  • Báwo ni wọ́n ṣe pọ́n Jésù lé kí Màríà tó bí i?

  • Báwo ni Màríà ṣe pẹ́ tó lọ́dọ̀ Èlísábẹ́tì, kí sì nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́